A ti kà nípa àwọn áńgẹ́lì nínú ìwé, a ti rí àwòrán wọn lóríṣiríṣi, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú fíìmù. Àmọ́ àwọn wo ni àwọn áńgẹ́lì, kí sì ni iṣẹ́ wọn?

Àwọn wo ni áńgẹ́lì?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

 

Àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run Olódùmarè kọ́kọ́ dá. Lẹ́yìn náà ló wá dá ayé àti ọ̀run àtàwọn ẹ̀dá alààyè tó wà nínú wọn, tó fi mọ́ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Wọ́n lágbára gan-an ju àwa èèyàn lọ, ibi tí Ọlọ́run wà lókè ọ̀run ni àwọn náà ń gbé; ìyẹn ibi téèyàn ò lè dé, téèyàn ò sì lè fojú rí. (Jóòbù 38:4, 7) Bíbélì pe àwọn ẹ̀dá alágbára yìí ní “ẹ̀mí.” Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run yìí la tún ń pé ní “áńgẹ́lì.”Sáàmù 104:4. *

Áńgẹ́lì mélòó ló wà? Wọ́n pọ̀ gan-an. “Ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún” tàbí “ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún” àwọn áńgẹ́lì ló yí ìtẹ́ Ọlọ́run ká. (Ìṣípayá 5:11) Tá a bá ní kí á wo iye wọn bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì yẹn, a jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì ló wà lọ́run!

“Mo sì rí . . .  ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ní àyíká ìtẹ́ . . . , iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.”Ìṣípayá 5:11.

Kí ni àwọn áńgẹ́lì ti ṣe láyé àtijọ́?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

 

Àwọn áńgẹ́lì sábà máa ń ṣe agbẹnusọ tàbí òjíṣẹ́ fún Ọlọ́run. * Bíbélì tún fi hàn pé Ọlọ́run máa ń rán wọn pé kí wọ́n lọ ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kan. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan láti lọ bù kún Ábúráhámù, áńgẹ́lì yẹn sì ni kò jẹ́ kó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:11-18) Áńgẹ́lì kan fara han Mósè láàárín igi kékeré kan tó ń jó, ó sì rán an níṣẹ́ kan tó máa tún ayé àwọn èèyàn ṣe. (Ẹ́kísódù 3:1, 2) Nígbà táwọn kan sọ wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnìún, ‘Ọlọ́run rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.’Dáníẹ́lì 6:22.

“Nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà fara [han Mósè] nínú ọwọ́ iná ní àárín igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.”Ẹ́kísódù 3:2.

 Kí ni àwọn áńgẹ́lì ń ṣe báyìí?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

 

A ò lè mọ gbogbo nǹkan tí àwọn áńgẹ́lì ń ṣe lónìí. Àmọ́, Bíbélì sọ pé wọ́n máa ń ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run.Ìṣe 8:26-35; 10:1-22; Ìṣípayá 14:6, 7.

Jèhófà fi ìran kan han baba ńlá náà Jékọ́bù lójú àlá, níbẹ̀ ó rí àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí “àkàsọ̀” kan tó wà láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 28:10-12) Pẹ̀lú àlá tí Jákọ́bù lá yìí, ó ṣeé ṣe kó gbà pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń rán àwọn áńgẹ́lì níṣẹ́ wá sórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n lè wá ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́. Àwa náà sì gbà lóde òní pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn.Jẹ́nẹ́sísì 24:40; Ẹ́kísódù 14:19; Sáàmù 34:7.

“Àkàsọ̀ kan [sì wà] tí a gbé dúró sórí ilẹ̀ ayé, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run; sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run wà, tí wọ́n ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ lórí rẹ̀.”Jẹ́nẹ́sísì 28:12.

^ ìpínrọ̀ 6 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan wà tí wọ́n kọ̀ láti fi ara wọn sábẹ́ àkóso Ọlọ́run, ó sì pe àwọn ángẹ́lì búburú yìí ní “ẹ̀mí èṣù.”Lúùkù 10:17-20.

^ ìpínrọ̀ 11 Kódà, ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a lò fún “áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “ìránṣẹ́.”