ONÍRÚURÚ nǹkan ló wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì, látorí àwọn èèyàn títí dorí ilẹ̀ wọn. Wọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oko wíìtì, gíréèpù àti igi ólífì. Odò kan wà lápá gúùsù tí kò fẹ̀ ju kìlómítà mẹ́rìnlá (14 km) lọ, odò yìí ló sì pààlà sí orílẹ̀-èdè Sípéènì àti ilẹ̀ Áfíríkà.

Gúùsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù ni orílẹ̀-èdè yìí wà, oríṣiríṣi ẹ̀yà ló sì kó wá síbẹ̀. Lára wọn ni àwọn ará Fòníṣíà, Gíríìkì àti Carthaginian. Nígbà táwọn ará Róòmù ṣẹ́gun ìlú yìí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni tí wọ́n sì tẹ̀ dó síbẹ̀, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Hispania. Lẹ́yìn náà àwọn ẹ̀yà Visigoth àti Moor wá ń gbébẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá àwọn ẹ̀yà yìí pa àṣà ìṣẹ́dálẹ̀ wọn tì.

Lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn tó ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Sípéènì tó mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́rin [68]. Èyí tó pọ̀ jù  ló wá gba oòrùn sára kí ara wọn lè móoru, àwọn míì wá sí àwọn etíkun golden beaches, àwọn míì sì wá wo àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé. Oúnjẹ àwọn ará Sípéènì tún máa ń fa àwọn àlejò mọ́ra. Lára oúnjẹ wọn ni àwọn nǹkan tí wọ́n pa látinú òkun, àyangbẹ ẹlẹ́dẹ̀, ọbẹ̀ ata, sàláàdì àti ewébẹ̀ tí wọ́n sè tàbí tí wọ́n yí pọ̀ mọ́ òróró ólíífì. Wọ́n tún láwọn oúnjẹ míì táwọn èèyàn kárí ayé ń gba tiẹ̀, bíi Spanish omelets, paella àti tapas.

Ọ̀kan lára oúnjẹ wọn ni Mariscada

Wọ́n ń jo ijó flamenco

Àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì tún kóni mọ́ra wọ́n sì lọ́yàyà. Ọ̀pọ̀ ló máa ń sọ pé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì làwọn, àmọ́ díẹ̀ lára wọn ló máa ń lọ sí Máàsì. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn láti ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà àti Látìn Amẹ́ríkà ti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń bá wọn jíròrò, àwọn ìjíròrò náà sì ti sèso rere. Torí pé ọ̀pọ̀ lára wọn la ti ràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́.

Lọ́dún 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àtààbọ̀ [10,500] ló yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ tàbí ṣàtúnsẹ àádọ́rin [70] Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìjọsìn wọn. Àwọn aláṣẹ àdúgbò ló fún wa ní ilẹ̀ tá a fi kọ́ àwọn kan lára àwọn ilé náà. Ká bàa lè ran àwọn tó kó wá sí orílẹ̀-èdè Sípéènì lọ́wọ́, a tún máa ń ṣe ìpàdé ní èdè ọgbọ̀n [30] míì láfikún sí èdè Sípáníìṣì. Lọ́dún 2016, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́sàn-àn ó lé mẹ́fà [186,000] ló wá sí ìpàdé pàtàkì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe láti fi rántí ikú Jésù Kristi.