Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ No. 5 2016 | Ibo Lo Ti Lè Rí Ìtùnú?

Gbogbo wa la nílò ìtùnú, pàápàá nígbà ìṣòro. Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń pèsè ìtùnú fún àwa èèyàn nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro.

COVER SUBJECT

Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú

Ibo lo ti lè rí ìtùnú tó o bá ń ṣọ̀fọ̀ tàbí tí àìsàn burúkú kan bá gbé ẹ ṣánlẹ̀, tàbí tí inú rẹ kò dùn sí bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ìgbéyàwó rẹ, tàbí tí kò sí iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ?

COVER SUBJECT

Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Tù Wá Nínú

Ọ̀nà mẹ́rin tẹ́ni tọ́ ń banújẹ́ lè gbà rí ìrànlọ́wọ́.

COVER SUBJECT

Bá A Ṣe Lè Rí Ìtùnú Lásìkò Wàhálà

Bí àwọn kan ṣe rí ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà tí wọ́n nílò rẹ̀ jùlọ.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

“Ti Jèhófà Ni Ìjà Ogun Náà”

Kí ló ran Dáfídì lọ́wọ́ láti pa Gòláyátì? Kí la rí kọ́ látinú ìtàn Dáfídì?

Ìjà Dáfídì Àti Gòláyátì—Ṣé Ó Ṣẹlẹ̀ Lóòótọ́?

Àwọn kan ò gbà pé àkọsílẹ̀ yìí jóòótọ́. Ṣé ohun tí wọ́n sọ bọ́gbọ́-n mu?

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Inú Mi Kì Í Dùn, Mo Sì Máa Ń Hùwà Ìpáǹle

Kí ló mú kí ọmọ ìta ìlú Mẹ́síkò kan fẹ́ láti yí ìwà rẹ̀ pa dà?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ní nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Àmọ́, kí ni Ìwé Mímọ́ kọ́ wa nípa rẹ̀? Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lè yà ẹ́ lẹ́nu.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Ṣé Ọlọ́run Á Gbọ́ Àdúrà Mi?

Bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà tó o bá gbà tàbí kò ní gbọ́ kù sí ọwọ́ rẹ.