“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁK. 4:8.

1, 2. (a) Báwo ni Sátánì ṣe máa ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? (b) Kí ló máa mú ká sún mọ́ Ọlọ́run?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN dá àwa èèyàn lọ́nà tó fi jẹ́ pé ó máa ń wù wá láti sún mọ́ ọn. Síbẹ̀, Sátánì fẹ́ ká máa ronú pé a lè ṣàṣeyọrí láìfi ti Jèhófà pè. Látìgbà tí Sátánì ti purọ́ tan Éfà jẹ nínú ọgbà Édẹ́nì ló ti ń fẹ́ kí àwa èèyàn gbà pé a ò nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà. (Jẹ́n. 3:4-6) Látìgbà yẹn náà sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti lérò pé àwa èèyàn lè máa dá tara wa ṣe láìfi ti Ọlọ́run pè.

2 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Ìdí sì ni pé Bíbélì ti ṣàlàyé fún wa nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tí Sátánì ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (2 Kọ́r. 2:11) Ó ń dẹ wá wò ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa mú ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, a ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́, eré ìdárayá àti àjọṣe ìdílé mú wa jìnnà sí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mẹ́rin mìíràn. Ìyẹn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, ìlera, owó àti ìgbéraga. Tá a bá ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti “sún mọ́ Ọlọ́run.”—Ják. 4:8.

ÀWỌN Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ

3. Onírúurú ọ̀nà wo làwọn èèyàn lè gbà lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé?

3 Ibi gbogbo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lóde òní. Àwọn ẹ̀rọ yìí wúlò gan-an téèyàn bá lò wọ́n lọ́nà tó tọ́. Ṣùgbọ́n téèyàn bá lò wọ́n lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n lè mú kéèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. Ẹ wò kọ̀ǹpútà bí àpẹẹrẹ. Kọ̀ǹpútà la fi ń kọ àwọn ìwé wa, tó fi mọ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí, òun náà sì ni a fi ń tẹ̀ wọ́n. A lè fi kọ̀ǹpútà ṣèwádìí ká sì tún fi bára wa sọ̀rọ̀. A sì lè lò ó nígbà míì láti ṣeré ìnàjú tó gbámúṣé. Àmọ́ tá a bá fẹ́ràn àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ju bó ṣe yẹ lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í run gbogbo àkókò wa lé e lórí. Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń mú ká ronú pé a gbọ́dọ̀ máa ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde. Bí àpẹẹrẹ, ó wu ọ̀dọ́mọkùnrin kan pé kó ra kọ̀ǹpútà kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde débi pé ó lọ ta ọ̀kan lára àwọn kíndìnrín rẹ̀ kó lè rówó rà á. Ẹ ò rí i pé ìyẹn tún lágbára!

4. Báwo ni arákùnrin kan ṣe jáwọ́ nínú lílo kọ̀ǹpútà ní àlòjù?

 4 Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé kó o jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ìyẹn sì lè ṣẹlẹ̀ tó o bá ń lò wọ́n lọ́nà tí kò yẹ, tàbí tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí wọn. Arákùnrin Jon * tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún sọ pé: “Mo mọ̀ pé Bíbélì sọ pé ká ‘ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà’ ká lè máa ráyè kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, àkóbá tí mò ń ṣe fún ara mi kì í ṣe kékeré látàrí bí mo ṣe ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí kọ̀ǹpútà.” Arákùnrin yìí sábà máa ń wà nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì títí di òru. Ó tún sọ pé: “Bó ti wù kó rẹ̀ mí tó, ìgbà yẹn gan-an ni màá túbọ̀ máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, tí màá sì máa wo àwọn fídíò kéékèèké. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò bójú mu ni mo máa ń wò.” Kó bàa lè jáwọ́ nínú ohun tó ti di bárakú fún un yìí, ó ṣe ohun kan sórí kọ̀ǹpútà rẹ̀ táá jẹ́ kí kọ̀ǹpútà náà máa kú fúnra rẹ̀ tó bá ti di àkókò tó yẹ kó lọ sùn.—Ka Éfésù 5:15, 16.

Ẹ̀yin òbí, ẹ máa kíyè sí ohun tí àwọn ọmọ yín ń ṣe lórí kọ̀ǹpútà

5, 6. (a) Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe fún àwọn ọmọ wọn? (b) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ní ọ̀rẹ́ tó dáa?

