Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àkọ̀

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run

“Jọ̀wọ́ béèrè lọ́wọ́ . . . àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá ojú ọ̀run pẹ̀lú, wọn yóò sì sọ fún ọ. Èwo nínú gbogbo ìwọ̀nyí ni kò mọ̀ dáadáa pé ọwọ́ Jèhófà ni ó ṣe èyí?”Jóòbù 12:7, 9.

NÍ OHUN tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tà [3,000] ọdún sẹ́yìn, Jóòbù kíyè sí i pé a lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run látara àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Bí àwọn ẹyẹ ṣe máa ń ṣe tún máa ń jẹ́ kí wọ́n fi wọ́n ṣe àpèjúwe tàbí àfiwé. Ọ̀pọ̀ ibi tí Bíbélì ti tọ́ka sí ẹyẹ ojú ọ̀run kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìgbésí ayé àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.

IBI TÍ ALÁPÀÁǸDẸ̀DẸ̀ Ń TẸ́ ÌTẸ́ RẸ̀ SÍ

Alápàáǹdẹ̀dẹ̀

Àwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù mọ ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ bí ẹni mowó. Inú òrùlé ló sábà máa ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Àwọn kan tiẹ̀ kọ́ ìtẹ́ wọn sínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹyẹ yìí fẹ́ràn láti kọ́ ìtẹ́ wọn sínú tẹ́ńpìlì lọ́dọọdún, kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn láìsí ìyọlẹ́nu kankan.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Kórà ló kọ Sáàmù 84. Láàárín oṣù mẹ́fà, ọ̀sẹ̀ kan péré lẹni yìí fi máa ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ ló ti kíyè sí àwọn ìtẹ́ ẹyẹ tó wà ní àyíká tẹ́ńpìlì. Ó wu òun náà kó dà bí ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tó ń gbé inú ilé Jèhófà. Ó sọ pé: “Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí, àárò rẹ̀ ń sọ mí. . . . Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé, àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọba mi, ati Ọlọrun mi.” (Sáàmù 84:1-3, Bíbélì Mímọ́) Ṣé ó máa ń wu àwa náà àtàwọn ọmọ wa láti máa wà láàárín ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run déédéé?Sáàmù 26:8, 12.

ẸYẸ ÀKỌ̀ MỌ ÀKÓKÒ RẸ̀

Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.” Kò sí àní-àní pé Jeremáyà ti kíyè sí bí àwọn ẹyẹ àkọ̀ ṣe máa ń fò gba Ilẹ̀ Ìlérí kọjá, tí wọ́n bá ń ṣí láti ibì kan sí ibòmíì. Ní ìgbà ìrúwé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300,000] ẹyẹ àkọ̀ aláwọ̀ funfun máa ń ṣí láti ilẹ̀ Áfíríkà lọ sí Àríwá Yúróòpù, wọ́n á sì gba Àfonífojì Jọ́dánì kọjá. Ara wọn ló máa ń sọ àkókò tó yẹ kí wọ́n ṣí lọ síbòmíì fún wọn. Bíi ti àwọn ẹyẹ míì tó máa ń ṣí kiri, àwọn ẹyẹ àkọ̀ máa ń “mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.”Jeremáyà 8:7, Bíbélì Mímọ́.

Ìwé Collins Atlas of Bird Migration sọ pé: “Ohun tó yani lẹ́ni nípa bí àwọn ẹyẹ yìí ṣe máa ń ṣí kiri ni pé, ọgbọ́n àdámọ́ni ló ń darí wọn.” Ọgbọ́n tí Jèhófà Ọlọ́run dá mọ́ àwọn ẹyẹ ló ń jẹ́ kí wọ́n mọ àkókò láti ṣípò pa dà. Àmọ́ ní ti àwa èèyàn, ńṣe ló fún wa ní agbára ká lè máa fi òye mọ ìgbà àti àkókò. (Lúùkù 12:54-56) Kì í ṣe ọgbọ́n àdámọ́ni bíi ti ẹyẹ àkọ̀ ló ń darí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ Ọlọ́run ló ń jẹ́ kí àwa èèyàn lè máa fi  òye mọ bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí ti ṣe pàtàkì tó. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Jeremáyà kò fiyè sí irú àmì bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tó fà ìṣòro yìí, ó ní: “Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?”Jeremáyà 8:9.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1-5) Ṣé wàá fara wé ẹyẹ àkọ̀, kó o máa kíyè sí ‘àkókò’?

