LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ Sunday kan láàárín ọdún 1520 sí 1523, àwọn èèyàn ìlú Meaux, tó jẹ́ ìlú kékeré kan nítòsí ìlú Paris, gbọ́ ohun kan tó yà wọ́n lẹ́nu ní ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n gbọ́ tí wọ́n ka ìwé Ìhìn Rere fún wọn ní èdè Faransé tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wọn, dípò èdè Látìn!

Nígbà tó yá, ọ̀gbẹ́ni Jacques Lefèvre d’Étaples (èdè Látìn, Jacobus Faber Stapulensis), tó túmọ̀ ìwé yìí kọ̀wé sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tímọ́tímọ́. Ó ní: “Ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ bí Ọlọ́run ṣe ń sún ọkàn àwọn mẹ̀kúnnù láwọn ìlú kan láti gba Ọ̀rọ̀ rẹ̀.”

Ní àkókò yẹn, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àtàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nílùú Paris kò fàyè gba títúmọ̀ Bíbélì sí èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ. Kí ló wá sún ọ̀gbẹ́ni Lefèvre tó fi túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé? Báwo ló sì ṣe ran àwọn mẹ̀kúnnù lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Ó WÁ Ọ̀NÀ LÁTI LÓYE ÌWÉ MÍMỌ́ DÁADÁA

Kí ọ̀gbẹ́ni Lefèvre tó bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì, ó ti kọ́kọ́ wá bó ṣe máa mú kí ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ ìsìn bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu. Ó kíyè sí i pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ àṣìṣe táwọn adàwékọ ṣe ti mú kí ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé tí wọ́n kọ tipẹ́tipẹ́ yí pa dà. Torí náà, kó báa lè mọ ìtúmọ̀ àwọn ìwé tí wọ́n ti kọ tipẹ́tipẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò fínnífínní nínú Bíbélì Latin Vulgate tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń lò.

Àyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ tó ṣe yìí jẹ́ kó rí i pé “téèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . ó máa ń fúnni láyọ̀ tó ga.” Torí náà, ọ̀gbẹ́ni Lefèvre jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ó sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì.

Lọ́dún 1509, ọ̀gbẹ́ni Lefèvre tẹ oríṣi ìwé Sáàmù * márùn-ún jáde lédè Látìn káwọn èèyàn lè fi wọ́n wéra, títí kan àtúnṣe tó ṣe sí Bíbélì Vulgate. Lefèvre kò ṣe bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ìgbà ayé rẹ̀, ńṣe ló sapá láti lóye ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì “túmọ̀ sí gan-an.” Ọ̀nà tó ń gbà ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ ní ipa tó lágbára lórí àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì míì àtàwọn alátùn-únṣe ìsìn.​—Wo àpótí náà “ Bí Ìsapá Lefèvre Ṣe Nípa Lórí Martin Luther.”

Àtẹ tí wọ́n fi to àwọn orúkọ òye tí Ọlọ́run ní, bó ṣe wà nínú ìwé Fivefold Psalter, ẹ̀dà ti 1513

Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n bí Lefèvre sí, ó sì gbà pé ohun tó lè mú kí ṣọ́ọ̀ṣì sunwọ̀n sí i ni pé kí wọ́n fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ gan-an kọ́ àwọn mẹ̀kúnnù. Àmọ́, báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe máa ṣe àwọn mẹ̀kúnnù láǹfààní nígbà tó jẹ́ pé èdè Látìn ni wọ́n fi kọ èyí tó pọ̀ jù lára rẹ̀?

ÌTÚMỌ̀ BÍBÉLÌ TÓ WÀ FÚN GBOGBO ÈÈYÀN

Ohun tí Lefèvre sọ nínú ọ̀rọ̀ tó fi bẹ̀rẹ̀ ìwé Ìhìn Rere jẹ́ kó hàn pé ó wù ú láti mú kí Bíbélì wà ní èdè abínibí àwọn èèyàn

Ọ̀gbẹ́ni Lefèvre nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Ìdí nìyẹn to fi fẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lè rí i kà. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ó tẹ ìwé Ìhìn Rere lédè Faransé jáde ní oṣù June, ọdún 1523. Ó jẹ́ ìdìpọ̀ kékeré méjì. Torí pé ìwé náà kéré, owó rẹ̀ kò sì ju ìlàjì èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀, èyí mú kó rọrùn fún àwọn mẹ̀kúnnù láti rà á.

 Inú àwọn mẹ̀kúnnù dùn sí ìgbésẹ̀ yìí gan-an. Tọkùnrin tobìnrin ló ń hára gàgà láti ka ọ̀rọ̀ Jésù ní èdè abínibí wọn, débi pé láàárín oṣù díẹ̀ péré, gbogbo ẹ̀dà ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì [1,200] tí wọ́n tẹ̀ ló tán pátá.

Ó LO ÌGBOYÀ LÁTI ṢÈTÌLẸ́YÌN FÚN BÍBÉLÌ

Nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí Lefèvre kọ nípa ìwé Ìhìn Rere, ó ṣàlàyé pé ohun tó mú kí òun túmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé ni pé kí “àwọn mẹ̀kúnnù” tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì lè “ní òye òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi ti àwọn tó ní Bíbélì èdè Látìn lọ́wọ́.” Àmọ́, kí ló fà á tí Lefèvre fi ń hára gàgà pé kí àwọn mẹ̀kúnnù náà lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì?

