Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 5 2016

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

ÀWỌN KAN GBÀ GBỌ́ PÉ ó túmọ̀ sí kí Ọlọ́run máa jọba lọ́kàn èèyàn, àwọn míì sì rò pé ìsapá àwa èèyàn láti mú kí àlááfíà àti ìṣọ̀kan wà láyé ni Ìjọba Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba [èèyàn] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba gidi ni Ìjọba Ọlọ́run.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso láti ọ̀run.Mátíù 10:7; Lúùkù 10:9.

  • Ọlọ́run máa lo Ìjọba yìí láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé.Mátíù 6:10.

Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé?

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kò sí ẹni tó mọ̀

  • Láìpẹ́

  • Kò lè dé láéláé

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Tí a bá ti wàásù ìhìn rere náà dáadáa kárí ayé, lẹ́yìn náà ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú ayé burúkú yìí lọ sópin.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Kò sí ẹnì kankan láyé yìí tó mọ àsìkò pàtó tí Ìjọba Ọlọ́run máa dé.Mátíù 24:36.

  • Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé láìpẹ́.Mátíù 24:3, 7, 12.