5 Kò pọn dandan kí ẹ̀yin òbí máa rí sí gbogbo nǹkan tí àwọn ọmọ yín bá ń ṣe. Àmọ́, ó yẹ kẹ́ ẹ máa kíyè sí ohun tí wọ́n ń ṣe lórí kọ̀ǹpútà. Àwọn ìkànnì kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì táwọn ọmọ ti lè wo ìṣekúṣe, tí wọ́n ti lè máa gbá géèmù oníwà ipá, tí wọ́n ti lè wo fíìmù tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò tàbí èyí tí wọ́n ti lè kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n lọ sórí irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá gbà wọ́n láyè láti máa lọ sórí àwọn ìkànnì yìí, bóyá torí kí wọ́n má bàa dí yín lọ́wọ́, ó lè mú kí wọ́n rò pé ohun tó dára làwọn ń ṣe. Ojúṣe ẹ̀yin òbí ni pé kẹ́ ẹ máa dáàbò bo àwọn ọmọ yín, kí wọ́n má bàa ṣe ohun tó lè mú kí wọ́n jìnnà sí Jèhófà. Ó ṣe tán, bí ẹnì kan bá ta félefèle lọ́dọ̀ àwọn òròmọdìyẹ, ńṣe ni ìyá àwọn òròmọdìyẹ náà máa pa kuuru mọ́ onítọ̀hún. Bí adìyẹ bá lè dáàbò bo ọmọ rẹ̀ lọ́nà yìí, mélòó mélòó wá ni ẹ̀yin òbí. Ó yẹ kẹ́ ẹ lè dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ ewu.

6 Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè máa bá àwọn àgbàlagbà àtàwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ ṣọ̀rẹ́. Ẹ má sì gbàgbé pé àwọn ọmọ yín fẹ́ kí ẹ̀yin òbí máa wá àyè láti bá àwọn ṣeré, kẹ́ ẹ jọ máa rẹ́rìn-ín, kẹ́ ẹ sì jọ máa ṣiṣẹ́. Ìyẹn á mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo yín láti jọ “sún mọ́ Ọlọ́run.” *

ÌLERA

7. Kí nìdí tó fi máa ń wu gbogbo wa pé kí ara wá dá ṣáṣá?

7 A sábà máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé, ‘Ṣé àlàáfíà lẹ wà?’ Gbólóhùn yìí fi hàn pé kò sẹ́ni tí kì í ṣàìsàn. Àìsàn sì ti bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti jẹ́ kí Sátánì mú wọn jìnnà sí Jèhófà. Inú Sátánì máa ń dùn tá a bá ń ṣàìsàn, torí pé àìsàn máa ń jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún wa láti sin Jèhófà. Tá a bá sì kú, a ò ní lè sin Ọlọ́run rárá. (Sm. 115:17) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń fẹ́ kí ara wa  dá ṣáṣá. * Ó sì yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin jẹ wá lógún.

8, 9. (a) Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe àṣejù nítorí ọ̀rọ̀ ìlera? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí inú wa máa dùn?

8 Àmọ́, kò tún wá yẹ ká ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ ìlera wa o. Ìtara tí àwọn kan fi ń polówó irú oúnjẹ kan, egbòogi tàbí ohun ìṣaralóge pọ̀ ju ìtara tí wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ. Òótọ́ ni pé ó lè jẹ́ pé ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, kò yẹ ká máa ta irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ní àwọn àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè. Kò sì yẹ ká máa polówó wọn níbẹ̀. Kí nìdí?

9 Ìdí tá a fi ń pàdé pọ̀ láwọn ibi àpéjọ wa ni pé ká lè jíròrò ohun tó wà nínú Bíbélì ká sì ní ayọ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń fúnni. (Gál. 5:22) Torí náà, kò ní bójú mu tó bá lọ jẹ́ pé ibẹ̀ la ti ń sọ fún àwọn tó béèrè lọ́wọ́ wa àtàwọn tí kò béèrè nípa ìlera àti irú egbòogi tó dáa kéèyàn lò. Ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìpàdé jẹ́. Tá a bá sọ ibẹ̀ di ibi ìtajà, a lè ba ayọ̀ àwọn míì jẹ́. (Róòmù 14:17) Olúkúlùkù ló máa pinnu irú ìtọ́jú tó tẹ́ òun lọ́rùn. Ó ṣe tán, kò sí èèyàn tó lè wo gbogbo àìsàn. Kódà, àwọn dókítà tó dáńgájíá jù lọ ń darúgbó, wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú. Àníyàn ò sì lè fi kún iye ọjọ́ tó yẹ ká lò láyé. (Lúùkù 12:25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé, “ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”—Òwe 17:22.

