Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  January 2013

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Ẹ Jìnnà Sí Jèhófà

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Ẹ Jìnnà Sí Jèhófà

“Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.”—JÓṢ. 24:15.

1-3. (a) Kí nìdí tí Jóṣúà fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa? (b) Kí la gbọ́dọ̀ máa rántí tá a bá ń ṣe ìpinnu?

ÀWỌN ìpinnu tá à ń ṣe ṣe pàtàkì gan-an ni. Wọ́n máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe àti bó ṣe yẹ ká gbé ìgbé ayé wa. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń tọ òpópónà kan lọ, tó wá dé ibì kan tí ọ̀nà ti pín sí méjì. Ṣé apá ọ̀tún ló máa yà sí ni àbí apá òsì? Tó bá jẹ́ pé onítọ̀hún mọ ibi tó ń lọ, ọ̀nà tó já síbẹ̀ ló máa yà sí. Ṣùgbọ́n tó bá lọ yà sí ọ̀nà kejì yẹn, ńṣe ni yóò túbọ̀ máa rìn jìnnà sí ibi tó ń lọ.

2 Bíbélì sọ fún wa nípa ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ní láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Kéènì ní láti pinnu bóyá kí òun gbà kí ìbínú mú òun ṣìwà hù tàbí kí òun kápá ìbínú òun. (Jẹ́n. 4:6, 7) Jóṣúà ní láti pinnu bóyá kí òun sin Ọlọ́run òtítọ́ tàbí kí òun máa forí balẹ̀ fún àwọn òrìṣà. (Jóṣ. 24:15) Ohun tí Jóṣúà fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ ni pé òun fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ṣe ìpinnu tó jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, Kéènì ò ní irú àfojúsùn bẹ́ẹ̀, èyí mú kó ṣe ìpinnu tó mú un jìnnà réré sí Jèhófà.

3 Ìgbà míì sì wà tó máa pọn dandan pé kí àwa náà ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì gan-an. Bí a bá ń ṣe irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa rántí àfojúsùn wa. A gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó máa fi ògo fún Jèhófà nínú ohun gbogbo, ká sì sá fún ohunkóhun tó bá máa mú ká jìnnà sí i. (Ka Hébérù 3:12.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méje tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mú wa jìnnà sí Jèhófà.

IṢẸ́

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn níṣẹ́ lọ́wọ́?

4 Ó pọn dandan pé kí àwọn Kristẹni máa ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn àti ti ìdílé wọn. Bíbélì sọ pé bí ẹnì kan kò bá fẹ́ pèsè fún ìdílé rẹ̀, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ. (2 Tẹs. 3:10; 1 Tím. 5:8) Torí náà,  ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ni iṣẹ́ jẹ́. Àmọ́, ó gba ìṣọ́ra o! Tó o bá yan iṣẹ́ tí kò tọ́, ó lè mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Lọ́nà wo?

5. Ká tó gba iṣẹ́ kan, kí la gbọ́dọ̀ ronú lé lórí dáadáa?

5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kò níṣẹ́ lọ́wọ́, tó sì tún ṣòro láti ríṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kó o bẹ́ mọ́ iṣẹ́ èyíkéyìí tó o bá rí. Àmọ́, bí iṣẹ́ náà ò bá bá ìlànà Bíbélì mu ńkọ́? Bí iṣẹ́ náà bá máa gbà ẹ́ lákòókò, tí kò ní jẹ́ kó o gbélé, tí wàá sì máa pa ìpàdé jẹ ńkọ́? Ṣé wàá ronú pé bí iṣẹ́ kan ò tiẹ̀ dáa, ó sàn ju kéèyàn má ní iṣẹ́ kankan lọ́wọ́, kó o sì torí ìyẹn gba iṣẹ́ náà? Rántí pé, tó o bá yan iṣẹ́ tí kò dára, ńṣe ló máa mú ẹ jìnnà sí Jèhófà! (Héb. 2:1) Yálà ò ń wáṣẹ́ ni o tàbí ò ń wá bó o ṣe máa yí iṣẹ́ tó ò ń ṣe pa dà, báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání?

