Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JÍ! No. 3 2017 | Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá Lóòótọ́?

Ṣé o gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? Àbí o rò pé èrò àwọn èèyàn ni wọ́n kàn kọ síbẹ̀?

Ìwé ìròyìn “Jí!” yìí ṣàlàyé ẹ̀rí mẹ́ta tó mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Lóòótọ́ Ni “Ọlọ́run Mí Sí” Bíbélì?

Àwọn kan gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá. Àwọn mí ì rò pé àwọn ìtàn àròsọ àtijọ́ àti àwọn òfin tí èèyàn kọ ló wà nínú rẹ̀.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bíbélì Péye ní Gbogbo Ọ̀nà

Tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn nǹkan tá a dé ayé bá ṣe rí gẹ́lẹ́ kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ṣàlàyé wọn, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn ilẹ̀ ọba ṣe máa bẹ̀rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe máa pa run, ó tún dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì

Ẹ̀yin òbí, ṣé ó máa ń ṣe yín bíi pé kẹ́ ẹ má ṣe yan iṣẹ́ ilé kankan fún àwọn ọmọ yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kà nípa bí iṣẹ́ ilé ṣe máa mú kí àwọn ọmọ yín ní ìwà àgbà tó sì máa mú kí wọ́n láyọ̀.

Ṣé “Ọpọlọ Méjì” La Ní?

Inú ikùn wa ni ohun tó dà bí ilé iṣẹ́ kẹ́míkà yìí wà. Iṣẹ́ wo ló ń ṣe nínú ara wa?

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ

Onímọ̀ Nípa Ètò Orí Kọ̀ǹpútà Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Fan Yu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìṣirò, ó gbà pé ńṣe ni gbogbo ohun alààyè ṣàdédé wà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ́n ṣe sọ. Àmọ́ ní báyìí, ó ti wá gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun alààyè. Kí nìdí?

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Angeli

A ti kà nípa àwọn áńgẹ́lì nínú ìwé, a ti rí àwòrán wọn lóríṣiríṣi, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú fí ìmù. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Irun Ara Ẹran Omi Tó Ń Jẹ́ Otter

Àwọn ẹranko inú omi kan máa ń ní ọ̀rá lábẹ́ awọ wọn, èyí sì máa ń mú kí ara wọn móoru kí òtútù máa bàa tètè mú wọn. Àmọ́, ọ̀nà mí ì ni ara otter ń gbà móoru.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Túbọ̀ Lómìnira?

O lè máa rò ó pé o kì í ṣe ọmọdé mọ́, àmọ́ àwọn òbí ẹ lè má gbà bẹ́ẹ̀. Kí lo lè máa ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ?

Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

Tó bá jẹ́ pé èèyàn ló kọ ọ́, ṣé a wá lè pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Èrò ta ló wà nínú Bíbélì?