10. (a) Kí ló ń mú ká ṣeyebíye lójú Jèhófà? (b) Ìgbà wo làwa èèyàn ò ní ṣàìsàn mọ́?

10 Kò burú ká máa tọ́jú ara wa kí ìrísí wa lè dáa. Àmọ́, kò pọn dandan kéèyàn máa dààmú ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ torí pé ó fẹ́ dán láwọ̀ ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ. Bíbélì sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Ìwà rere wa ló ń mú ká ṣeyebíye jù lọ lójú Jèhófà, ohun tó sì yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí àwa náà nìyẹn. (Ka 1 Pétérù 3:3, 4.) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn lọ ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ kan tó lè fi ẹ̀mí ẹni sínú ewu, tàbí kéèyàn máa lo àwọn oògùn kan tó léwu fún ara kó má bàa tètè darúgbó? Bó ti wù ká darúgbó tàbí kí ara wá dá ṣáṣá tó, “ìdùnnú Jèhófà” nìkan ló lè mú ká ní ẹwà tòótọ́. (Neh. 8:10) Inú ayé tuntun nìkan la ò ti ní ṣàìsàn mọ́ tí ara wa á sì máa jà yọ̀yọ̀. (Jóòbù 33:25; Aísá. 33:24) Títí dìgbà náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání ká sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà. Èyí á jẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, ọ̀rọ̀ ìlera ò sì ní gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ.—1 Tím. 4:8.

OWÓ

11. Báwo ni owó ṣe lè mú wa jìnnà sí Jèhófà?

11 Kò burú láti ní owó tàbí kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ tó dára, tó sì ń mówó wọlé. (Oníw. 7:12; Lúùkù 19:12, 13) Àmọ́ “ìfẹ́ owó” lè mú wa jìnnà sí Jèhófà. (1 Tím. 6:9, 10) “Àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí,” èyí tó túmọ̀ sí pé kéèyàn máa ṣàníyàn jù nítorí jíjẹ, mímu àti ohun ìní, lè mú ká jìnnà sí Jèhófà. “Agbára ìtannijẹ ọrọ̀” tún lè mú ká jìnnà sí Ọlọ́run. Ohun tí agbára ìtannijẹ ọrọ̀ sì túmọ̀ sí ni pé kéèyàn gbà pé owó ló lè fúnni ní ayọ̀ àti ààbò tó tọ́jọ́. (Mát. 13:22) Jésù mú kó ṣe kedere pé “kò sí ẹnì kan” tó lè sìnrú fún Ọlọ́run àti ọrọ̀.—Mát. 6:24.

12. Onírúurú ọ̀nà wo làwọn èèyàn ń gbà wá owó òjijì lóde òní? Kí la lè ṣe tí a kò fi ní dà bí wọn?

12 Tá a bá rò pé owó ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́. (Òwe 28:20) Torí pé àwọn kan fẹ́ láti di olówó òjijì, ńṣe ni wọ́n lọ fi owó wọn ta tẹ́tẹ́. Àwọn ará kan tiẹ̀ lọ́wọ́ sí àwọn okòwò tí wọ́n rò pé ó máa tètè sọ wọ́n di olówó, wọ́n sì ṣèlérí fún àwọn ará míì nínú ìjọ pé àwọn pẹ̀lú máa rí owó nídìí okòwò náà. Àwọn míì sì sọ pé káwọn ará kan nínú ìjọ yá àwọn lówó láti fi ṣòwò àti pé owó gọbọi làwọn máa fi san án pa dà fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí ìwọra mú kó o lọ ṣe òwò tó máa mú kó o kó sọ́wọ́ àwọn gbájúẹ̀! Torí náà, ṣọ́ra kó o má ṣe di  oníwọra. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́. Kò rọrùn láti tètè rí owó rẹpẹtẹ kó jọ o!

13. Èrò wo ni Jèhófà fẹ́ ká ní nípa owó?

13 Tí a kò bá jẹ́ kí iṣẹ́ wa dí wa lọ́wọ́ láti fi “ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀” sí ipò àkọ́kọ́, Jèhófà máa fún wa ní àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémáàní. (Mát. 6:33; Éfé. 4:28) Jèhófà kò fẹ́ ká máa sùn nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ torí pé ó máa ń rẹ̀ wá nítorí iṣẹ́ àṣejù. Kò sì fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa owó nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà káwọn lè lówó. Kí ìyẹn lè jẹ́ àṣesílẹ̀ tó máa di àbọ̀wábá fún wọn nígbà tí wọ́n bá darúgbó. Ohun tí wọ́n sì máa ń sọ pé káwọn ọmọ wọn náà ṣe nìyẹn. Jésù fi hàn pé kò bọ́gbọ́n mu láti ronú lọ́nà yẹn. (Ka Lúùkù 12:15-21.) Èyí lè mú ká rántí Géhásì tó jẹ́ oníwọra, àmọ́ tó rò pé òun ṣì lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà lẹ́sẹ̀ kan náà.—2 Ọba 5:20-27.

14, 15. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé owó ló lè mú ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

14 Àwọn ẹyẹ idì kan wà tí wọ́n gbé ẹja tó wúwo jù fún wọn láti gbé. Àmọ́, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ju ẹja náà sílẹ̀, ńṣe ni wọ́n rì sínú omi. Ǹjẹ́ ohun tó jọ ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ sí àwa Kristẹni? Alàgbà kan tó ń jẹ́ Alex sọ pé: “Mo máa ń ṣọ́wó ná gan-an ni. Ó bá mi débi pé bí ọṣẹ olómi tí mo bù sọ́wọ́ látinú ike bá ti pọ̀ jù, ńṣe ni màá da díẹ̀ pa dà sínú ike náà.” Àmọ́ Alex rò pé bí òun bá lè wá díẹ̀ kún owó tó wà lọ́wọ́ òun, òun á fi iṣẹ́ tí òun ń ṣe sílẹ̀, òun á sì wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà, ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe ń ra ìpín ìdókòwò àti bí wọ́n ṣe ń tà á. Lẹ́yìn náà, ó fi gbogbo owó tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ ra ìpín ìdókòwò. Kódà, ó tún yáwó láti ra ìpín ìdókòwò púpọ̀ sí i! Àwọn ọ̀mọ̀ràn tó mọ bí wọ́n ṣe ń díwọ̀n èrè orí ìpín ìdókòwò tiẹ̀ sọ fún un pé kò ní pẹ́ rárá tí èrè orí ìpín ìdókòwò rẹ̀ á fi pọ̀ gan-an. Àmọ́, ńṣe ni èrè orí ìpín ìdókòwò já wálẹ̀ lójijì. Alex sọ pé: “Mo pinnu pé màá gba owó mi pa dà. Èrò mi ni pé, ìgbà yòówù kó jẹ́, màá dúró dìgbà tí èrè orí ìpín ìdókòwò náà bá lọ sókè.”

15 Fún ọ̀pọ̀ oṣù tí Alex fi ń dúró yìí, kò rí nǹkan míì rò mọ́ ju ìpín ìdókòwò tó rà lọ. Iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́lẹ̀, kò sì rí oorun sùn dáadáa mọ́. Àmọ́, ìpín ìdókòwò náà ò lọ sókè mọ́ o! Gbogbo owó tí Alex dà lé e lórí ló wọgbó, nǹkan sì wá le fún un débi pé ńṣe ló ta ilé rẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ìṣòro tí ọ̀rọ̀ yìí dá sílẹ̀ nínú ìdílé mi kì í ṣe kékeré.” Àmọ́, ó sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó rí kọ́. Ó ní: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé bí ẹnikẹ́ni bá gbẹ́kẹ̀ lé ayé tí Sátánì ń darí yìí pé ó máa fún òun ní ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀, ńṣe lonítọ̀hún á fi ìka àbámọ̀ bọnu gbẹ̀yìn.” (Òwe 11:28) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé owó wa tàbí ọgbọ́n tá a fi lè mówó wọlé, ńṣe là ń gbẹ́kẹ̀ lé Sátánì, tí í ṣe “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́r. 4:4; 1 Tím. 6:17) Ní báyìí, Alex ti ṣe àwọn ìyípadà tó máa mú kó lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Èyí ti mú kí òun àti ìdílé rẹ̀ láyọ̀ kí wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—Ka Máàkù 10:29, 30.

ÌGBÉRAGA

16. Kí ni àwa Kristẹni tòótọ́ lè máa fi yangàn? Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ?

16 Kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa fi ohun tó dára yangàn. Bí àpẹẹrẹ, ohun àmúyangàn ló jẹ́ pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. (Jer. 9:24) Ìyẹn ló sì fà á tá a fi ń gbìyànjú nígbà gbogbo ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dára ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, ká má sì ṣe máa rò pé a gbọ́n ju Jèhófà lọ. Ńṣe ni irú èrò bẹ́ẹ̀ máa mú ká jìnnà sí Jèhófà.—Sm. 138:6; Róòmù 12:3.