6, 7. (a) Kí nìdí méjì téèyàn fi lè fẹ́ láti gba iṣẹ́ kan? (b) Èwo nínú méjèèjì ni kò ní mú kó o jìnnà sí Jèhófà, kí sì nìdí?

6 Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, má ṣe gbàgbé àfojúsùn rẹ. Bi ara rẹ pé, ‘Torí kí ni mo ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí?’ Tó bá jẹ́ pé torí àtigbọ́ bùkátà ara rẹ àti ti ìdílé rẹ kẹ́ ẹ lè máa sin Jèhófà nìṣó lo ṣe ń wáṣẹ́, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Mát. 6:33) Jèhófà mọ bó ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ tàbí nígbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀. (Aísá. 59:1) Ó “mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 Pét. 2:9.

7 Tó bá wá jẹ́ pé torí kó o lè di ọlọ́rọ̀ lo ṣe ń wáṣẹ́ ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kọ́wọ́ rẹ tẹ ohun tó ò ń wá lóòótọ́. Àmọ́, ewu wà nínú kéèyàn máa ṣiṣẹ́ nítorí àtidi ọlọ́rọ̀. (Ka 1 Tímótì 6:9, 10.) Tó o bá ka owó àti iṣẹ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ, ńṣe ni wọ́n máa mú ẹ jìnnà sí Jèhófà.

8, 9. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí àwọn òbí bi ara wọn nípa iṣẹ́ wọn? Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Ẹ̀yin òbí, ẹ má gbàgbé pé àwọn ọmọ yín ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe. Kí ni àwọn ọmọ rẹ gbà pé o kà sí pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé iṣẹ́ ni àbí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà? Bí wọ́n bá rí i pé bó o ṣe máa di èèyàn pàtàkì láwùjọ àti bó o ṣe máa di olówó ló gbà ẹ́ lọ́kàn jù lọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o mọ̀ pé èyí lè mú káwọn náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ kí wọ́n sì ṣe ìpinnu tí kò dára nígbà tí wọ́n bá dàgbà? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé ìyẹn lè mú kí wọ́n má bọ̀wọ̀ fún ẹ bó ṣe yẹ mọ́? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Látìgbà tí mo ti gbọ́njú mọ bàbá mi, iṣẹ́ ló jẹ wọ́n lógún jù lọ. Ó kọ́kọ́ dà bíi pé torí kí wọ́n lè tẹ́ wa lọ́rùn ni wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, torí pé wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun wọ́n wa. Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Iṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe ṣáá ní gbogbo ìgbà. Wọ́n á sì ra àwọn nǹkan ìgbádùn tí kò pọn dandan wálé fún wa. Dípò káwọn èèyàn mọ̀ wá sí ìdílé tó ń fún àwọn míì níṣìírí láti sin Jèhófà, ọmọ bàbá olówó ni wọ́n mọ̀ wá sí. Dípò tí bàbá mi fi ń ṣiṣẹ́ kára láti wá owó, ohun tó wù mí jù lọ ni pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ìdílé wa sún mọ́ Jèhófà.”

9 Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ yín mú kẹ́ ẹ jìnnà sí Jèhófà. Àpẹẹrẹ rere ni kẹ́ ẹ fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ yín. Ẹ fi hàn wọ́n pé òótọ́ lẹ gbà gbọ́ pé kéèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀ ju kéèyàn máa kó owó tàbí àwọn nǹkan ìní jọ.—Mát. 5:3.

10. Kí ló yẹ kí ọ̀dọ́ kan ronú lé lórí kó tó yan irú iṣẹ́ tó máa ṣe?

10 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó o sì ń ronú lórí irú iṣẹ́ tó o máa ṣe nígbà tó bá yá, báwo lo ṣe lè yan iṣẹ́ tó dára? Bá a ṣe ń sọ bọ̀, ohun tó o bá fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe ló máa pinnu irú iṣẹ́ tó o máa yàn. Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ lo fẹ́ kọ́, ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ á mú kó o lè fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ? Ṣé iṣẹ́ náà kò ní mú ẹ jìnnà sí Jèhófà? (2 Tím. 4:10) Ṣé o fẹ́ dà bí ọ̀pọ̀  èèyàn nínú ayé tó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá ní owó rẹpẹtẹ nìkan ni wọ́n máa ń láyọ̀? Àbí o máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri”? (Sm. 37:25) Má ṣe gbàgbé pé ọ̀nà méjì ló wà o! Ọ̀kan á mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Èkejì á mú kó o gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ. (Ka Òwe 10:22; Málákì 3:10.) Èwo lo máa yàn nínú ọ̀nà méjèèjì? *

ERÉ ÌDÁRAYÁ

11. Kí ni Bíbélì sọ nípa eré ìdárayá? Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?

11 Bíbélì kò sọ pé ó burú láti ṣeré ìdárayá, kò sì sọ pé ńṣe ni ẹni tó bá ń ṣeré ìdárayá ń fi àkókò ṣòfò. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Eniyan a máa rí anfani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tím. 4:8, Ìròhìn Ayọ̀) Bíbélì tiẹ̀ tún sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà, “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” sì tún wà. Ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa sinmi dáadáa. (Oníw. 3:4; 4:6) Àmọ́, bí o kò bá ṣọ́ra, eré ìdárayá lè mú kó o jìnnà sí Jèhófà. Lọ́nà wo? Torí pé ó lè jẹ́ irú èyí tí kò dára lo yàn tàbí kó o máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí rẹ̀.

Tá a bá ṣe eré ìdárayá tó dára, tí a kò sì ṣe é ní àṣejù, a máa gbádùn rẹ̀ gan-an

12. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ronú lé tó o bá ń yan eré ìdárayá?

12 Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa irú eré ìdárayá tó yẹ ká máa ṣe. Ohun kan tó dájú ni pé àwọn eré ìdárayá tó gbámúṣé wà dáadáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn eré ìdárayá tàbí ohun táwọn èèyàn kà sí eré ìnàjú nínú ayé lónìí ló dá lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá, ìbẹ́mìílò àti ìṣekúṣe. Torí náà, o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa irú eré ìdárayá tí ò ń ṣe. Bi ara rẹ pé: ‘Ipa wo ni eré ìdárayá tí mò ń ṣe ń ní lórí mi? Ṣé kì í jẹ́ kí n máa hùwà ipá tàbí kí n máa rò pé orílẹ̀-èdè tèmi ló dára jù? Ṣé kì í mú kí n máa ronú pé èmi ni mo gbọ́dọ̀ borí ní gbogbo ọ̀nà? (Òwe 3:31) Ṣé kì í ná mi lówó tó pọ̀ jù? Ṣé kò lè mú àwọn míì kọsẹ̀? (Róòmù 14:21) Èmi àti àwọn wo la jọ ń ṣe eré ìdárayá náà? (Òwe 13:20) Ṣé kì í mú kí n máa fẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́?—Ják. 1:14, 15.’

13, 14. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú lórí bí àkókò tó o fi ń ṣe eré ìdárayá ṣe pọ̀ tó?

13 Tún ronú lórí bí àkókò tó ò ń lò nídìí  eré ìdárayá ṣe pọ̀ tó. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an nídìí eré ìdárayá débi pé mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè lọ sóde ẹ̀rí àti ìpàdé mọ́?’ Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìdárayá, wàá rí i pé o kò ní gbádùn wọn tó bó ṣe yẹ. Kódà, àwọn tí kì í pẹ́ jù nídìí eré ìdárayá ni wọ́n máa ń gbádùn rẹ̀ jù. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé àwọn ti kọ́kọ́ bójú tó “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” torí náà ọkàn wọn kò ní dá wọn lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ìdárayá.—Ka Fílípì 1:10, 11.

14 Ẹnì kan lè ronú pé ńṣe ni òun ń gbádùn ara òun tó bá ń fi àkókò tó pọ̀ jù ṣe eré ìdárayá, àmọ́ ńṣe ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń mú kéèyàn jìnnà sí Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kim mú kó gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó ní: “Gbogbo àpèjẹ tí wọ́n bá pè mí sí pátá ni mo máa ń lọ. Òde àríyá ni mo sì máa ń wà ní gbogbo ọjọ́ Friday, Saturday àti Sunday. Àmọ́ mo ti wá rí i báyìí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ló wà tó yẹ kí n máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ní báyìí tí mo ti di aṣáájú-ọ̀nà, agogo mẹ́fà ìdájí ni mo máa ń jí kí n lè múra òde ẹ̀rí. Torí náà, kò sí bí mo ṣe lè máa ṣe fàájì títí di aago kan tàbí aago méjì òru. Mo mọ̀ pé kò burú láti lọ síbi àríyá, àmọ́ àpọ̀jù rẹ̀ kì í jẹ́ kéèyàn lè fi àkókò ṣe nǹkan gidi. Torí náà, ó yẹ kéèyàn ṣe é níwọ̀n.”

15. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè yan ère ìdárayá tó dára?

15 Ó pọn dandan pé káwọn òbí máa pèsè jíjẹ àti mímu fún ara wọn àtàwọn ọmọ wọn. Kí wọ́n jọ máa gba ìtọ́ni látinú Bíbélì, kí wọ́n sì jọ máa gba tara wọn rò. Ó sì tún yẹ kí wọ́n máa wáyè láti ṣeré ìdárayá. Tó o bá jẹ́ òbí, má ṣe rò pé gbogbo eré ìdárayá ló burú. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ṣọ́ra fún àwọn eré ìdárayá tí kò dára. (1 Kọ́r. 5:6) Tẹ́ ẹ bá fara balẹ̀ dáadáa, ẹ lè rí eré ìdárayá tó dára tí ìdílé yín lè máa ṣe. * Nípa bẹ́ẹ̀, eré ìdárayá tí ẹ̀ ń ṣe kò ní mú kẹ́ ẹ jìnnà sí Jèhófà.

ÀJỌṢE ÌDÍLÉ

16, 17. Ohun tí kò dára wo ló ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ òbí? Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe rí lára wọn?

16 Àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa ń fẹ́ràn ara wọn gan-an. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ pé òun fẹ́ràn àwọn èèyàn òun bí ìyá ṣe máa ń fẹ́ràn ọmọ rẹ̀. (Aísá. 49:15) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí ẹnì kan nínú ìdílé bá fi Jèhófà sílẹ̀, ó máa ń dun àwọn yòókù nínú ìdílé gan-an. Arábìnrin kan tí wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ obìnrin lẹ́gbẹ́ sọ pé: “Ó bà mí nínú jẹ́ gan-an. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ló mú kó fi Jèhófà sílẹ̀?’ Ọkàn mi ò wá balẹ̀ mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara mi lẹ́bi.”

17 Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ó dájú pé Jèhófà mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Ó dun Jèhófà gan-an nígbà tí Ádámù ọmọ rẹ̀ àti èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó gbé láyé ṣáájú Ìkún-omi di ọlọ̀tẹ̀. (Jẹ́n. 6:5, 6) Àwọn tí irú nǹkan báyìí ò tíì ṣẹlẹ̀ sí rí lè má mọ bó ṣe máa ń dunni tó. Síbẹ̀, bí wọ́n bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ nínú ìdílé yín, ó léwu gan-an tó o bá lọ jẹ́ kí ìwà àìtọ́ onítọ̀hún mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fi Jèhófà sílẹ̀ nínú ìdílé rẹ ńkọ́? Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní máa banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ?

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn òbí máa dá ara wọn lẹ́bi tí ọmọ wọn bá fi Jèhófà sílẹ̀?

18 Má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi torí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ẹni tó bá ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣe ìrìbọmi ló máa ‘ru ẹrù ara rẹ̀.’ Òun ló sì máa pinnu bóyá òun á máa sin Jèhófà nìṣó. (Gál. 6:5) Torí náà, ẹni tó bá ṣẹ̀ ló máa dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níwájú Jèhófà. Jèhófà ò ní dá ẹ lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀  ẹlòmíì. (Ìsík. 18:20) Bákan náà, má ṣe dá àwọn míì lẹ́bi. Fi hàn pé o ní ọ̀wọ̀ fún ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí. Má ṣe dá àwọn alàgbà tó ń dáàbò bo ìjọ lẹ́bi. Èṣù ni kó o kọjú ìjà sí. Má ṣe kọjú ìjà sí àwọn alàgbà. Má sì ṣe jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ mú kó o jìnnà sí Jèhófà.—1 Pét. 5:8, 9.

Kò burú tó o bá ní in lọ́kàn pé èèyàn rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì máa pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà

19, 20. (a) Kí ni òbí kan lè ṣe tí kò fi ní banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí wọ́n bá yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́? (b) Kí ló yẹ kí irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ní lọ́kàn?

19 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá lọ ń bínú sí Jèhófà nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ? Irú ìbínú bẹ́ẹ̀ lè mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà gbọ́dọ̀ rí i pé ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà pọ̀ ju èyí tó o ní fún ìdílé rẹ lọ. Kí o má bàa banú jẹ́ jù, rí i pé ohunkóhun kò bá àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Òwe 18:1) Gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì sọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lọ́kàn rẹ fún un. (Sm. 62:7, 8) Má ṣe máa dọ́gbọ́n wá ọ̀nà láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́. Má ṣe máa kàn sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bóyá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí fóònù. (1 Kọ́r. 5:11) Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni kó o gbájú mọ́. (1 Kọ́r. 15:58) Arábìnrin tí inú rẹ̀ bà jẹ́ torí pé wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́ yẹn sọ pé, “Mo mọ̀ pé ọwọ́ mi gbọ́dọ̀ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà kò sì gbọ́dọ̀ yingin. Kó lè jẹ́ pé bí ọmọ mi bá pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà, ó máa ṣeé ṣe fún mi láti ràn án lọ́wọ́.”

20 Bíbélì sọ pé ìfẹ́ a “máa retí ohun gbogbo.” (1 Kọ́r. 13:4, 7) Kò burú tó o bá ní in lọ́kàn pé èèyàn rẹ kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣì máa pa dà wá sọ́dọ̀ Jèhófà. Ọdọọdún ni ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ ń ronú pìwà dà tí wọ́n sì ń pa dà wá sínú ètò Jèhófà. Jèhófà kì í bínú sí wọn mọ́ tí wọ́n bá ti ronú pìwà dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ‘ṣe tán láti dárí jì wọ́n.’—Sm. 86:5.

ṢE ÌPINNU TÓ BỌ́GBỌ́N MU

21, 22. Irú ìpinnu wo lo fẹ́ máa ṣe?

21 Jèhófà ti fún àwa ẹ̀dá èèyàn ní òmìnira láti yan àwọn ohun tá a bá fẹ́ láti ṣe. (Ka Diutarónómì 30:19, 20.) Àmọ́, àwọn ìpinnu tó dára ló yẹ ká máa fi òmìnira yìí ṣe. Ó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa mú mi yà kúrò lójú ọ̀nà tó tọ́ ni mò ń ṣe? Ṣé kì í ṣe pé iṣẹ́ tí mò ń ṣe àti eré ìdárayá tí mo yàn láàyò ti mú kí n jìnnà sí Jèhófà? Ṣé àjọṣe àárín èmi àti ìdílé mi ò sì ti mú kó ṣòro fún mi láti sún mọ́ Ọlọ́run?’

22 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn rẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Torí náà, kò sí ohun tó lè mú wa jìnnà sí Jèhófà, àyàfi tá a bá ṣe àwọn ìpinnu tí kò dára. (Róòmù 8:38, 39) Kò sì yẹ ká jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. Rí i dájú pé o kò jẹ́ kí ohunkóhun mú ẹ jìnnà sí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí ohun mẹ́rin míì tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mú wa jìnnà sí Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 10 Wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bó o ṣe lè yan iṣẹ́ tó o máa ṣe ní orí 38 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì.

^ ìpínrọ̀ 15 Àwọn àbá lórí bí èèyàn ṣe lè yan eré ìnàjú tó gbámúṣé wà ní ojú ìwé 62 sí 73 nínú ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.