NÍ ỌDÚN mélòó kan sẹ́yìn, Roald àti Elsebeth ìyàwó rẹ̀ ń gbé ní ìlú Bergen. Ọ̀kan lára àwọn ìlú méjì tó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè Norway ni ìlú yìí. Àwọn méjèèjì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ àádọ́ta ọdún nígbà yẹn, wọ́n sì rí já jẹ. Akéde onítara ni Isabel, ọmọ wọn obìnrin àti Fabian, ọmọ wọn ọkùnrin. Alàgbà ni Roald, aṣáájú-ọ̀nà déédéé sì ni Elsebeth. Gbogbo wọn kì í gbẹ́yìn nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ.

Àmọ́, ní oṣù September, ọdún 2009, tọkọtaya yìí ṣe ohun kan tó yàtọ̀. Wọ́n pinnu láti lọ wàásù fún ọ̀sẹ̀ kan níbi àdádó kan ní ìlú Nordkyn, lórílẹ̀-èdè Finnmark. Àwọn àti Fabian, ọmọ wọn ọkùnrin tó ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún nígbà yẹn, ni wọ́n jọ lọ. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n pàdé àwọn ará míì táwọn náà wá síbẹ̀. Gbogbo wọn sì jọ lọ wàásù ní abúlé Kjøllefjord. Roald sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yẹn lọkàn mi ti balẹ̀ pé mo ṣètò àkókò mi kí n lè lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe yìí fún ọ̀sẹ̀ kan gbáko.” Ṣùgbọ́n láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ mọ́. Kí ló fà á?

 ÌBÉÈRÈ KAN BÁ WỌN LÓJIJÌ

Roald sọ pé: “Mario, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń sìn ní orílẹ̀-èdè Finnmark sọ pé àwọn akéde mẹ́tàlélógún kan wà ní ìlú Lakselv. Ó wá béèrè bóyá a lè kó lọ síbẹ̀ ká lè lọ ràn wọ́n lọ́wọ́.” Ìbéèrè yìí bá Roald lójijì, kò sì mọ ohun tí ì bá sọ. Ó ní: “Èmi àti ìyàwó mi ti jọ sọ ọ́ rí pé a lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àmọ́ ìyẹn dìgbà táwọn ọmọ wa bá ti wà láyè ara wọn.” Àmọ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan tí Roald fi wàásù ní abúlé àdádó yẹn, ó rí i pé àwọn èèyàn náà fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ẹ̀rí ọ̀kan mi ò jẹ́ kí n gbádùn. Kódà, ó tó ọjọ́ bíi mélòó kan tí mi ò fi rí oorun sùn.” Ó wu Mario kí Roald àti ìdílé rẹ̀ fi ojú ara wọn rí ìjọ kékeré náà. Torí náà, ó fi ọkọ̀ gbé wọn lọ sí ìlú Lakselv. Ìyẹn tó nǹkan bí igba ó lé ogójì kìlómítà sí ìlú Kjøllefjord, béèyàn bá gba apá gúúsù.

Nígbà tí wọ́n dé ìlú Lakselv, Arákùnrin Andreas tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà méjì tó wà ní ìjọ náà, ló wá pàdé wọn. Ó mú wọn rìn yí ká àdúgbò náà. Lẹ́yìn náà, ó mú wọn lọ sí ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà. Kódà, nígbà tí àwọn ará ìjọ náà rí wọn, ńṣe ni wọ́n gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Wọ́n sọ pé inú àwọn máa dùn bí Roald àti Elsebeth bá lè wá ran àwọn lọ́wọ́ ní ìjọ náà. Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ ni alàgbà tó wá pàdé wọn yẹn fi sọ fún wọn pé àwọn ti ń ṣètò iṣẹ́ tí Roald àti Fabian, ọmọ wọn ọkùnrin máa ṣe. Ohun tó kù ni pé kí wọ́n lọ síbi iṣẹ́ náà kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Ọ̀rọ̀ ti pèsì jẹ wàyí! Kí wá ni Roald, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ wọn máa ṣe?

KÍ NI WỌ́N MÁA ṢE?