Dípò tí wàá fi máa wá ipò nínú ìjọ, máa fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ nìṣó!

17, 18. (a) Irú èèyàn wo ni Bíbélì fi hàn pé Dáfídì jẹ́? Àwọn wo ni Bíbélì fi hàn pé wọ́n jẹ́ agbéraga? (b) Báwo ni arákùnrin kan kò ṣe jẹ́ kí ìgbéraga mú òun jìnnà sí Jèhófà?

17 Bíbélì sọ fún wa nípa àwọn tó jẹ́ agbéraga àtàwọn tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ ni Dáfídì Ọba. Ó bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì rí ìbùkún Jèhófà. (Sm. 131:1-3) Àmọ́ Jèhófà fìyà jẹ Nebukadinésárì Ọba àti Bẹliṣásárì torí pé wọ́n jẹ́ agbéraga. (Dán. 4:30- 37; 5:22-30) Láwọn ìgbà míì, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa fi hàn bóyá a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tàbí agbéraga. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Ryan, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ míì. Ó sọ pé: “Èrò mi ni pé mi ò ní pẹ́ di alàgbà tí mo bá débẹ̀. Àmọ́, ní ọdún kan lẹ́yìn tí mo débẹ̀, mi ò tíì di alàgbà.” Ṣé Ryan bínú sí àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ torí pé wọn kò tètè dámọ̀ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alàgbà? Ṣé ìgbéraga mú kó pa ìpàdé tì, kó sì wá kọ Jèhófà àtàwọn ará sílẹ̀? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Ryan, kí lo máa ṣe?

18 Látàrí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, Arákùnrin Ryan sọ pé: “Mo ṣe ìwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa mo sì kà nípa ìdí tó fi dára pé kéèyàn máa ní sùúrù.” (Òwe 13:12) “Ìgbà yẹn ni mo tó wá rí i pé mo gbọ́dọ̀ ní sùúrù àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà kọ́ mi.” Látìgbà yẹn ni Ryan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bó ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. Kò sì pẹ́ tó fi ní àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jíire. Ó wá sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo di alàgbà ní ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà. Ìdí tó sì fi yà mí lẹ́nu ni pé mi ò tiẹ̀ ronú nípa rẹ̀ mọ́, torí pé mò ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi.”—Ka Sáàmù 37:3, 4.

DÚRÓ TI JÈHÓFÀ

19, 20. (a) Báwo la ṣe lè rí i dájú pé èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí kò mú wa jìnnà sí Jèhófà? (b) Àwọn adúróṣinṣin wo la lè fi ṣe àwòkọ́ṣe wa?

19 Kò sí èyí tó burú nínú àwọn nǹkan méje tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí àti èyí tá à ń jíròrò lọ́wọ́ yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéraga kò dára, ohun àmúyangàn ni pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Ìdílé aláyọ̀ àti ìlera tó dára jẹ́ ara ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa. A mọ̀ pé tá a bá níṣẹ́ lọ́wọ́ tá a sì lówó lọ́wọ́, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti máa gbọ́ bùkátà ara wa. A mọ̀ pé eré ìdárayá máa ń tuni lára. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé sì wúlò gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé tá a bá ṣe ohunkóhun nígbà tí kò tọ́, tá a bá ṣe é láṣejù, tàbí tá a ṣe é lọ́nà tó máa pa iṣẹ́ ìsìn wa lára, ó lè mú ká jìnnà sí Jèhófà.

Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà!

20 Ohun tí Sátánì sì fẹ́ ni pé ká jìnnà sí Jèhófà. Àmọ́, o lè ṣiṣẹ́ kára láti dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ. (Òwe 22:3) Sún mọ́ Jèhófà, má sì ṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ adúróṣinṣin. Énọ́kù àti Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́n. 5:22; 6:9) Mósè “ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:27) Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni Jésù máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà, Ọlọ́run sì tì í lẹ́yìn. (Jòh. 8:29) Fi àwọn tá a dárúkọ yìí ṣe àwòkọ́ṣe rẹ. ‘Máa yọ̀ nígbà gbogbo. Máa gbàdúrà láìdabọ̀. Máa dúpẹ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo.’ (1 Tẹs. 5:16-18) Má sì ṣe jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà!

^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 6 Wo “Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Yanjú” nínú Jí! October–December 2011.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo “Ohun Márùn-ún Tó Lè Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I” nínú Jí! April–June 2011.