Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Dúró Sí Ibi Ààbò Jèhófà

Dúró Sí Ibi Ààbò Jèhófà

“Jèhófà yóò . . . bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì jagun bí ti ọjọ́ ìjagun rẹ̀, ní ọjọ́ ìjà.”—SEK. 14:3.

1, 2. Ogun tòótọ́ wo ló máa tó jà? Kí la ò ní ṣe tí ogun náà bá dé?

NÍ October 30, ọdún 1938, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń tẹ́tí sí ètò orí rédíò kan. Bí ètò náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, àwọn òṣèré kan tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí àwọn tó ń ka ìròyìn lórí rédíò ṣe ìkìlọ̀ pàtàkì kan fáwọn aráàlú. Wọ́n ní àwọn abàmì ẹ̀dá kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ojú sánmà láti wá pa ilé ayé run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé iṣẹ́ rédíò náà sọ pé eré làwọn ń fi ètò náà ṣe, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì rò pé òótọ́ ni ogun náà máa jà. Torí náà, jìnnìjìnnì mú wọn. Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí wá bí wọ́n á ṣe dáàbò bo ara wọn tí ogun náà bá dé.

2 Láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ogun kan ń bọ̀ tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré rárá. Àmọ́, àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ni kò múra sílẹ̀ de ogun náà. Orúkọ ogun yìí ni Amágẹ́dọ́nì, òun ni ogun tí Ọlọ́run máa fi pa ayé búburú yìí run. Ogun yìí kì í ṣe ìtàn kan lásán. Ohun tó sì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ logun náà máa jà ni pé Ọlọ́run ti sọ fún wa nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. (Ìṣí. 16:14-16) A ò ní ṣe ohunkóhun láti gbèjà ara wa nígbà ogun náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ láti pa wá mọ́ lọ́nà àgbàyanu.

3. Àsọtẹ́lẹ̀ wo la máa jíròrò? Kí nìdí tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí?

3 Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú Sekaráyà orí 14 sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa ogun Amágẹ́dọ́nì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wà lákọọ́lẹ̀ láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] ọdún sẹ́yìn, ó ṣe pàtàkì gan-an fún wa lónìí. (Róòmù 15:4) Ó sọ nípa àwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ọdún 1914 tí Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Ó tún sọ fún wa nípa àwọn ohun àrà tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ fún wa nípa “àfonífojì ńlá kan” àti “omi ààyè.” (Sek. 14:4, 8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ ohun  tí àfonífojì náà jẹ́ àti bí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lè rí ààbò níbẹ̀. A tún máa mọ ohun tí omi ààyè náà jẹ́ àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀. Gbogbo èyí á wá jẹ́ ká rí ìdí tó fi pọn dandan pé ká mu nínú omi náà àti ìdí tí a fi máa fẹ́ láti mu nínú rẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ náà.—2 Pét. 1:19, 20.

ỌJỌ́ JÈHÓFÀ BẸ̀RẸ̀

4. (a) Ìgbà wo ni ọjọ́ Jèhófà bẹ̀rẹ̀? (b) Ṣáájú ọdún 1914, kí ni àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn ti ń wàásù rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún? Kí sì ni àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn olórí ẹ̀sìn ṣe?

4 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà orí 14, Bíbélì sọ pé: “Ọjọ́ kan ń bọ̀, tí ó jẹ́ ti Jèhófà.” (Ka Sekaráyà 14:1, 2.) Ọjọ́ wo nìyẹn? Ó jẹ́ ọjọ́ tí Bíbélì tún pè ní “ọjọ́ Olúwa.” Ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 nígbà tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣí. 1:10; 11:15) Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi wàásù pé ọdún 1914 ni “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” máa dópin. Wọ́n tún wàásù pé láti ìgbà yẹn lọ, wàhálà máa pọ̀ sí i nínú ayé ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. (Lúùkù 21:24) Ṣé “àwọn orílẹ̀-èdè” kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn olórí ẹ̀sìn fi àwọn Kristẹni tó ń fi ìtara wàásù yẹn ṣẹ̀sín, wọ́n sì tún ṣe inúnibíni sí wọn. Ńṣe ni wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi Ọlọ́run Olódùmarè ṣẹlẹ́yà, torí pé Ìjọba Ọlọ́run làwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn ń ṣojú fún.—Héb. 12:22, 28.

5, 6. (a) Kí ni àwọn ọ̀tá ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Àwọn wo ni “àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà”?

