Kí Lèrò Rẹ?

Ta ni ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run tó ń fúnni ní ẹ̀bùn?

“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.”​Jákọ́bù 1:17.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká mọ ẹ̀bùn pàtàkì kan tí Ọlọ́run fún wa àti bó ṣe ju gbogbo ẹ̀bùn lọ.