Ohun tí Fabian kọ́kọ́ sọ ni pé: “Kò wu èmi láti kó wá síbí o.” Kò wù ú rárá láti fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ tí wọ́n jọ ṣe kékeré sílẹ̀ nínú ìjọ tó wà, kó wá lọ máa gbé ní ìlú kékeré kan. Bákan náà, ó ṣì ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di atúnnáṣe. Kí wọ́n lè mọ èrò Isabel, ìyẹn ọmọ wọn obìnrin tó wà nílé (tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún nígbà yẹn), wọ́n fi fóònù pè é. Kí ló wá sọ nípa bóyá ó máa fẹ́ kí ìdílé wọn kó lọ sí ìlú Lakselv? Ó sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn mi láti ṣe gan-an nìyẹn!” Ó tún wá sọ pé: “Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà tí mo bá ronú lé e lórí, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé ìpinnu tó tọ́ ni mo fẹ́ ṣe yìí? Ṣé àárò àwọn ọ̀rẹ́ mi ò ní máa sọ mí? Ṣé kò ní dára kí n kúkú dúró ní ìjọ tí mo wà, níbi tá a ti mọwọ́ ara wa, tí mo sì ti mojú ilẹ̀ dáadáa?’” Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Elsebeth, tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọ náà? Ó sọ pé: “Ńṣe ni mo wò ó bíi pé Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún ìdílé wa. Àmọ́ mo tún ń ronú nípa ilé wa tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe àti gbogbo ohun tá a ti ń kó jọ láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn.”

Elsebeth àti Isabel

Lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe náà parí, wọ́n pa dà sí ìlú wọn ní Bergen. Àmọ́, wọ́n ṣì ń ronú nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tó wà ní ìlú Lakselv, èyí tó fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún kìlómítà jìnnà sí wọn. Elsebeth sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbàdúrà sí Jèhófà nítorí ọ̀rọ̀ yìí. Èmi àti àwọn ará tí mo rí níbẹ̀ sì máa ń fi fọ́tò àtàwọn ìrírí tá a bá ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ránṣẹ́ síra.” Roald náà sọ pé: “Mi ò lè kánjú ṣe ìpinnu yẹn. Mo gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ó ti tó àkókò fún wa láti lọ lóòótọ́. Mo sì gbọ́dọ̀ ronú nípa bá a ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ yìí. Kódà, mo máa ń jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ìdílé mi àti àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.” Ọmọ wọn ọkùnrin náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń ronú lórí ọ̀rọ̀ náà tó, bẹ́ẹ̀ ni mò ń rí i pé kò sí ìdí pàtàkì kan tí mo fi lè sọ pé mi ò ní lọ. Mo gbàdúrà lemọ́lemọ́ nípa rẹ̀. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti lọ.” Ọmọ wọn obìnrin wá ńkọ́? Òun ti múra tán láti lọ ní tiẹ̀. Láti gbára dì, ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn tó ti ṣe é fún oṣù mẹ́fà, tó sì lo ọ̀pọ̀ àkókò láti dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó gbà pé òun ti ṣe tán láti lọ.

WỌ́N ṢE ÀWỌN ÌPINNU PÀTÀKÌ

Ní báyìí, ìdílé náà ti múra tán láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Àmọ́, wọ́n ní láti ṣe àwọn ìpinnu kan tí kò rọrùn. Iṣẹ́ tó ń mówó wọlé dáadáa ni Roald ń ṣe, ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ náà gan-an. Àmọ́, ó lọ bá ọ̀gá rẹ̀ pé kó fún òun ní àyè ọdún kan. Ṣùgbọ́n ọ̀gá rẹ̀ sọ pé kó máa wá ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ méjì, láàárín oṣù méjì. Roald sọ pé: “Èyí mú kí owó tó ń wọlé fún mi kéré gan-an, àmọ́ ó tẹ́ mi lọ́rùn bẹ́ẹ̀.”

Elsebeth sọ pé: “Ọkọ mi sọ pé kí n wá ilé kan sí Lakselv, ká wá fi ilé wa tó wà ní Bergen rẹ́ǹtì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí gba ọ̀pọ̀ àkókò, a ṣàṣeyọrí. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ wa náà rí iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, wọ́n sì ń bá wa fi iye tí wọ́n bá rí kún owó oúnjẹ àti owó ọkọ̀.”

