Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Milford Sound

 Ilẹ̀ Àti Àwọn Èèyàn

Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand

Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè New Zealand

NǸKAN bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún sẹ́yìn ni àwọn ẹ̀yà Maori rìnrìn àjò gba alagbalúgbú òkun tó fẹ̀ lọ salalu, kí wọ́n tó wá tẹ̀dó sí orílẹ̀-èdè New Zealand. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i pé ilẹ̀ ibẹ̀ yàtọ̀ sí ti erékùṣù olóoru Polynesia tí wọ́n ti ń bọ̀. Àwọn òkè pọ̀ níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí, àwọn òkìtì yìnyín àti ìsun omi tó lọ́wọ́ọ́wọ́ wà níbẹ̀, yìnyín sì tún máa ń jábọ́ níbẹ̀. Nǹkán bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kó débẹ̀, àwọn ẹ̀yà míì láti ilẹ̀ Yúróòpù kó wá síbẹ̀. Lónìí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè New Zealand ló fẹ́ràn àṣà àwọn ẹ̀yà méjéèjì tó tẹ ibẹ̀ dó, ìyẹn àwọn tó wá láti Polynesia àti àwọn Anglo-Saxon. Ìgboro ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó wà ní orílẹ̀-èdè yìí ń gbé. Wellington ni olú ìlú ibẹ̀, òun sì ni ìlú tó jìnnà sí gúúsù jù lọ lágbàáyé.

Ẹrẹ̀ tó ń hó kùṣùkùṣù tó wà ní Erékùṣù Àríwá

 Orílẹ̀-èdè New Zealand ò fi bẹ́ẹ̀ lókìkí tó àwọn orílẹ̀-èdè tó kù, àmọ́ torí pé àwọn nǹkan tó rẹwà gan-an pọ̀ níbẹ̀, àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ lọ sí ibẹ̀ lọ́dọọdún fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta.

Igi fern yìí máa ń ga ju ilé alájà-méjì lọ

Láti ọdún 1948 ni kò ti sí ẹyẹ tó ń jẹ́ takahe yìí mọ́

Oríṣiríṣi àwọn ẹranko ló wà ní orílẹ̀-èdè New Zealand, ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn oríṣi ẹyẹ tí kì í fò pọ̀ sí jù lọ láyé. Ẹranko kan tó dá bí aláǹgbá tí wọ́n ń pè ní Tuatara pọ̀ níbẹ̀, ẹranko yìí lè lò tó ọgọ́rùn-ún [100] ọdún láyé! Díẹ̀ lára àwọn oríṣi ẹranko tó ń fọ́mọ́ lọmú tá a lè rí ní orílẹ̀-èdè yìí ni àwọn àdán, ẹja àbùùbùtán àti dolphin.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́fà [120] ọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù lórílẹ̀-èdè New Zealand. Ó kéré tán, à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè mọ́kàndínlógún [19], tó fi mọ́ èdè ìbílẹ̀ Polynesia tí wọ́n ń pè ní Niuean, èdè Rarotongan, èdè Samoan, àti èdè Tongan.

Àwọn ẹ̀yà Maori wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n sì ń jó sí orin ìbílẹ̀ wọn kan