5 Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí àwọn ọ̀tá máa ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ó ní: “A ó sì gba ìlú ńlá náà ní ti tòótọ́.” “Ìlú” náà, ìyẹn Jerúsálẹ́mù, ló dúró fún Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ló ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. (Fílí. 3:20) Àwọn ọ̀tá “gba” ìlú yìí nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Bí wọ́n sì ṣe gbà á ni pé wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Jèhófà, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n ní ìlú Atlanta tó wà ní ìpínlẹ̀ Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé: “A ó sì kó àwọn ilé ní ìkógun.” Lọ́nà wo? Nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró yìí wà ní àtìmọ́lé, àwọn ọ̀tá fi ìwọ̀sí lọ̀ wọ́n, wọ́n sì hùwà ìkà sí wọn. Wọ́n fi òfin de àwọn ìwé wọn, wọ́n sì ka iṣẹ́ ìwàásù wọn léèwọ̀. Ó wá dà bíi pé wọ́n kó wọn ní “ìkógun” ní ti pé wọ́n ka iṣẹ́ ìwàásù wọn léèwọ̀, wọ́n sì kó àwọn ìwé wọn tó ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní kúrò nílẹ̀.

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ṣe inúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n sì pa irọ́ mọ́ wọn, wọn ò lè pa ìsìn tòótọ́ run. Àwọn ẹni àmì òróró kan wà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Bí Sekaráyà ṣe sọ, àwọn yìí ni “àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà,” tí wọn kò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá “ké wọn kúrò ní ìlú” náà.

7. Kí ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní rí kọ́ lára àwọn ẹni àmì òróró?

7 Ǹjẹ́ àwọn ọ̀tá dẹ́kun láti máa ṣe inúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí? Rárá o. Inúnibíni tí Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣì ń bá a lọ. (Ìṣí. 12:17) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn ará wa lọ́nà rírorò nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́, bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe jẹ́ olóòótọ́ nígbà yẹn ń ran àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní lọ́wọ́ ká lè máa fara da àdánwò. Lára irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ ni yẹ̀yẹ́ tí àwọn ìbátan wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, tàbí àwọn ọmọléèwé wa máa ń fi wá ṣe, torí ohun tá a gbà gbọ́.  (1 Pét. 1:6, 7) Ibi yòówù ká máa gbé, a ti pinnu láti máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́, a kò sì ní jẹ́ kí àwọn tó ń ṣàtakò sí wa kó jìnnìjìnnì bá wa. (Fílí. 1:27, 28) Àmọ́, báwo la ṣe lè rí ààbò nínú ayé tí wọ́n ti kórìíra wa yìí?—Jòh. 15:17-19.

JÈHÓFÀ ṢE “ÀFONÍFOJÌ ŃLÁ KAN”

8. (a) Nígbà míì, kí ni àwọn òkè máa ń dúró fún nínú Bíbélì? (b) Kí ni “òkè ńlá igi ólífì” dúró fún?

8 A ti rí i nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà pé “ìlú” náà, tàbí Jerúsálẹ́mù dúró fún Ìjọba Ọlọ́run. Kí wá ni “òkè ńlá igi ólífì, èyí tí ó wà ní iwájú Jerúsálẹ́mù,” dúró fún? Báwo ni òkè náà ṣe máa “là ní àárín” tí yóò sì wá di òkè méjì? Kí sì nìdí tí Jèhófà fi pè é ní “àwọn òkè ńlá mi”? (Ka Sekaráyà 14:3-5.) Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo òkè láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba tàbí ìṣàkóso. Bákan náà, Bíbélì sábà máa ń sọ pé ìbùkún tàbí ààbò wá láti orí òkè Ọlọ́run. (Sm. 72:3; Aísá. 25:6, 7) Látàrí èyí, òkè ńlá igi ólífì náà dúró fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, ìyẹn ìṣàkóso Jèhófà lórí àwọn ẹ̀dá rẹ̀.

9. Kí ló túmọ̀ sí pé “òkè ńlá igi ólífì” là “ní àárín”?

9 Sekaráyà sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé òkè ńlá igi ólífì náà, tàbí “oke Olifi” là “ní àárín.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé, nítorí ìdí pàtàkì kan, Jèhófà dá ìṣàkóso kejì sílẹ̀. Ó fi ìṣàkóso kejì náà sí ìkáwọ́ Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí Ọba. Àmọ́, torí pé Jèhófà náà ló ṣì ni méjèèjì, ó pè wọ́n ní “àwọn òkè ńlá mi.”—Sek. 14:4, Bibeli Mimọ.