ẸYẸ IDÌ MÁA Ń RÍ IBI TÓ JÌNNÀ GAN-AN

Idì

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì dárúkọ ẹyẹ idì. Àwọn tó ń gbé Ilẹ̀ Ìlérí sì máa ń rí ẹyẹ yìí dáadáa. Láti orí òkè tó ga fíofío tí ẹyẹ yìí tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí “ni ó ti ń wá oúnjẹ; ojú rẹ̀ ń wo ọ̀nà jíjìn.” (Jóòbù 39:27-29) Ojú ẹyẹ idì lágbára débi pé ó lè rí eku tó wà ní nǹkan bí kìlómítà kan (1 km) síbi tó wà, ìyẹn nǹkan bí ogún [20] opó iná.

Bí ẹyẹ idì ṣe máa “ń wo ọ̀nà jíjìn,” bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe lágbára láti rí ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àbájọ tí Bíbélì fi sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé ó jẹ́ “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.” (Aísáyà 46:10) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà, ọgbọ́n àti agbára tó ní láti mọ ọjọ́ ọ̀la á ṣe wá láǹfààní.Aísáyà 48:17, 18.

Bíbélì tún fi àwọn tó gbọ́kàn lé Ọlọ́run wé ẹyẹ idì, ó ní: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì.” (Aísáyà 40:31) Bí ooru bá ṣe ń mú sí ló máa ń jẹ́ kí ẹyẹ idì lè fò lọ sókè dáadáa. Tí ẹyẹ yìí bá ti dé ibi tí atẹ́gùn ti pọ̀, ó máa na ìyẹ́ apá rẹ̀, á sì máa fò yípo, bó ṣe ń fò yìí láá máa lọ sókè sí i. Ẹyẹ idì kò gbára lé agbára rẹ̀ láti fò lọ sókè, kó sì fò lọ sí ọ̀nà tó jìn. Bákan náà, ojú Jèhófà làwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e máa ń wò pé kó fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tó ṣèlérí.2 Kọ́ríńtì 4:7, 8.

‘Ọ̀NÀ TÍ ADÌYẸ FI Ń KÓ ÀWỌN ÒRÒMỌDÌYẸ RẸ̀ JỌ PỌ̀’

Adìyẹ àtàwọn òròmọdìyẹ

Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó dúró láti wo ìlú Jerúsálẹ́mù. Ó wá kédàárò pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta, iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ.”Mátíù 23:37.

Ọ̀kan lára ọgbọ́n tí Ọlọ́run dá mọ́ àwọn ẹyẹ ni bí wọ́n ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Àwọn ẹyẹ tó ń gbé orí ilẹ̀, irú bí adìyẹ, máa ń wà lójúfò gan-an nítorí ewu. Tí adìyẹ bá rí àṣà tó ń rà bàbà lókè, á pariwo káwọn ọmọ rẹ̀ lè mọ̀ pé ewu ń bọ̀. Àwọn ọmọ náà á sì sáré bọ́ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀. Tí àwọn òròmọdìyẹ bá sá sábẹ́ ìyẹ́ ìyá wọn, kò ní jẹ́ kí oòrùn tàbí òjò pa wọ́n. Bákan náà, Jésù fẹ́ pèsè ààbò nípa tẹ̀mí fún àwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù. Lóde òní, Jésù ń pè wá pé ká wá sọ́dọ̀ òun ká lè rí ìtura àti ààbò, ká sì bọ́ lọ́wọ́ àwọn àjàgà àti àníyàn ìgbésí ayé.Mátíù 11:28, 29.

Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ lára àwọn ẹyẹ. Bó o ṣe ń kíyè sí ìṣesí wọn, ronú nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ fi wọ́n wé. Ǹjẹ́ kí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ mú kó o mọyì àwọn ibi tá a ti ń jọ́sìn Jèhófà. Kí o ní ìrètí nínú Ọlọ́run, èyí ló máa mú kó o ròkè lálá bíi ẹyẹ idì. Kó o sì wá sọ́dọ̀ Jésù kó o lè rí ààbò nípa tẹ̀mí, bí ìgbà tí adìyẹ bá dáàbò bo àwọn òròmọdìyẹ. Kí ẹyẹ àkọ̀ sì máa rán ẹ létí láti wà lójúfò, bí onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé.