Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  No. 3 2016

 ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Yanjú Ọ̀rọ̀

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Yanjú Ọ̀rọ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, ṣé ẹ máa ń lè yanjú rẹ̀ nítùbí ìnùbí àbí ńṣe lọ̀rọ̀ náà máa ń di iṣu ata yán-an-yàn-an? Tó bá jẹ́ pé ńṣe lọ̀rọ̀ náà máa ń le sí i, ẹ ṣì lè rí nǹkan ṣe sí i. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ̀ pé kì í ṣe bákan náà ni ọkùnrin àti obìnrin ṣe máa ń sọ èrò ọkàn wọn jáde. *

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ọ̀pọ̀ obìnrin sábà máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó gbọ́ ojútùú rẹ̀. Nígbà míì ó lè jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ni wọ́n ti máa rí ojútùú sí ìṣòro náà.

“Ara máa ń tù mí tí mo bá ti sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi, tí mo sì mọ̀ pé ọkọ mi fara mọ́ ohun tí mo sọ. Tí mo bá ti sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ náà ti tán lọ́kàn mi nìyẹn, láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan màá ti gbàgbé ẹ̀.”—Sirppa. *

“Ọkàn mi ò lè kúrò lórí ìṣòro náà àfi tí mo bá ráyè sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún ọkọ mi. Tí mo bá ti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, kò ní jẹ mí lọ́kàn mọ́.”—Ae-Jin.

“Ńṣe ló dà bí iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́. Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, màá wá máa yiiri ọ̀rọ̀ náà wò, èyí sì máa jẹ́ kí n lóye ohun tó fa ìṣòro náà.”—Lurdes.

Bí ìṣòro ṣe máa yanjú làwọn ọkùnrin máa ń rò. Kò sì yà wá lẹ́nu torí pé tí ọkọ bá ran ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro kan, ó máa ń mú inú ọkọ dùn pé òun wúlò fún aya òun. Wọ́n gbà pé táwọn bá wá ojútùú sí ìṣòro ìyàwó àwọn, á jẹ́ káwọn túbọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣe é gbára lé. Torí náà, ó máa ń ya ọkọ lẹ́nu tí ìyàwó rẹ̀ kò bá tètè fara mọ́ ojútùú tó mú wá. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Kirk sọ pé: “Mi ò mọ ìdí tó o fi máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro tí o kò bá fẹ́ ká wá ojútùú sí i!”

Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní The Seven Principles for Making Marriage Work sọ pé: “Ó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó gbani nímọ̀ràn. O gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí ẹnì kejì rẹ mọ̀ pé o lóye  ohun tó ṣẹlẹ̀, kó o sì bá a kẹ́dùn, kó o tó wá sọ ọ̀nà tẹ́ ẹ máa gbà yanjú ìṣòro náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyàwó rẹ kò retí pé kó o yanjú ìṣòro náà, ohun tó kàn fẹ́ ni pé kó o fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ òun.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Fún àwọn ọkọ: Fi kọ́ra láti máa fara balẹ̀ gbọ́ aya rẹ kó o sì sapá láti mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Tomás sọ pé: “Nígbà míì tí mo bá ti tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, mo máa ń bi ara mi pé ‘àǹfààní wo nìyẹn wá ṣe báyìí?’ Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ohun tí ìyàwó mi fẹ́ kò ju pé kí n kàn tẹ́tí sí òun.” Ọkọ kan tó ń jẹ́ Stephen náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Mo ti rí i pé ó dára kí n jẹ́ kí ìyàwó mi sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ láì já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ ọn lẹ́nu. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tó bá fi máa sọ̀rọ̀ náà tán, á sọ pé ọ̀rọ̀ náà ti tán lọ́kàn òun.”

Gbìyànjú èyí: Nígbà míì tí ìyàwó rẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, jẹ́ kó bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ délẹ̀ kó o tó gbà á nímọ̀ràn. Ojú rẹ̀ ni kó o máa wò, kó o sì fọkàn sí ohun tó ń sọ. Bákan náà, mi orí rẹ láti fi hàn pé o fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tún ọ̀rọ̀ náà sọ láti fi hàn pé gbogbo ohun tó sọ ló yé ẹ. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Charles sọ pé: “Nígbà míì, ohun tí ìyàwó mi kàn fẹ́ mọ̀ ni pé ọ̀rọ̀ tó ń sọ yé mi àti pé ẹ̀yìn rẹ̀ ni mo wà.”—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 1:19.

Fún àwọn ìyàwó: Sọ ohun tó o fẹ́ fún ọkọ rẹ. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Eleni sọ pé: “A máa ń retí pé kí ọkọ wa mọ ohun tá a fẹ́, àmọ́ ìgbà míì wà tá a ní láti fúnra wa sọ ohun tá a fẹ́ gan an.” Ìyàwó kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ynez dá àbá yìí, ó ní: “Mo lè sọ pé, ‘ohun kan wà tó ń jẹ mí lọ́kàn, mo sì fẹ́ kó o tẹ́tí sí mi. Mi ò sọ pé kó o yanjú ìṣòro náà, àmọ́ mo fẹ́ kó o mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi.”

Gbìyànjú èyí: Tí ọkọ rẹ bá yára sọ ohun tó jẹ́ ojútùú sí ìṣòro tẹ́ ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, má ṣe parí èrò sí pé kò ro bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ń gbìyànjú láti mú kí ọ̀rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn rẹ. Ìyàwó kan tó ń jẹ́ Ester sọ pé: “Dípò tí màá fi bínú, ohun tí mo máa ń rò ni pé ọkọ mi kà mí sí, ó sì fẹ́ gbọ́rọ̀ mi, ó sì tún ń wá bọ́rọ̀ náà ṣe máa yanjú.”—Ìlànà Bíbélì: Róòmù 12:10.

Fún àwọn tọkọtaya: Ohun tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa la máa ń ṣe sí wọn. Àmọ́, láti sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan lọ́nà tí ìṣòro náà á fi yanjú, o ní láti ro ohun tí ẹnì kejì rẹ máa fẹ́ kó o ṣe fóun. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ọkọ kan tó ń jẹ́ Miguel sọ pé: “Tó o bá jẹ́ ọkọ, múra tán láti fetí sílẹ̀. Tó o bá jẹ́ ìyàwó, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, múra tán láti gbọ́ ojútùú sí ìṣòro náà. Tẹ́ ẹ bá ń gba ti ara yín rò, ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ máa jàǹfààní.”—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 3:8.

^ ìpínrọ̀ 4 Oríṣiríṣi ọ̀nà tá a máa jíròrò nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin lè má bá bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára gbogbo ọkọ àti ìyàwó mu. Àmọ́, àwọn ìlànà tá a máa jíròrò lè ran tọkùnrin tobìnrin tó ti ṣègbéyàwó lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ẹnì kejì wọn, kí wọ́n sì jọ máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.