10. Kí ni “àfonífojì ńlá” tó wà láàárín àwọn òkè méjèèjì náà túmọ̀ sí?

10 Nígbà tí òkè ńlá igi ólífì náà là ní àárín, apá kan wà ní àríwá, ìdajì tó kù sì wà ní apá gúúsù. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ẹsẹ̀ Jèhófà ṣì dúró lórí àwọn òkè náà, “àfonífojì ńlá” kan wá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Kí ni àfonífojì yìí? Àfonífojì yìí dúró fún ààbò Ọlọ́run lórí àwọn èèyàn rẹ̀. Kò sí ohun tó lè pa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lára lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ àti ìṣàkóso Ọmọ rẹ̀. Jèhófà ò ní fàyè gba ẹnikẹ́ni láti pa ìsìn mímọ́ run. Ìgbà wo ni “òkè ńlá igi ólífì” yìí là ní àárín? Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso lọ́run. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tiẹ̀ tún sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà máa sá lọ sí “àfonífojì ńlá” náà. Ìgbà wo nìyẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀?

ÀWỌN ÈÈYÀN ỌLỌ́RUN BẸ̀RẸ̀ SÍ Í SÁ LỌ SÍ ÀFONÍFOJÌ NÁÀ!

11, 12. (a) Ìgbà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àfonífojì náà? (b) Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀?

11 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mát. 24:9) Ìkórìíra yẹn ti ń pọ̀ sí i láti ọdún 1914 tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé nínú rẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ọ̀tá ṣe inúnibíni rírorò sí àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Wọ́n fi àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n, wọn ò lè pa ìsìn tòótọ́ run. Ní ọdún 1919, wọ́n dá wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èèyàn Ọlọ́run di òmìnira lọ́wọ́ ìsìn èké, ìyẹn Bábílónì Ńlá. (Ìṣí. 11:11, 12) * Ìgbà yẹn ni àwọn èèyàn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àfonífojì náà.

12 Láti ọdún 1919 ni Jèhófà ti ń bá a nìṣó láti máa dáàbò bo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín níbikíbi tí wọ́n bá wà lágbàáyé. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn sì ni  ọ̀pọ̀ ìjọba ti ń gbìyànjú láti pa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́, wọ́n sì ti fi òfin de àwọn ìwé wa. Èyí ṣì ń bá a nìṣó láwọn orílẹ̀-èdè kan. Àmọ́, Jèhófà ò fàyè gba àwọn ìjọba yìí láti pa ìsìn tòótọ́ run. Ohun yòówù kí àwọn ìjọba ṣe, Jèhófà á ṣì máa fi agbára ńlá rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.—Diu. 11:2.

13. Báwo la ṣe lè dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá? Kí nìdí tó fi túbọ̀ ṣe pàtàkì báyìí pé ká dúró síbẹ̀?

13 Ọ̀nà tá a lè gbà dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá ni pé ká máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Òun àti Ọmọ rẹ̀ kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun mú wa kúrò níbi ààbò náà. (Jòh. 10:28, 29) Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà ká lè jẹ́ adúróṣinṣin lábẹ́ ìṣàkóso òun àti Ọmọ rẹ̀. A máa túbọ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. Torí náà, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé ká dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá.

“ỌJỌ́ ÌJAGUN” JÈHÓFÀ

14, 15. Ní ọjọ́ tí Jèhófà bá bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bá sí lábẹ́ ààbò Ọlọ́run?

14 Láti ìsinsìnyí lọ títí dìgbà tí ayé búburú yìí á fi wá sópin, ńṣe ni ọwọ́ àtakò Sátánì á túbọ̀ máa le sí i. Àmọ́, kò ní pẹ́ tó fi máa ṣe àṣemọ. Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa bá gbogbo ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀ jà, ó sì máa pa gbogbo wọn run. Àkókò yẹn ni Bíbélì pè ní “ọjọ́ ìjagun” rẹ̀. Ogun yẹn ló máa mú kí gbogbo aráyé rí i pé kò sí Jagunjagun tó dà bíi Jèhófà.—Sek. 14:3.

15 Ní ọjọ́ tí Jèhófà bá bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò sí lábẹ́ ààbò Ọlọ́run? Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé wọn kò ní ní “ìmọ́lẹ̀ iyebíye.” Èyí túmọ̀ sí pé wọn kò ní rí ojúure Ọlọ́run. Àsọtẹ́lẹ̀ náà wá sọ síwájú sí i pé “ẹṣin, ìbaaka, ràkúnmí àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti gbogbo onírúurú ẹran agbéléjẹ̀” máa “dì.” Lọ́nà wo? Ohun kan ni pé àwòrán àwọn ẹranko yìí làwọn orílẹ̀-èdè máa ń yà sára àwọn ohun ìjà àti ọkọ̀ ogun wọn. Torí náà, àwọn ohun ìjà àti ọkọ̀ ogun wọn máa “dì” ní ti pé wọn kò ní wúlò fún nǹkan kan. Sekaráyà sọ pé Jèhófà máa fi “òjòjò àrànkálẹ̀” tàbí àrùn kọ lu àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ojú wọn àti ahọ́n wọn máa “jẹrà dànù.” A kò mọ̀ bóyá àrùn gidi ni èyí máa jẹ́. Ohun tá a mọ̀ ni pé wọn kò ní lè pa wá lára, wọn kò sì ní lè sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run. (Sek. 14:6, 7, 12, 15.) Sátánì ni gbogbo “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn” máa fara mọ́ ní tiwọn. Àmọ́, ibi yòówù kí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà máa pa wọ́n run. (Ìṣí. 19:19-21) “Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.”—Jer. 25:32, 33.

16. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa? Kí la gbọ́dọ̀ ṣe nígbà ìpọ́njú ńlá?

16 Gbogbo èèyàn ló máa ń fojú winá ìṣòro nígbà ogun, tó fi mọ́ àwọn tó ṣẹ́gun. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí àwa náà fojú winá àwọn nǹkan kan nígbà ìpọ́njú ńlá. A lè ṣàì rí oúnjẹ tó tó jẹ. A lè pàdánù èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun ìní wa. A lè má fi bẹ́ẹ̀ lómìnira mọ́. Bí irú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀ sí wa, kí la máa ṣe? Ṣé ẹ̀rù ò ní bà wá ju bó ṣe yẹ lọ? Ṣé a kò ní rẹ̀wẹ̀sì? Ṣé kò ní máa ṣe wá bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ? Ṣé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀? Nígbà ìpọ́njú ńlá, a gbọ́dọ̀ dúró sínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá, ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ká sì ní ìgbọ́kànlé pé ó máa dáàbò bò wá.—Ka Hábákúkù 3:17, 18.

 “OMI ÀÀYÈ YÓÒ JÁDE LỌ”

17, 18. (a) Kí ni “omi ààyè”? (b) Kí ni “òkun ìhà ìlà-oòrùn” dúró fún? Kí ni “òkun ìhà ìwọ̀-oòrùn” dúró fún? (d) Kí lo pinnu láti ṣe lọ́jọ́ iwájú?

17 Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, “omi ààyè yóò jáde lọ” láti ibùjókòó Ìjọba Kristi. “Omi ààyè” yìí ni gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ti fún àwa èèyàn ká lè wà láàyè títí láé. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà, “òkun ìhà ìlà-oòrùn” ni Òkun Pupa, ó sì dúró fún àwọn tí wọ́n ti kú, tí wọ́n sì máa ní àjíǹde. “Òkun ìhà ìwọ̀-oòrùn” ni Òkun Mẹditaréníà. Àwọn ohun alààyè wà nínú òkun yìí, torí náà ó dúró fún “àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí wọ́n máa la ogun Amágẹ́dọ́nì já. (Ka Sekaráyà 14:8, 9; Ìṣí. 7:9-15) Àwọn èèyàn tó wà nínú àwùjọ méjèèjì yìí máa mu “omi ààyè” látinú “odò omi ìyè.” Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn máa di pípé, wọ́n á sì máa wà láàyè títí láé.—Ìṣí. 22:1, 2.

Má ṣe kúrò nínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá

18 Nígbà tí Jèhófà bá pa ayé búburú yìí run, ó máa dáàbò bò wá ó sì máa mú ká jogún ayé tuntun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè ló kórìíra wa, a ti pinnu pé a ó máa bá a nìṣó láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, a ò sì ní kúrò nínú àfonífojì tí Jèhófà ti ń dáàbò bò wá.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! ojú ìwé 169 sí 170.