Obìnrin kan tó ń jẹ́ Patricia sọ pé: “NÍGBÀ TÍ MO WÀ LỌ́MỌDÉ, WỌ́N MÁA Ń BÚ ARA WỌN GAN-AN NÍNÚ ÌDÍLÉ WA, WỌ́N SÌ MÁA Ń PARIWO MỌ́RA WỌN. Ìyẹn ò jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń dárí jini. Kódà nígbà tí mo dàgbà, téèyàn bá ṣẹ̀ mí, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni mo fi máa ń gbé ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, tí mi ò sì ní rí oorun sùn.” Tí ìgbésí ayé ẹni bá kún fún ìbínú ní gbogbo ọjọ́, téèyàn sì ń gbé ọ̀rọ̀ sọ́kàn, èèyàn ò ní láyọ̀, ìlera rẹ̀ ò sì ní dára. Ìwádìí tiẹ̀ fi hàn pé, àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kì í dárí jini:

 • Wọ́n máa ń jẹ́ kí ìbínú dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn àtàwọn míì, èyí sì lè mú kí wọ́n máa dá nìkan wà

 • Wọ́n máa ń kanra, wọ́n máa ń ṣàníyàn, wọ́n sì máa ń ní ìdààmú ọkàn

 • Wọ́n máa ń fìgbà gbogbo ronú nípa ohun tẹ́nì kan ṣe fún wọn, débi pé wọn ò ní lè gbádùn ayé wọn

 • Wọ́n máa ń mọ̀ pé àwọn ò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́

 • Nǹkan máa ń tojú sú wọn gan-an, wọ́n sì máa ń ní onírúurú àìlera, bí ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ọkàn àti ìrora, oríkèé ara lè máa ro wọ́n tàbí kí orí máa fọ́ wọn *

KÍ NI ÌDÁRÍJÌ? Ìdáríjì túmọ̀ sí pé kí èèyàn gbójú fo àìdáa tẹ́nì kan ṣe sí wa, kí èèyàn má ṣe bínú mọ́, kó má ṣe gbé e sọ́kàn, kó má sì ronú láti gbẹ̀san. Èyí kò túmọ̀ sí pé a fara mọ́ ohun tí ẹni náà ṣe, tàbí pé ohun náà kò tó nǹkan, kò sì túmọ̀ sí pé à ń díbọ́n bíi pé nǹkan kan kò ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la dìídì pinnu láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wa, torí pé a fẹ́ kí àlàáfíà jọba, a ò sì fẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn míì bà jẹ́.

Ẹni tó bá ní àròjinlẹ̀ ló máa ń dárí jini. Ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìdáríjì mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa. (Róòmù 3:23) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”​—⁠Kólósè 3:⁠13.

Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti sọ pé, dídárí ji àwọn míì jẹ́ ara ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́  wọn, ìfẹ́ yìí sì ni Bíbélì pè ní “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Kódà, ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì Mayo Clinic sọ pé àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ń dárí jini:

 • Wọ́n máa ń ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn, wọ́n máa ń gba ti àwọn èèyàn rò, wọ́n máa ń fi òye báni lò, wọ́n sì máa ń yọ́nú sí ẹni tó bá ṣẹ̀ wọ́n

 • Ọpọlọ wọn máa ń jí pépé, wọ́n sì máa ń sún mọ́ Ọlọ́run

 • Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn, nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ tojú sú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sábà kanra

 • Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ní ìdààmú ọkàn

DÁRÍ JI ARA RẸ. Ìwé kan tó ń jẹ́ Disability & Rehabilitation sọ pé kí èèyàn dárí ji ara rẹ̀ “ló máa ń ṣòro jù,” àmọ́ “ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù tí èèyàn bá fẹ́ ní ìlera tó dáa,” torí pé ó máa ń jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé kí ara sì yá gágá. Kí ló lè mú kó o máa dárí ji ara rẹ?

 • Má ṣe máa wo ara rẹ bí ẹni tí kò lè ṣe àṣìṣe rárá, àmọ́ ńṣe ni kó o gbà pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣe àṣìṣe, ìyẹn ò sì yọ ìwọ náà sílẹ̀.​—⁠Oníwàásù 7:⁠20

 • Kọ́gbọ́n nínú àṣìṣe rẹ, kí ohun tó ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kan má bàa tún ṣe ẹ́ nígbà míì

 • Máa ṣe sùúrù fún ara rẹ; fi sọ́kàn pé àwọn ìwà tàbí àṣà kan tó ti mọ́ni lára kì í lọ bọ̀rọ̀.​—⁠Éfésù 4:​23, 24

 • Àwọn tó yẹ kó o máa bá ṣọ̀rẹ́ ni àwọn tó lè fún ẹ níṣìírí láti máa ṣe ohun tó dára, tí wọ́n gbà pé nǹkan ṣì máa dára, tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì lè bá ẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.​—⁠Òwe 13:⁠20

 • Tó o bá ṣẹ ẹnì kan, gbà pé o jẹ̀bi, kó o sì tètè tọrọ àforíjì. Tó o bá ń sapá láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín ìwọ àtàwọn míì, ọkàn tìẹ náà á balẹ̀.​—⁠Mátíù 5:​23, 24

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ DÁRA GAN-AN!

Nígbà tí Patricia tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá dẹni tó máa ń dárí jini. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe bọ́ lọ́wọ́ ìbínú burúkú tó fẹ́ bayé mi jẹ́ nìyẹn. Mi ò fi ayé ni ara mi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò fayé ni àwọn míì lára mọ́. Àwọn ìlànà Bíbélì ń fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ohun tó dáa jù lọ ló sì ń fẹ́ fún wa.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ron sọ pé: “Kò sóhun tí mo lè ṣe nípa ohun táwọn míì ń rò àti ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ mo lè ṣe nǹkan kan nípa èrò àti ìṣe tèmi. Tí mo bá fẹ́ kí àlàáfíà jọba, mi ò gbọ́dọ̀ máa di àwọn míì sínú. Mo wá rí i pé mi ò lè sọ pé ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni mí kí n tún máa di àwọn èèyàn sínú. Ọkàn mi ti wá balẹ̀ gan-an báyìí.”

^ ìpínrọ̀ 8 Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: Orí ìkànnì Mayo Clinic àti Johns Hopkins Medicine àti ìwé Social Psychiatry and Psychiatric Epidemiology.