Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ No. 5 2017 | Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì?

Kí Lèrò Rẹ?

Ṣé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́? Bíbélì sọ pé:

“Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀.”​Sáàmù 103:20.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn áńgẹ́lì àti bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?

Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí máa ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Òótọ́ Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì

Kò sí ibòmí ì tó dáa tá a ti lè rí ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì ju inú Bíbélì lọ.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

Ṣé o máa ń ronú pé o ní áńgẹ́lì kan tàbí àwọn áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ẹ́?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Burúkú Wà?

Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdáhùn tó ṣe kedere.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ti mú kí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí dá sí ọ̀rọ̀ aráyé.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé èébú ni bí Jésù ṣe fi àwọn tí kì í ṣe Júù wé “ajá kéékèèké”?

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ní Tèmi O, Kò Sí Ọlọ́run

Báwo lẹnì kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà tó sì fara mọ́ ìjọba orí-ò-jorí nígbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ṣe wá dẹni tó fẹ́ràn Bíbélì?

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”

Kí nìdí tí orúkọ tuntun yìí fi tọ́ sí Sárà?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ó jọ pé kò lè sí àlááfíà láyé àti pé ẹnì kọ̀ọ̀kan kò lè ní àlááfíà ọkàn tí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ bá ṣì wà láyé. Ṣé ojútùú wà sí ìṣòro yìí?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Ṣé Ó Pọn Dandan Kéèyàn Máa Dara Pọ̀ Mọ́ Ẹ̀sìn Kan Pàtó?

Ṣé ó ṣeé ṣe kí èèyàn máa sin Ọlọ́run láì lọ sí ilé ìjọsìn?