ÀWỌN olùṣèwádìí láti ilẹ̀ Yúróòpù rí ohun kan tó wú wọn lórí nígbà tí wọ́n dé àgbègbè Central America àti South America ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún. Wọ́n rí àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ onírù gígùn tó ní àwọ̀ mèremère tó ń fò lọ lójú òfúrufú. Àgbègbè olóoru tó wà nílẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn ẹyẹ yìí sì ń gbé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwòrán ẹyẹ yìí sórí máàpù láti fi ṣe àmì ilẹ̀ tó dára rèǹtèrente tí wọ́n ṣàwárí.

Takọtabo wọn ló máa ń ní àwọ̀ mèremère, èyí mú kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn ẹyẹ aláwọ̀ mèremère míì. Ẹyẹ ayékòótọ́ gbọ́n, wọ́n tún máa ń gbé pọ̀ bí agbo kan. Igbe wọn sì máa ń han èèyàn létí. Wọ́n lè tó ọgbọ̀n [30] nínú agbo kan. Láàárọ̀ kùtù, gbogbo wọn á gbéra láti wá oúnjẹ lọ, èyí sì ní nínú, èso àtàwọn oúnjẹ míì. Wọ́n sábà máa ń lo èékánná ẹsẹ̀ wọn láti fi gbé oúnjẹ, wọ́n á sì fi àgógó ẹnu wọn fa oúnjẹ náà ya. Kódà, wọ́n lè la ẹ̀pà tí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ le gbagidi! Lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun tán, wọ́n sábà máa ń fò lọ sí ẹsẹ̀ òkè tàbí etí odò láti lọ jẹ amọ̀. Amọ̀ yìí máa ń pa oró tó bá wà nínú oúnjẹ tí wọ́n jẹ, á sì fún wọn ní àwọn èròjà míì tó wúlò fún ara wọn.

“Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀.”Oníwàásù 3:11

Akọ kan àti abo kan ló máa ń gbé pọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Àwọn méjèèjì ló sì  máa ń pawọ́ pọ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn. Onírúurú àwọn ẹyẹ yìí máa ń kọ́ ìtẹ́ wọn sínú ihò igi, ihò etí odò, inú ilé ikán tàbí inú ihò àpáta. Níbẹ̀, àá rí àwọn takọtabo tí wọ́n ń bá ara wọn yọ ìdọ̀tí inú ìyẹ́. Àwọn ọmọ wọn máa ń dàgbà láàárín oṣù mẹ́fà, síbẹ̀ wọ́n ṣì máa wà pẹ̀lú àwọn òbí wọn fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Àwọn ayékòótọ́ tó bá ń gbé inú igbó lè lò tó ọgbọ̀n [30] ọdún sí ogójì [40] ọdún láyé. Àmọ́, èyí táwọn èèyàn ń sìn nílé lè lò tó ọgọ́ta [60] ọdún láyé. Onírúurú àwọn ẹyẹ yìí ló wà, díẹ̀ lára wọn ló wà nínú àwòrán yìí.

Ayékòótọ́ aláwọ̀ ewé, tó tún máa ń ní àwọ̀ pupa. Ó máa ń gùn tó sẹ̀ǹtímítà márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95]

Ayékòótọ́ aláwọ pupa. Ó máa ń gùn tó sẹ̀ǹtímítà márùnlélọ́gọ́rin [85]

Ayékòótọ́ Hyacinth. Ó máa ń gùn tó ọgọ́rùn-ún sẹ̀ǹtímítà [100]. Òun ló tóbi jù nínú gbogbo àwọn ayékòótọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó kílógírámù kan ààbọ̀