Ọmọ wọn obìnrin sọ pé: “Torí pé ìlú kékeré ni ìlú  yẹn, olórí ìṣòro mi ni bí mo ṣe máa rí iṣẹ́ tí màá fi máa gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà míì, nǹkan máa ń tojú sú mi.” Àmọ́, ó máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ èyíkéyìí tó bá ti rí láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Nígbà tí wọ́n fi máa lo ọdún kan níbẹ̀, ó ti ṣe onírúurú iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ mẹ́sàn-án. Ọmọ wọn ọkùnrin ńkọ́? Nǹkan ṣẹnuure fún òun náà. Ó sọ pé: “Mo gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá atúnnáṣe kan kí n tó lè parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ mi. Mo parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ni Lakselv. Nígbà tó yá, mo yege nínú ìdánwò tí mo ṣe. Mo sì rí iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí atúnnáṣe.”

BÍ ÀWỌN MÍÌ ṢE FI KÚN IṢẸ́ ÌSÌN WỌN

Marelius àti Kesia ń jẹ́rìí fún obìnrin kan tó ń sọ èdè Sami lórílẹ̀-èdè Norway

Arákùnrin Marelius àti Kesia ìyàwó rẹ̀ náà fẹ́ láti lọ sìn ní ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ni Marelius báyìí. Ó sọ pé: “Àwọn àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí mo máa ń gbọ́ láwọn àpéjọ àgbègbè nípa iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà máa ń mú kí n ronú nípa bí mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi.” Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni Kesia ìyàwó rẹ̀ báyìí. Ṣùgbọ́n, ìṣòro tiẹ̀ ni pé kò fẹ́ kó lọ sí ibi tó ti máa jìnnà sí àwọn ìbátan rẹ̀. Ó ní: “Mi ò fẹ́ jìnnà sí àwọn èèyàn mi rárá.” Ní ti Marelius, ó pọn dandan pé kó máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè san owó tí wọ́n fi ra ilé wọn pa dà fún báńkì. Ó sọ pé: “A ò sinmi àdúrà, ńṣe là ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ. Jèhófà gbọ́ àdúrà wa. A sì lọ sí ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.” Wọ́n kọ́kọ́ lo àkókò púpọ̀ sí i láti dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, wọ́n ta ilé wọn, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀. Ní oṣù August, ọdún 2011, wọ́n kó lọ sí ìlú Alta, tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Norway. Kí wọ́n lè máa rówó gbọ́ bùkátà wọn níbẹ̀, Marelius ń ṣe iṣẹ́ olùṣirò owó, Kesia sì ń bá wọn tajà ní ilé ìtajà kan.

Arákùnrin Knut àti Lisbeth ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọmọ ọdún márùndínlógójì ni. Wọ́n máa ń ka ìtàn àwọn ará wa tó lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i nínú ìwé ọdọọdún wa. Àwọn ìtàn náà máa ń wú wọn lórí gan-an. Lisbeth sọ pé: “Àwọn ìtàn wọ̀nyẹn ń mú ká fẹ́ láti lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Àmọ́, mo máa ń ronú pé kì í ṣe nǹkan tí irú èèyàn bíi tèmi yìí lè ṣe.” Síbẹ̀, àwọn méjèèjì sapá gidigidi kí wọ́n lè lọ. Knut sọ pé: “A ta ilé wa, a sì kó lọ sọ́dọ̀ ìyá mi, ká bàa lè dín ìnáwó kù. A kọ́kọ́ fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí láti sìn níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Torí náà, a lọ lo ọdún kan ní ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìlú Bergen, a sì ń gbé lọ́dọ̀ ìyá ìyàwó mi.” Kò pẹ́ tí Knut àti Lisbeth fi rí i pé àwọn ti wà ní sẹpẹ́ láti lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Torí náà, wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Uganda. Ní oṣù méjì láàárín ọdún kan, wọ́n máa ń pa dà wá ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Norway. Owó iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe yìí ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn jálẹ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè Uganda.

“Ẹ TỌ́ Ọ WÒ, KÍ Ẹ SÌ RÍ I PÉ JÈHÓFÀ JẸ́ ẸNI RERE”

“A ti túbọ̀ sún mọ́ra nínú ìdílé wa.”—Roald

Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n fínnú fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yìí? Roald sọ pé: “A jùmọ̀ máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ní abúlé yìí ju ìgbà tá a wà ní ìlú Bergen  lọ. A ti túbọ̀ sún mọ́ra nínú ìdílé wa. Inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń rí i tí àwọn ọmọ wa ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. A kò lé nǹkan tara mọ́. A ti rí i pé wọn ò ṣe pàtàkì tó bá a ṣe rò tẹ́lẹ̀.”

Ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ Lakselv tí wọ́n wà, abúlé kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Karasjok. Ibẹ̀ làwọn ọmọ ìbílẹ̀ àríwá orílẹ̀-èdè Norway, Sweden, Finland àti Rọ́ṣíà wà. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló ń sọ èdè Sami. Kó bàa lè ṣeé ṣe fún Elsebeth láti wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn náà ní èdè wọn, ó kọ́ èdè náà. Ní báyìí, ó ti lè fi èdè Sami wàásù níwọ̀nba, ó sì ń gbádùn ìpínlẹ̀ ìwàásù rẹ̀ tuntun yìí. Ó sọ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Mo ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà báyìí. Inú mi dùn gan-an pé a wá sìn níbí yìí.”

Ní báyìí, Fabian ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó sọ pé òun àti Isabel fún àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta kan ní ìṣírí láti túbọ̀ máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ń jáde òde ẹ̀rí déédéé báyìí. Kódà, méjì lára wọn ti ṣèrìbọmi, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, ọdún 2012. Ọ̀kan lára wọn dúpẹ́ lọ́wọ́ Fabian àti Isabel pé wọ́n ran òun lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara sin Jèhófà. Fabian sọ pé: “Orí mi wú nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Téèyàn bá ran àwọn míì lọ́wọ́, ó máa ń fúnni láyọ̀ gan-an ni.” Isabel sọ nípa iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé: “Mo ti ‘tọ́ ọ wò, mo sì ti rí i pé ẹni rere ni Jèhófà.’” (Sm. 34:8) Ó tún sọ pé: “Ìyẹn nìkan kọ́ o, mó tún ń gbádùn ara mi níbí yìí gan-an ni!”

Marelius àti Kesia jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, àmọ́ wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. Ní báyìí, akéde mọ́kànlélógójì ló wà ní Ìjọ Alta tí wọ́n ti ń sìn. Marelius sọ pé: “Ká sòótọ́, ìgbésí ayé wa ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká lè máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbí yìí. Ìgbésí ayé wa níbí yìí tẹ́ wa lọ́rùn, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni.” Kesia náà sọ pé: “Mo ti wá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ń tọ́jú wa dáadáa. Bí mo ṣe jìnnà sí àwọn ìbátan mi ti wá túbọ̀ jẹ́ kí n mọyì àwọn àkókò tí a fi ń wà pa pọ̀ báyìí. Mi ò kábàámọ̀ pé a wá sìn ní ibí yìí.”

Knut àti Lisbeth ń kọ́ ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Uganda

Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Knut àti Lisbeth ní Uganda? Knut sọ pé: “Ó pẹ́ kí àyíká àti àṣà ìbílẹ̀ ibẹ̀ tó bá mi lára mu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ní ìṣòro omi àti iná mànàmáná. Inú sì máa ń yọ mí lẹ́nu nígbà míì. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn la máa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Lisbeth sọ pé: “Àwọn ibì kan wà tí kò ju ìrìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sí ibi tá a wà lọ. Síbẹ̀, àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ò tíì gbọ́ ìwàásù rí. Nígbà tá a débẹ̀, a rí àwọn èèyàn tó ń ka Bíbélì, wọ́n sì sọ fún wa pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Ká sòótọ́, ayọ̀ tá à ń ní bá a ṣe ń kọ́ àwọn tó lọ́kàn rere lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọjá àfẹnusọ!”

Ó dájú pé inú Ọ̀gá wa, Kristi Jésù á máa dùn bó ṣe ń rí i pé iṣẹ́ ìwàásù tí òun bẹ̀rẹ̀ ti wá tàn ká ọ̀pọ̀ ibi tó jìnnà gan-an lórí ilẹ̀ ayé! Inú àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run náà ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti pa àṣẹ Jésù mọ́, èyí tó sọ pé ká ‘sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.’—Mát. 28:19, 20.