KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?
Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà
Onírúurú ìṣòro làwa èèyàn máa ń dojú kọ. A ò lè sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ìṣòro náà báyìí, àmọ́ a máa sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà. Kó o sì kíyè sí bí àwọn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro ṣe rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
TÍ IṢẸ́ BÁ BỌ́ LỌ́WỌ́ RẸ
“Mo gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú, a sì dín ìnáwó wa kù.”
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Seth * sọ pé: “Ìgbà kan náà ni iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ èmi àti ìyàwó mi. Owó táwọn mọ̀lẹ́bí ń fún wa àti iṣẹ́ lébìrà la fi gbọ́ bùkátà ara wa fún ọdún méjì gbáko. Èyí kó ẹ̀dùn ọkàn bá Priscilla, ìyàwó mi, èmi náà ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú ara mi.
“Ọgbọ́n wo la wá dá sí i? Gbogbo ìgbà ni Priscilla máa ń ronú lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 6:34. Jésù sọ pé ká má ṣe ṣàníyàn nípa ọ̀la, torí pé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Àdúrà tí ìyàwó mi máa ń gbà látọkànwá sì máa ń fún un lókun láti máa fara dà á. Sáàmù 55:22 ló ran èmi lọ́wọ́. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù yẹn, ńṣe ni mo ju gbogbo ẹrù ìnira mi sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ní báyìí mo ti ríṣẹ́, síbẹ̀ à ṣì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó wà ní Mátíù 6:20-22, a ò sì ṣe kọjá agbára wa. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a ti sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, èmi àtìyàwó mi sì tún ti mọ́wọ́ ara wa dáadáa.”
Jonathan sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí okòwò tí ìdílé wa ń ṣe dẹnu kọlẹ̀. Torí ìṣòro ọrọ̀ ajé tí kò lọ dáadáa, gbogbo ohun tá a ti fi ogún [20] ọdún kó jọ ló lọ láú. Ó wá di pé kémi àti ìyàwó mi máa bára wa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ owó. Ó le débi pé a ò lè lo káàdì tá a fi ń rajà láwìn torí pé ẹ̀rù ń bà wá pé wọ́n lè má tajà fún wa.
“Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́. Mo gbà láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú, a sì dín ìnáwó wa kù. Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn ará wa tún ràn wá lọ́wọ́. Wọn ò jẹ́ kójú tì wá, wọ́n sì máa ń tì wá lẹ́yìn nígbà tí nǹkan bá le koko.”
BÍ ÌGBÉYÀWÓ BÁ TÚ KÁ
Raquel sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi já mi jù sílẹ̀ ní ọ̀sán kan òru kan, ó dùn mí wọra, inú sì bí mi gan-an. Ìbànújẹ́ tó kọjá àfẹnusọ dorí mi kodò. Àmọ́ mo sún mọ́ Ọlọ́run. Ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.
“Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lára mi, òun ló jẹ́ kí n lè gbé ìbínú àti ìkórìíra kúrò lọ́kàn. Mo tún máa ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó wà nínú Róòmù 12:21, tó sọ pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.’
“Ìgbà míì wà tó máa gba pé ká gbọ́kàn kúrò lára nǹkan wa tó ‘ti sọnù.’ . . . Mo ti wá ní àwọn nǹkan tuntun tí mò ń lépa báyìí.”
“Ọ̀rẹ́ mi kan tún jẹ́ kí n rí ìdí tó fi yẹ kí n máa bá ìgbésí ayé mi lọ. Ó fi ohun tó wà nínú Oníwàásù 3:6 hàn mí, ó sì sọ fún mi pé ìgbà míì wà tó máa gba pé ká gbọ́kàn kúrò lára nǹkan wa tó ‘ti sọnù.’ Ìmọ̀ràn yẹn le lójú mi, àmọ́ ohun tí mo nílò gan-an nìyẹn. Mo ti wá ní àwọn nǹkan tuntun tí mò ń lépa báyìí.”
Elizabeth sọ pé: “Èèyàn máa ń nílò ìtìlẹ́yìn lásìkò tí ìgbéyàwó rẹ̀ bá tú ká. Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fún mi ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́. Ó máa ń bá mi sunkún, ó máa ń tù mí nínú, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Ó dá mi lójú pé ńṣe ni Jèhófà lò ó láti wo ọgbẹ́ ọkàn mi sàn.”
TÍ ÀÌSÀN TÀBÍ ỌJỌ́ OGBÓ BÁ DÉ
“Tí mo bá ti gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run fún mi lókun.”
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Luis, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ní àrùn ọkàn tó lágbára gan-an, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Ní báyìí, ó ní láti lo ẹ̀rọ téèyàn fi ń mí fún wákàtí mẹ́rìndínlógún [16] lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Tí mo bá ti gbàdúrà, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti fún mi lókun. Àdúrà máa ń jẹ́ kí n nígboyà láti má ṣe sọ̀rètí nù, torí mò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, mo sì mọ̀ pé ó bìkítà fún mi.”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Petra tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń wù mí láti ṣe, àmọ́ agbára mi ò gbé e. Kò rọrùn rárá bí mi ò ṣe lókun mọ́. Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe, oògùn ni mo sì fi ń gbéra. Mo sábà máa ń ronú nípa bí Jésù ṣe bẹ Bàbá rẹ̀ pé kó jẹ́ kí àwọn ìṣòro kan ré òun kọjá, tó bá ṣeé ṣe. Àmọ́, Jèhófà fún Jésù lókun, ó sì ń fún èmi náà lókun. Ojoojúmọ́ ni mò ń gbàdúrà, ara sì máa ń tù mí lẹ́yìn tí mo bá ti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀.”—Mátíù 26:39.
Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Julian náà nìyẹn. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí tí àìsàn sclerosis tó máa ń mú kí iṣan ara le gbagidi, ti ń yọ ọ́ lẹ́nu. Ó sọ pé: “Èmi tí mo máa ń jókòó sórí àga ọlọ́lá tẹ́lẹ̀ wá dẹni tó ń jókòó sórí àga arọ. Àmọ́ ayé yẹ mí torí pé mò ń ṣe ohun tó ń ṣe àwọn míì láǹfààní. Fífún àwọn èèyàn ní nǹkan lè dín ìyà tó ń jẹ wọ́n kù. Jèhófà sì máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á fún wa lókun nígbà ìṣòro. Èmi náà lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.’”—Fílípì 4:13.
TÍ ÈÈYÀN RẸ BÁ KÚ
Antonio sọ pé: “Ńṣe ló dà bí àlá lójú mi nígbà tí bàbá mi kú nínú ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Kó dáa rárá, torí pé jẹ́jẹ́ ni wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn lọ, tí mọ́tò fi yà lọ gbá wọn. Àmọ́ kò sí ohun tí mo lè ṣe sí i. Ọjọ́ márùn-ún ni wọn ò fi mọ nǹkan kan, kí wọ́n tó kú. Mi ò kì í sunkún tí mo bá wà lọ́dọ̀ màmá mi, àmọ́ tí mo bá dá wà, ńṣe ni mo máa ń wa ẹkún mu. Ohun tí mo ṣáà ń bi ara mi ni pé, ‘Kí ló dé tírú èyí fi ṣẹlẹ̀.’
“Ní gbogbo àkókò yẹn, mi ò yéé gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn mi, kó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Nígbà tó yá, ara bẹ̀rẹ̀ sí í tù mí. Mo rántí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀’ lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni lára wa. Ó dá mi lójú pé màá rí bàbá mi pa dà nígbà àjíǹde, torí pé Ọlọ́run kò lè parọ́.”
“Òótọ́ ni pé ìjàǹbá ọkọ̀ òfúrufú náà gba ẹ̀mí ọmọ wa, síbẹ̀ a ṣì ń rántí àwọn àkókò alárinrin tá a ti jọ lò pa pọ̀.”
Èrò yẹn náà ni Robert tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ní. Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ti wá mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ní àlàáfíà Ọlọ́run tí Fílípì 4:
“Nígbà tí àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún wa pé àwọn rí wa tí à ń fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, ohun tá a sọ fún wọn ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà tí wọ́n gbà fún wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Ó dá mi lójú pé Jèhófà tì wá lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n sọ fún wa.”
Bí àwọn ohun tá a gbé yẹ̀wò yìí ṣe fi hàn, Ọlọ́run lè pèsè ìtùnú fún àwọn èèyàn tó ń dojú kọ onírúurú ìṣòro àti ìpèníjà. Ìwọ ńkọ́? Ìṣòro yòówù kó o dojú kọ nígbèésí ayé, ohun tó lè tù ẹ́ nínú nírú àkókò tó nira bẹ́ẹ̀ wà. * O ò ṣe kúkú yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́? Òun ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”
^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 23 Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kó o sì rí ìtùnú, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó bá sún mọ́ ẹ jù lọ.