ỌPỌLỌ mélòó lo ní? Tó o bá sọ pé “ẹyọ kan,” òótọ́ lo sọ. Àmọ́, ìṣùpọ̀ iṣan kan wà nínú ara wa tí iṣẹ́ rẹ̀ lágbára gan-an tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi pè é ní “ọpọlọ kejì.” Ìṣùpọ̀ iṣan yìí ni wọ́n ń pè ní enteric nervous system (ENS). Kì í ṣe inú orí wa ni ìṣùpọ̀ iṣan yìí wà o, inú ikùn wa ló wà.

Nǹkan kékeré kọ́ ló ń ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ara wa kó tó di pé oúnjẹ dà kó sì wúlò fún ara. Torí náà, ó wúni lórí gan-an pé ńṣe ni ọpọlọ wa máa ń darí ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn yìí, ìyẹn ENS, pé kó máa bójú tó bí oúnjẹ á ṣe máa dà nínú ara wa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí ìṣùpọ̀ iṣan yìí ń ṣe kò tó ti ọpọlọ, síbẹ̀ ó lágbára gan-an. Nínú ara èèyàn, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì [200] sí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] mílíọ̀nù iṣan ló para pọ̀ di ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀nà ọ̀fun dé inú ikùn wa. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ká ní inú ọpọlọ ni ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí ti ń ṣiṣẹ́ ni, iṣan tí ọpọlọ máa nílò láti ṣiṣẹ́ á ti pọ̀ jù. Abájọ tí ìwé náà The Second Brain fi sọ pé: “Ohun tó dáa jù náà ni bí ìṣùpọ̀ iṣan yìí ṣe gbájú mọ́ bí á ṣe máa mú kí oúnjẹ dà nínú ara.”

“ILÉ IṢẸ́ KẸ́MÍKÀ”

Kí oúnjẹ tó lè dà nínú ara, àwọn kẹ́míkà inú ara kan gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ lórí oúnjẹ náà ní ìwọ̀n tó yẹ àti ní àkókò pàtó, kí wọ́n sì tún darí àwọn oúnjẹ náà gba ibi tó yẹ nínú ara. Ìdí nìyẹn tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Gary Mawe fi sọ pé apá tó ń mú oúnjẹ dà nínú ara wa dà bí “ilé iṣẹ́ kẹ́míkà.” Ìyàlẹ́nu gbáà ni bí ètò inú ara yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, awọn sẹ́ẹ̀lì kan wà nínú ìfun wa tó máa ń dá kẹ́míkà mọ̀, èyí ló máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ irú kẹ́míkà tó wà nínú oúnjẹ tá a bá jẹ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí á wá gbé ìsọfúnni náà lọ sínú ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn. Ìsọfúnni yìí ló máa mú kí ara gbé kẹ́míkà tiẹ̀ jáde tó máa lè bá èyí tó wà nínú oúnjẹ náà ṣiṣẹ́ láti mú kí oúnjẹ náà dà lọ́nà tí á fi ṣe ara lóore. Tí ásíìdì inú oúnjẹ bá sáfẹ́rẹ́ tàbí pọ̀ jù èyí tí ara lè bá ṣiṣẹ́, ìṣùpọ̀ iṣan ENS ló máa bójú tó gbogbo rẹ̀.

Lẹ́nu kan, a lè sọ pé apá tó ń mú kí oúnjẹ dà nínú ikùn dà bí ẹrọ ńlá kan tí ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn ń darí. Ìṣùpọ̀ iṣan yìí ló ń darí bí oúnjẹ ṣe ń lọ láti ọ̀nà ọ̀fun sí inú ikùn tí á sì mú kí ikùn wa lọ oúnjẹ tá a bá jẹ kúnná. Ọ̀nà àrà tó ń gbà ṣe iṣẹ́ yìí dà bíi ti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá, tó máa gbé bébà, tó máa gé e, tó máa tẹ̀ ẹ́, tó sì máa gbé e jáde.

Ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn yìí tún máa ń dáàbò bò wá. Ó ṣeé ṣe kí àwọn nǹkan kan wà nínú oúnjẹ tá à ń jẹ tó lè ṣàkóbá fún ara wa. Àmọ́, torí pé inú ikùn wa ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn wà, èyí ló máa ń dáàbò bò wá. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a jẹ ohun kan tó lè ṣàkóbá fún wa, kíá ni ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí á mú kí ikùn wa pọ májèlé náà jáde tàbí ká yà á dà nù.

Ó Ń ṢIṢẸ́ PẸ̀LÚ ỌPỌLỌ

Ó lè dà bíi pé ńṣe ni ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí ń dá ṣiṣẹ́ láìsí ọwọ́ ọpọlọ níbẹ̀, àmọ́ ní  ti gidi, ńṣe ni àwọn méjéèjì jọ ń ṣisẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìṣùpọ̀ iṣan yìí ló máa ń rán kẹ́míkà lọ sínú ọpọlọ tó ń jẹ́ ká mọ̀ tí ebi bá ń pa wá àti ìwọ̀n oúnjẹ tó yẹ ká jẹ. Ó tún máa ń rán àwọn sẹ́ẹ̀lì kan lọ sí inú ọpọlọ láti jẹ́ ká mọ̀ pé a ti yó; tí a bá sì jẹun jù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í bì.

Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka àpilẹ̀kọ yìí, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti máa fura pé ńṣe ni ọpọlọ, ọ̀nà ọ̀fun àti ikùn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ti kíyè sí pé tó o bá jẹ oúnjẹ tó ní ọ̀rá tàbí òróró, ara rẹ máa ń yá gágá? Ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn pé ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí ló fi ìsọfúnni ‘amóríyá’ ránṣẹ́ sí ọpọlọ, tí ọpọlọ sì ṣiṣẹ́ lé e lórí láti mú kí ara wa yá gágá. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí àwọn èèyàn fi sábà máa ń jẹ́ ìpápánu nígbà tí nǹkan bá sú wọn. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ láti rí i bóyá wọ́n á lè rí nǹkan kan ṣe sí ìṣùpọ̀ iṣan yìí láti fi tọ́jú àwọn tó ní ìdààmú ọkàn.

Nígbà míì, inú wa á kàn ṣàdédé máa kùn. Kò dédé rí bẹ́ẹ̀ o, ìwádìí fi hàn pé ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó ti rẹ ọpọlọ, tí ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí sì darí ẹ̀jẹ̀ kúrò nínú ikùn; èyí sì jẹ́ ọ̀nà míì tó fi hàn pé ńṣe ni ọpọlọ àti ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. Tó bá rẹ ọpọlọ, ó máa ń gbé ìsọfúnni kan lọ sí inú ìṣùpọ̀ iṣan ENS tó máa ń yí bí ọ̀nà ọ̀fun wa ṣe ń ṣiṣẹ́ pa dà, èyí sì máa ń mú kí èébì gbé wa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣùpọ̀ iṣan yìí lè jẹ́ kí èèyàn ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ a ò lè fi ronú, kò sì lè darí ìpinnu wa. Ní kúkúrú, ìṣùpọ̀ iṣan ENS yìí kì í ṣe ọpọlọ rárá. Bí àpẹẹrẹ, a ò lè fi ṣàkójọ orin, a ò lè fi ṣírò owó, a ò sì lè fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá. Síbẹ̀ ohun àrà ni, ìyàlẹ́nu gbáà ló ṣì jẹ́ fún àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọn ò sì tíì mọ̀ nípa rẹ̀. Torí náà, nígbàkigbà tó o bá fẹ́ jẹun, ronú nípa bí ìṣùpọ̀ iṣan inú ikùn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọpọlọ láti gbé ìsọfúnni káàkiri ara, láti bójú tó bí oúnjẹ ṣe ń dà àti láti dáàbò bò wá kí ohun tá à ń jẹ má bàa ṣàkóbá fún wa!