Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Èmi àti Tabitha ìyàwó mi wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ní Tèmi O, Kò Sí Ọlọ́run

Ní Tèmi O, Kò Sí Ọlọ́run
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: GERMAN DEMOCRATIC REPUBLIC

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MI Ò GBÀ PÉ ỌLỌ́RUN WÀ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

Abúlé kan ní ìlú Saxony ni wọ́n bí mi sí, ní orílẹ̀-èdè tá a mọ̀ sí German Democratic Republic (GDR) tẹ́lẹ̀. Ilé wa tura gan-an, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa, àwọn òbí mi kọ́ mi níwà ọmọlúwàbí. Ìjọba orí-ò-jorí ni wọ́n ń ṣe ní GDR, torí náà ọ̀pọ̀ ni kò ka ẹ̀sìn sí. Pàápàá fún èmi, mi ò gbà pé Ọlọ́run wà. Ní gbogbo ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi títí mo fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo gbà pé kò sí Ọlọ́run, mo sì tún gbà gbọ́ nínú ìjọba orí-ò-jorí. Èrò yìí sì ti nípa lórí mi gan-an.

Kí nìdí tí mo fi nífẹ̀ẹ́ sí ìjọba orí-ò-jorí? Ìdí ni pé mo gbà pé ohun tó tọ́ ni pé kí ẹnì kan má ju ẹnì kan lọ. Yàtọ̀ síyẹn, mo gbà pé ó yẹ kí wọ́n máa pín ohun ìní lọ́gbọọgba, torí ìyẹn ni ò ní jẹ́ káwọn kan jẹ́ ọlọ́rọ̀ káwọn míì sì jẹ́ tálákà. Ìyẹn ló jẹ́ kí n tara bọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣagbátẹrù ìjọba orí-ò-jorí. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, mo lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àtúnṣe ìlú, mo ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń fi pépà tí kò wúlò mọ́ ṣe nǹkan míì. Inú àwọn ará ìlú Aue dùn gan-an fún ìsapá mi, wọ́n sì fún mi ní àmì ẹ̀yẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré, mo láǹfààní láti mọ àwọn olóṣèlú pàtàkì-pàtàkì lórílẹ̀-èdè GDR. Gbogbo èrò mi ni pé ohun tó dáa ni mò ń fayé mi ṣe àti pé ọjọ́ iwájú mi máa dáa.

Àmọ́, ṣàdédé ni nǹkan yí pa dà fún mi. Lọ́dún 1989, ògiri tí wọ́n ń pè ní Berlin Wall wó lulẹ̀, ìgbà yẹn náà ni àwọn ìjọba orí-ò-jorí nílẹ̀ Yúróòpù forí ṣánpọ́n. Oríṣiríṣi nǹkan ló wá ń ṣẹlẹ̀. Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ìwà ìrẹ́jẹ wọ́pọ̀ ní orílẹ̀-èdè GDR. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni wọ́n ń fìyà jẹ àwọn tí kò fara mọ́ ìjọba orí-ò-jorí. Kí ló fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? Ṣebí ohun tá a gbà gbọ́ ni pé ẹ̀tọ́ kan náà ni gbogbo wa ní. Ṣé a wá ń tanra wa látọjọ́ yìí ni? Àwọn nǹkan yìí wá ń mú kí n máa ṣàníyàn.

Bí mo ṣe yí àfojúsùn mi pa dà nìyẹn, mo wá gbájú mọ́ orin àti iṣẹ́ ọnà. Mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ orin, mo sì ronú pé tó bá ṣeé ṣe màá lọ sí yunifásítì, màá sì di olórin. Láfikún sí i, mo pa gbogbo ìwà ọmọlúwàbí táwọn òbí mi ti kọ́ mi tì. Ohun tó wá ṣe pàtàkì sí mi ni pé kí n jayé orí mi, mo sì ń kó obìnrin. Àmọ́ orin kíkọ àti iṣẹ́ ọnà kò mú àníyàn kúrò lọ́kàn mi. Kódà, ìbẹ̀rù máa ń hàn nínú àwọn àwòrán tí mò ń yà, torí pé mi ò  mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, mi ò sì mọ ìdí tí mo fi wà láyé.

Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo wá rí ìdáhùn sí àwọn ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan nígbà tí mo wà níléèwé, èmi àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan jọ jókòó, a sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni Mandy, * Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Lọ́jọ́ yẹn, ó fún mi láwọn ìmọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu. Ó sọ pé, “Andreas, tó o bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn nípa ìgbésí ayé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.”

Mi ò kọ́kọ́ fara mọ́ ohun tó sọ, àmọ́ mo ronú pé kí n gbìyànjú ẹ̀ wò. Mandy ní kí n lọ ka Dáníẹ́lì orí 2, ohun tí mo sì kà níbẹ̀ yà mí lẹ́nu. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ nípa agbára ayé, ìyẹn àwọn ìjọba tó máa ṣàkóso ayé títí fi di àkókò wa. Mandy tún fàwọn ẹsẹ Bíbélì míì hàn mí tó jẹ mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú wa. Mo ti wá ń rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi báyìí! Àmọ́ ta ló sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ta ló sì lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jú iwájú lọ́nà tó ṣe rẹ́gí bí èyí? Ṣé ó wá lè jẹ́ pé Ọlọ́run wà lóòótọ́ ni?

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

Mandy mú mi mọ tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Horst àti Angelika. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, wọ́n sì lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni ẹ̀sìn tó ń lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, tí wọ́n sì tún ń fi kọ́ àwọn èèyàn. (Sáàmù 83:18; Mátíù 6:9) Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run fún àwa èèyàn láǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Sáàmù 37:9 sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” Ó dùn mọ́ mi pé gbogbo èèyàn tó bá gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Ọlọ́run mu bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀ ló máa ní àǹfààní yìí.

Àmọ́, ó ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé kí n sì máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Àwọn àṣeyọrí tí mo ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ orin ti sọ mí di agbéraga, torí náà mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Bákan náà, kò rọrùn fún mi láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà ìṣekúṣe tó ti mọ́ mi lára. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé Jèhófà máa ń ní sùúrù fáwọn tó ń sapá gan-an kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, ó máa ń fi àánú hàn sí wọn, ó sì máa ń lóye wọn!

Títí mo fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] mi ò gbà pé Ọlọ́run wà, mo sì ń ṣagbátẹrù ìjọba orí-ò-jorí; àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn Bíbélì ti wá ń yí ìgbésí ayé mi pa dà. Àwọn ohun tí mo kọ́ ti mú àníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la kúrò lọ́kàn mi, ó sì ti jẹ́ kí n rí ohun gidi fi ayé mi ṣe. Lọ́dún 1993, mo ṣe ìrìbọmi, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó sì di ọdún 2000, mo gbé Tabitha, tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí níyàwó. A máa ń lo àkókò tó pọ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń bá pàdé lọ̀rọ̀ wọn dà bíi tèmi, wọ́n fẹ́ràn ìjọba orí-ò-jorí, wọn ò sì gbà pé Ọlọ́run wà. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá fi bí wọ́n á ṣe mọ Jèhófà hàn wọ́n.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

Inú bí àwọn òbí mi nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, láti ìgbà yẹn ni wọ́n ti rí i pé ó ti mú kí n máa gbé ìgbésí ayé tó dára. Ayọ̀ mi kún báyìí pé àwọn náà ti ń ka Bíbélì, wọ́n sì ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Èmi àti Tabitha ń gbádùn ìgbéyàwó wa torí pé à ń sapá láti fi àwọn ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn tọkọtaya ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, à ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò nípa bí tọkọtaya ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ síra wọn, èyí sì ti mú kí ìgbéyàwó wa dúró sán-ún.​—Hébérù 13:4.

Ẹ̀rù kì í bà mí mọ́ nípa ìgbésí ayé, mi ò sì ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la mọ́. Mo gbà pé mo jẹ́ ara ìdílé onígbàgbọ́ tó wà kárí ayé, a sì ń gbádùn àlááfíà àti ìṣọ̀kan. Nínú ìdílé yìí, ẹnì kan ò ju ẹnì kan lọ. Ohun tí mo fẹ́ gan-an nìyẹn, ohun tí mo sì ti fi ayé mi lépa nìyẹn.

^ ìpínrọ̀ 12 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.