Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Elias Hutter Ṣiṣẹ́ Ribiribi Sínú Àwọn Bíbélì Èdè Hébérù Tó Ṣe

Elias Hutter Ṣiṣẹ́ Ribiribi Sínú Àwọn Bíbélì Èdè Hébérù Tó Ṣe

ǸJẸ́ o lè ka èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀? Kò dájú pé o lè kà á. Ó sì lè jẹ́ pé o kò tíì rí Bíbélì èdè Hébérù rí. Àmọ́, tó o bá mọ ìtàn ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Elias Hutter, tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún àti ẹ̀dà Bíbélì méjì tó ṣe lédè Hébérù, wàá túbọ̀ mọyì Ìwé Mímọ́ tó o ní lọ́wọ́.

Ọdún 1553 ni wọ́n bí Elias Hutter ní ìlú Görlitz, ìlú kékeré kan nítòsí ẹnubodè Jámánì, Poland àti Czech Republic báyìí. Hutter kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè àwọn ará Ìlà Oòrùn ní Yunifásítì Lutheran tó wà ní Jena. Nígbà tó kù díẹ̀ kó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24], wọ́n fi joyè ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdè Hébérù ní ìlú Leipzig. Torí pé Hutter mọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́, ó sì fẹ́ kó dáa sí i, ó dá ilé ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ ní ìlú Nuremberg. Ibẹ̀ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ kọ́ èdè Hébérù, Gíríìkì, Látìn àti Jámánì ti lè kọ́ ọ láàárín ọdún mẹ́rin. Kò sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí yunifásítì tó lè ṣe ohun tó ṣe yìí nígbà yẹn.

“Ẹ̀DÀ BÍBÉLