Sẹ́ ìwọ náà máa ń ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run àti àwọn tó ń gbé níbẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bó ṣe ń ṣe ẹ́ ló ń ṣe àwọn míì. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn tí máa ń jíròrò ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn kan gbà gbọ́ pé àwọn baba ńlá tí àwọn gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ló wà lọ́run. Àwọn kan sì máa ń fọkàn yàwòrán pé ibi tó tura ni ọ̀run, tí àwọn áńgẹ́lì àti àwọn èèyàn rere tó ti kú ń gbé. Síbẹ̀ àwọn míì gbà pé ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òrìṣà ló ń gbé ní ọ̀run.

Ọ̀pọ̀ ló sọ pé kò sí ẹni tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run torí pé kò sí ẹni tó ti lọ sí ọ̀run bọ̀ láti wá ṣàlàyé fún wa bí ọ̀run ṣe rí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ o. Torí pé ọ̀run ni Jésù Kristi ń gbé kó tó wá sáyé. Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” Torí náà, Jésù sọ ohun tó ṣojú rẹ̀ nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ.”Jòhánù 6:38; 14:2.

Ọlọ́run ni Bàbá Jésù, Jèhófà ni orúkọ rẹ̀, ọ̀run sì ni “ilé” Jèhófà wà. (Sáàmù 83:18) Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ló lè ṣàlàyé bí ọ̀run ṣe rí, kò sí ẹni tó lè ṣàlàyé tó wọn. Wọ́n ti fi àwọn ìran àgbàyanu han àwọn èèyàn olóòótọ́ kan láti fi ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run fún wa.

Àwọn àpilẹ̀kọ tó kù máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn apá kan nínú Bíbélì tó ṣàlàyé àwọn ìran táwọn kan rí. Bí o ṣe ń gbé àwọn ìran náà yẹ̀ wò, mọ̀ dájú pé ọ̀run yìí kì í ṣe ibi téèyàn lè fojú rí, kò sì sí ohun téèyàn lè fọwọ́ kan níbẹ̀. Torí náà, dípò tí Ọlọ́run ì bá fi ṣàlàyé fún wa lọ́nà tẹ̀mí, tí kò sì ní ṣeé ṣe fún wa láti lóye rárá, Ọlọ́run lo àwọn ìràn yìí láti jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run lọ́nà táá fi yé wa dáadáa. Àwọn ìran náà máa jẹ́ kó o lóye àwọn tó ń gbé ní ọ̀run tó ní “ọ̀pọ̀ ibùjókòó.”