Tí ẹnì kan bá jẹ́ kí ìdẹwò borí òun, lára ohun tó lè yọrí sí ni pé ìdílé rẹ̀ lè tú ká, ó lè kó àìsàn burúkú tàbí kí ẹ̀rí ọkàn máa dà á láàmú. Báwo la ṣe lè yẹra fún ìdẹwò?

Kí ni ìdẹwò?

Ìdẹwò ni kí ọkàn èèyàn máa fà sí nǹkan kan, pàápàá ohun tí kò dára. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o wà nínú ilé ìtajà kan, o sì rí ohun kan tó wọ̀ ẹ́ lójú. Ó ṣe ẹ́ bíi pé kó o jí i, o sì mọ̀ pé kò sẹ́nì kankan tó máa mọ̀. Àmọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ ń sọ fún ẹ pé kó o má ṣe jí i! Lo bá gbé èrò burúkú náà kúrò lọ́kàn, o sì bá tìẹ lọ. Bó o ṣe borí ìdẹwò nìyẹn tó o sì di aṣẹ́gun.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

 

Ti pé nǹkan kan jẹ́ ìdẹwò fún ẹnì kan, ìyẹn ò sọ ọ́ di èèyàn burukú. Bíbélì sọ pé gbogbo wa la máa ń kojú ìdẹwò. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì ni ohun tá a ṣe nígbà ìdẹwò náà. Àwọn kan máa ń gba èròkérò náà láyè, tí wọ́n á sì kó wọnú ìdẹwò. Àwọn míì máa ń tètè gbé e kúrò lọ́kàn.

“Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.” ​—Jákọ́bù 1:14.

Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká tètè ṣe ohun tó yẹ nígbà ìdẹwò?

Bíbélì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó máa ń mú kí èèyàn hùwà tí kò tọ́. Jákọ́bù 1:15 sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn náà [ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́], nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí ẹnì kan bá ń ro èròkérò ṣáá, ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn yẹn, bó ṣe jẹ́ pé bó pẹ́, bó yá aboyún máa bí ọmọ tó wà ní ikún rẹ̀. Àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe kí èròkérò má bàa sọ wá di ẹrú. Ó dájú pé a lè ṣẹ́gun eròkérò.

BÍBÉLÌ LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

 

Èròkérò lè wọni lọ́kàn lóòótọ́, àmọ́, a lè gbé e kúrò lọ́kàn. Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn nǹkan míì, bóyá ká ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan, ká máa bá àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀, tàbí ká máa ro àwọn nǹkan tó dáa. (Fílípì 4:8) Ó tún yẹ ká máa ro ohun tó lè jẹ́ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ tá a bá lọ kó sínú ìdẹwò, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, ó lè fìyà jẹ wá tàbí kó ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Diutarónómì 32:29) Àdúrà tún lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Jésù Kristi sọ pé: ‘Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.’​—Mátíù 26:41.

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”​—Gálátíà 6:7.

 Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ de ìdẹwò?

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀

 

Ó yẹ kó o kọ́kọ́ gbà pé ńṣe ni ìdẹwò dà bí pańpẹ́, wẹ́rẹ́ báyìí sì làwọn tí kò gbọ́n tàbí àwọn tí kò kíyè sára máa ń kó sí i, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ sì máa ń burú gan-an. (Jákọ́bù 1:14) Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá kó sí ìdẹwò ìṣekúṣe, aburú ńlá gbáà ló máa ń yọrí sí.​—Òwe 7:​22, 23.

BÍBÉLÌ LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

 

Jésù Kristi sọ pé: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mátíù 5:29) Kì í ṣe ohun tí Jésù ń sọ ni pé ká yọ ojú wa gangan dà nù o! Kákà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé, tá a bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn tá a sì fẹ́ rí ìyè àìnípẹ̀kun, a ò gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ẹ̀yà ara wa hùwà àìtọ́, ńṣe ni kó dà bíi pé a ti sọ wọ́n di òkú. (Kólósè 3:5) Ìyẹn sì gba pé kí èèyàn dìídì pinnu pé òun ò ní gbà kí ìdẹwò borí òun. Ọkùnrin olóòótọ́ kan gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”​—Sáàmù 119:37.

Kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá fún èèyàn láti kó ara rẹ̀ níjàánu. Ìdí sì ni pé, “ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mátíù 26:41) Torí náà, a lè ṣe àṣìṣe nígbà míì. Àmọ́, tá a bá fi hàn pé ohun tá a ṣe yẹn dùn wá gan-an, tá a sì ń sapá gidigidi láti má ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, Ẹlẹ́dàá wa tó “jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ” máa dárí jì wá. (Sáàmù 103:8) Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!

“Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” ​—Sáàmù 130:3.