Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Ìwé Tó Kàn Dáa Ni Bíbélì?

Ṣé Ìwé Tó Kàn Dáa Ni Bíbélì?

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn ni wọ́n parí kíkọ Bíbélì. Látìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé míì ni wọ́n ti kọ́ tó sì ti kógbá wọlé. Àmọ́ Bíbélì ṣì wà títí dòní. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan díẹ̀ nípa Bíbélì.

  • Ọ̀pọ̀ àwọn tó lẹ́nu láwùjọ ló ti gbógun ti Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tó ń jẹ́ An Introduction to the Medieval Bible sọ nípa bí nǹkan ṣe rí ní àwọn ìlú tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá sí kẹẹ̀ẹ́dógún. Ó ní, ‘ẹni tó bá ní Bíbélì lédè ìbílẹ̀ tó sì ń kà á lè jẹ̀bi ẹ̀sùn aṣòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì.’ Ńṣe ni àwọn ọ̀mọ̀wé tó túmọ̀ Bíbélì sáwọn èdè ìbílẹ̀ tàbí tó ń sọ pé káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ̀mí ara wọn wewu. Wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan nínú wọn.

  • Láìka gbogbo bí wọ́n ṣe gbógun ti Bíbélì sí, Bíbélì ṣì ni ìwé tí wọ́n pín kiri jù lọ látìgbà yẹn títí dòní. Nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún odindi tàbí apá kan Bíbélì ni wọ́n ti tẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800] èdè. Èyí yàtọ̀ sí àwọn ìwé tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn míì tó jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn èèyàn ló máa ń ní in, kì í sì í pẹ́ tó fi máa ń kógbá wọlé.

  • Bíbélì ti mú kí àwọn èdè tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bí Martin Luther ṣe túmọ̀ Bíbélì sí èdè Jámánì ti mú kí èdè náà túbọ̀ gbèrú. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà pé Bíbélì King James Version tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde ni ìwé tó tíì mú kí èdè Gẹ̀ẹ́sì gbayì jù lọ.

  • Ìwé The Oxford Encyclopedia of the Books of the Bible sọ pé, Bíbélì ti kópa pàtàkì nínú àṣà àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù. Kì í ṣe ilé ìjọsìn nìkan ni wọ́n ti ń lò ó, àmọ́ wọ́n ti lò ó nínú òfin, ìṣèlú, kíkọ̀wé, yíya àwòrán àti lónírúurú àwọn ọ̀nà míì.

Èyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú kí Bíbélì yàtọ̀ sáwọn ìwé míì. Àmọ́, kí ló mú káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n nílé lóko? Kí sì nìdí táwọn kan fi fẹ̀mí ara wọn wewu torí rẹ̀? Ìdí ni pé Bíbélì fún wa láwọn ìsọfúnni tó mọ́gbọ́n dání nípa bó ṣe yẹ ká gbé ìgbésí ayé wa àti bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó fa ogun àti ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ìṣòro yìí máa dópin, ó sì ṣàlàyé bó ṣe máa ṣẹlẹ̀.

 Bíbélì Kọ́ Wa ní Ìwà Rere àti Bá A Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ẹ̀kọ́ ìwé ṣe pàtàkì. Síbẹ̀, ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè Kánádà tó ń jẹ́ Ottawa Citizen sọ pé, ‘ti pé èèyàn kàwé gboyè rẹpẹtẹ kò túmọ̀ sí pé ẹni náà máa níwà ọmọlúwàbí.’ Ọ̀pọ̀ àwọn tó kàwé rẹpẹtẹ tó jẹ́ olóṣèlú àti oníṣòwò ló máa ń kówó jẹ, wọ́n sì máa ń lu jìbìtì. Iléeṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Edelman tiẹ̀ sọ pé ‘èyí ló fà á táwọn èèyàn ò fi fọkàn tán wọn.’

Àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí béèyàn ṣe lè ní ìwà rere kó sì sún mọ́ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì. Ó jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ “òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá.” (Òwe 2:9) Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Stephen tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] wà ní ẹ̀wọ̀n lórílẹ̀-èdè Poland. Inú ẹ̀wọ̀n yẹn ló wà tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó kọ́ nínú rẹ̀. Ó sọ pé: “Ní báyìí mo ti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé, ‘bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.’ Mo sì tún ti kọ́ bí màá ṣe máa ṣàkóso ìbínú òdì mi.”—Éfésù 4:31; 6:2.

Ọ̀kan nínú àwọn ìmọ̀ràn tó ran Stephen lọ́wọ́ wà nínú Òwe 19:11 tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Ní báyìí, tẹ́nì kan bá múnú bí Stephen, ńṣe ló máa ń sinmẹ̀dọ̀ táá sì fi àwọn ìlànà Bíbélì tó bá yẹ sílò. Stephen sọ pé: “Mo ti rí i pé Bíbélì ni ìwé atọ́nà tó dáa jù lọ.”

Obìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́tanú fi àbùkù kan Maria tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kódà, ojú ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fàbùkù náà kàn án. Àmọ́ kàkà kí Maria fèsì pa dà, ńṣe ló rọra bá tiẹ̀ lọ. Obìnrin náà wá ronú pé ìwà tóun hù kò dáa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Maria. Lẹ́yìn oṣù kan, obìnrin náà rí Maria, ó dì mọ́ ọn, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má ṣe bínú. Obìnrin náà kíyè sí i pé ẹ̀sìn tí Maria ń ṣe ló mú kó  níwà tútù, kó sì rára gba nǹkan sí. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Obìnrin tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹlẹ́tanú àtàwọn márùn-ún nínú ìdílé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Jésù Kristi sọ pé a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀. (Mátíù 11:19) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà pé àwọn ìlànà Bíbélì gbéṣẹ́ gan-an. Wọ́n máa ń jẹ́ ká lè hùwà rere. Wọ́n sì máa ń mú kí ‘aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n,’ wọ́n máa ń ‘mú ọkàn yọ̀,’ wọ́n sì máa ń ‘mú kí ojú mọ́lẹ̀’ kedere nípa ṣíṣàlàyé bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 19:7, 8.

Bíbélì Ṣàlàyé Ohun Tó Ń Fa Ìyà àti Ogun

Nígbà tí àrùn burúkú kan bá ń jà lọ ràn-ìn, àwọn èèyàn máa bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí ohun tó fa àjàkálẹ̀ àrùn náà. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká wádìí ohun tó fa ìyà tó ń jẹ aráyé. Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ ní ti pé, ó sọ ìtàn ìgbésí ayé wa, ìyẹn ìgbà tí wàhálà wa bẹ̀rẹ̀.

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé ìṣòro wa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Wọ́n fẹ́ fúnra wọn pinnu ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa, ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ fún wa. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7) Ó ṣeni láàánú pé látìgbà yẹn wá lọ̀pọ̀ èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe tinú wọn nìkan. Kí wá ni àbárèbábọ̀ èyí? Dípò ká ní ayọ̀ àti òmìnira tá à ń wá, ogun, ìnilára àti ìwàkiwà ló kún inú ìtàn àwa èèyàn. (Oníwàásù 8:9) Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn . . . láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àmọ́, ìròyìn kan tó ń múni lọ́kàn yọ̀ ni pé láìpẹ́ gbogbo wàhálà tí àwa èèyàn ti fọwọ́ ara wa fà máa dópin.

Bíbélì Fún Wa ní Ìrètí

Bíbélì fi dá wa lojú pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìyà àti ìwà ibi máa bá a lọ títí láé. Ìdí sì ni  pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń pa òfin rẹ̀ mọ́. Bíbélì sọ pé àwọn ẹni burúkú máa “jẹ nínú èso ọ̀nà wọn,” ìyẹn ni pé wọ́n máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn. (Òwe 1:30, 31) Lọ́wọ́ kejì, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

‘Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’1 Timothy 2:3, 4

Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé máa di Párádísè máa nímùúṣẹ nígbà tí “Ìjọba Ọlọ́run” bá dé. (Lúùkù 4:43) Ìjọba yìí máa ṣàkóso gbogbo ayé, ó sì máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run. Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù gbà, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba náà máa nasẹ̀ dé ayé, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ . . . lórí ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 6:10.

Àwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n máa gbà pé Ẹlẹ́dàá ni Alákòóso kì í ṣe èèyàn. Àwọn ìṣòro bí ìwọra, ẹ̀tanú, ogun, àìríná àìrílò àti kíkó owó jẹ máa dópin. Nígbà yẹn, Ìjọba kan ṣoṣo láá máa ṣàkóso ayé, ìlànà kan náà sì ni gbogbo èèyàn á máa tẹ̀ lé.—Ìṣípayá 11:15.

Èèyàn gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ kó tó lè dé inú ayé tuntun. Ìwé 1 Tímótì 2:3, 4 sọ pé: ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ Òtítọ́ yìí ní nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó  sọ nípa àwọn òfin àti ìlànà tó wà fún àwọn tó fẹ́ gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ wà nínú Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù Kristi ṣe. (Mátíù, orí 5 sí 7) Tó o bá ń ka àwọn orí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, ronú nípa bí ayé ṣe máa rí tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Jésù sọ.

Ṣé ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Bíbélì ni ìwé tí wọ́n pín kiri jù lọ láyé? Rárá o! Àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú rẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run ló dárí àwọn tó kọ ọ́. Bí ìpínkiri Bíbélì ṣe gbòòrò mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun láìka èdè tí wọ́n ń sọ, àti pé ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn gbádùn àwọn ìbùkún tí Ìjọba rẹ̀ máa mú wá.—Ìṣe 10:34, 35.