Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Jí!  |  No. 2 2017

 Kókó Iwájú Ìwé | Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Agbára Abàmì

Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Agbára Abàmì Ń Pọ̀ Sí I!

Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Agbára Abàmì Ń Pọ̀ Sí I!

“Àwọn fíìmù tó ní àwọn oṣó, ẹlẹyẹ, iwin, àǹjọ̀nú, babaláwo àtàwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn míì ló wá pọ̀ níta báyìí.”—Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal.

LÓDE òní àwọn ohun tó wọ́pọ̀ jù tí wọ́n ń gbé jáde nínú ìwé, fíìmù àtàwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà ni àwọn èèyàn tó ní agbára abàmì, bí oṣó lọ́mọdé àti lágbà, àjẹ́, emèrè, iwin àtàwọn àǹjọ̀ọ̀nú. Kí ló fàá táwọn èèyàn fi ń nífẹ̀ẹ́ sírú àwọn nǹkan yìí? *

Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá kan tó ń jẹ́ Claude Fischer sọ pé: “Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn tó nígbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀mí àìrí ti wá pọ̀ kọjá àfẹnusọ. Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èèyàn kan nínú mẹ́ta ló nígbàgbọ́ nínú wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé nígbà kan ẹnì kan nínú mẹ́wàá ló gbà wọ́n gbọ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn ti lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń woṣẹ́, pé àwọn sì nígbàgbọ́ nínú ẹ̀mí àìrí àti ilé àwọn àǹjọ̀ọ̀nú.”

Torí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn fíìmù tó dá lórí àwọn ẹ̀mí òkùnkùn tó ń gbénú èèyàn ni wọ́n sábà ń gbé jáde báyìí. Ọ̀gbẹ́ni Michael Calia tiẹ̀ sọ nínú ìwé ìròyìn The Wall Street Journal, pé: “Àwọn fíìmù tí iwin, àwọn ṣẹranko-ṣènìyàn, àtàwọn mùjẹ̀-mùjẹ̀ kúnnú ẹ̀ ló gbòde kan báyìí, èyí ló mú káwọn èèyàn tó lẹ́mìí òkùnkùn máa pọ̀ sí i.”

Ìròyìn kan fi hàn pé “nǹkan bí ìdajì àwọn èèyàn tó wà láyé ló nígbàgbọ́ nínú ẹ̀mí àìrí, torí náà wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀mí àìrí yìí nínú àwọn ìwé tó dá lórí àṣà ìbílẹ̀.” Bákan náà, ìwádìí kan tí Christopher Bader àti Carson Mencken tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà “fi hàn pé nǹkan bí ìdá méje sí mẹ́jọ nínú èèyàn mẹ́wàá lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló gbà gbọ́ nínú oníruúrú agbára abàmì.”

Ṣé àṣà tí kò léwu ni tá a bá ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òkùnkùn tàbí tí à ń wá agbára abàmì?

^ ìpínrọ̀ 4 Àgbára abàmì: Èyí jẹ́ ohun kan “tí àwọn onímọ̀ sáyẹ̀ǹsì kò lè ṣàlàyé rẹ̀ tó sì ta ko òfin ìṣẹ̀dá.”—Ìwé atúmọ̀ èdè Merriam-Webster’s Learner’s Dictionary.