Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 5 2017

Gbogbo ohun ìjà ogun ni kò ní sí mọ́

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé àlááfíà ṣì máa wà láyé?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

Nígbà tí Jésù Kristi bá ń ṣàkóso, ‘ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà yóò wà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́,’ àní títí láé.​—Sáàmù 72:7.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Àwọn èèyàn burúkú kò ní sí mọ́ láyé, àwọn èèyàn rere máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:​10, 11.

  • Ọlọ́run máa mú gbogbo ogun kúrò pátápátá.​—Sáàmù 46:​8, 9.

Ṣé ó ṣeé ṣe ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ báyìí?

Èrò àwọn kan ni pé . . . kò ṣeé ṣe káwa èèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ torí pé ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ ló kún inú ayé. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Lónìí, àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”​—Fílípì 4:​6, 7.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ, òun á sì sọ “ohun gbogbo di tuntun.”​—Ìṣípayá 21:​4, 5.

  • A máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tá a bá sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.​—Mátíù 5:3.