Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  No. 6 2017

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ AYÉ YÌÍ TI BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?

Ṣé Ayé Yìí Ti Bà Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe Àbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́?

ÌRÒYÌN burúkú kan látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni aráyé fi bẹ̀rẹ̀ ọdún 2017. Ní oṣù January, àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lágbàáyé kéde pé àjálù ńlá kan tí kò ṣẹlẹ̀ rí máa tó bá ayé yìí. Wọ́n lo aago ńlá kan tó ń ka wákàtí tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock láti fi ṣàpèjúwe bí ayé yìí ṣe sún mọ́ àjálù náà tó. Wọ́n sún ọwọ́ tó ń ka ìṣẹ́jú síwájú sí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú àáyá. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ohun tó wà lójú Doomsday Clock yìí fi hàn pé ayé ti wà ní aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú méjì àtààbọ̀, tí ìyẹn sì fi hàn pé a ti sún mọ́ àkókò tí àjálù máa bá gbogbo ayé! Láti ọgọ́ta [60] ọdún tí aago yìí ti ń ka wákàtí, àkókò yìí ni aráyé sún mọ́ àjálù yìí jù lọ!

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pinnu láti tún aago yìí kà tó bá di ọdún 2018 láti fi mọ bí aráyé ṣe sún mọ́ àjálù tó. Tó bá di ìgbà yẹn, ṣé aago yìí ṣì tún máa fi hàn pé àjálù tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí ti fẹ́ dé bá ayé? Kí ni èrò rẹ? Ṣé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe? Ó lè dà bíi pé ìbéèrè yẹn ṣòro láti dáhùn. Kódà, èrò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pàápàá kò ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ náà. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà pé àjálù kan ń bọ̀ tó máa pa gbogbo ayé run.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára. Wọ́n sọ pé àwọn ní ẹ̀rí tó dá àwọn lójú pé títí láé ni àwọn èèyàn á máa gbé ayé torí pé ayé ò lè pa rẹ́ láé, wọ́n tún sọ pé ìgbé ayé wa máa dára sí i. Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà lóòótọ́ pé nǹkan máa rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?