Ọ̀gbẹ́ni Lefèvre mọ̀ pé èrò àwọn èèyàn àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ní ipa búburú lórí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. (Máàkù 7:7; Kólósè 2:8) Ó sì dá a lójú pé àkókò ti tó láti mú Ìhìn Rere dé “ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n má báa tún máa fi ẹ̀kọ́ àjèjì ṣi àwọn èèyàn lọ́nà mọ́.”

Ọ̀gbẹ́ni Lefèvre tú àṣírí àwọn tó ń ta ko títúmọ̀ Bíbélì sí èdè Faransé. Ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà àgàbàgebè wọn, ó ní: “Báwo ni [àwọn èèyàn] ṣe máa lè pa gbogbo àṣẹ Jésù Kristi mọ́, bí wọn kò bá fojú ara wọn rí, kí wọ́n sì fetí ara wọn gbọ́ Ìhìn Rere Ọlọ́run ní èdè abínibí wọn?”​—Róòmù 10:14.

Kò yani lẹ́nu pé, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní Yunifásítì tó wà nílùú Paris gbìyànjú láti pa Lefèvre lẹ́nu  mọ́. Ní oṣù August, ọdún 1523, wọ́n tako títúmọ̀ Bíbélì sí èdè ìbílẹ̀, wọ́n sọ pé “ó lè ṣàkóbá fún Ṣọ́ọ̀ṣì.” Ká ní kì í ṣe pé Francis Kìíní tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Faransé dá sí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ì bá ka Lefèvre sí aṣòdì sí ṣọ́ọ̀ṣì.

BÓ ṢE PARÍ IṢẸ́ ÌTÚMỌ̀ NÁÀ NÍ BÒÓKẸ́LẸ́

Ọ̀gbẹ́ni Lefèvre kò jẹ́ kí awuyewuye táwọn èèyàn ṣe lórí iṣẹ́ rẹ̀ dí i lọ́wọ́ láti parí títúmọ̀ Bíbélì. Nígbà tó parí iṣẹ́ títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì lọ́dún 1524, (èyí tí wọ́n pè ní Májẹ̀mú Tuntun), ó tẹ ìwé Sáàmù jáde lédè Faransé káwọn onígbàgbọ́ báa lè máa gbàdúrà “pẹ̀lú ìfọkànsìn, kó sì ti ọkàn wọn wá.”

Àwọn olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìsìn Sorbonne kò fàkókò ṣòfò rárá, kíá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tọ pinpin iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí Lefèvre ṣe. Ni wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n dáná sun ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì náà ní gbangba, wọ́n sì kéde pé àwọn ìwé míì tó kọ “ń ṣagbátẹrù àwọn ẹ̀kọ́ Luther tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì.” Nígbà tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní kó wá jẹ́jọ́, Lefèvre pinnu láti má ṣe “sọ ohunkóhun,” ó sì sá lọ sí ìlú Strasbourg. Nígbà tó débẹ̀, ó ń bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì náà lọ ní bòókẹ́lẹ́. Ohun tó ṣe yìí mú kí àwọn kan sọ pé ojo ni, síbẹ̀ èrò rẹ̀ ni pé èyí jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ tí òun lè gbà bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí kò mọyì “péálì” iyebíye, ìyẹn òtítọ́ inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Mátíù 7:6.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tó sá kúrò nílùú, Ọba Francis Kìíní ní kí Lefèvre máa kọ́ Charles ọmọ òun, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin lẹ́kọ̀ọ́. Iṣẹ́ yìí jẹ́ kí Lefèvre rí àyè láti parí iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì. Lọ́dún 1530, Olú Ọba Charles Karùn-ún fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tẹ odindi Bíbélì tí Lefèvre túmọ̀ sí èdè Faransé jáde. Wọn ò tẹ ìwé náà lórílẹ̀-èdè Faransé, ìlú Antwerp, lórílẹ̀-èdè Belgium ni wọ́n ti lọ tẹ̀ ẹ́. *

ỌWỌ́ RẸ̀ KÒ TẸ ÀFOJÚSÙN RẸ̀

Ọ̀gbẹ́ni Lefèvre nírètí pé bó pẹ́ bó yá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì á pa ẹ̀kọ́ àwọn èèyàn tì, wọ́n á sì pa dà máa fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kọ́ni. Tọkàntara ló fi gbà pé “ẹ̀tọ́ àti ojúṣe gbogbo Kristẹni ló jẹ́ láti ka Bíbélì fúnra wọn kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” Ìdí nìyẹn tó fi ṣiṣẹ́ kára kí gbogbo èèyàn lè rí Bíbélì kà nílé lóko. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ àfojúsùn rẹ̀ pé kí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì máa fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì kọ́ni, a ò lè fojú kéré akitiyan tí Lefèvre ṣe kí àwọn mẹ̀kúnnù lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 8 Ìwé Fivefold Psalter pín ìwé Sáàmù sí ọ̀nà márùn-ún, ó sì tún ní apá kan tí wọ́n fi to àwọn orúkọ òye tí wọ́n fi ń pe Ọlọ́run àti lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.

^ ìpínrọ̀ 21 Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1535, atúmọ̀ èdè ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó ń jẹ́ Olivétan tẹ ìtúmọ̀ Bíbélì tirẹ̀ jáde. Bíbélì tí wọ́n kọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ló gbé ìtumọ̀ rẹ̀ kà. Àmọ́, ìtúmọ̀ Bíbélì tí Lefèvre ṣe ló gbára lé nígbà tó ń túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì.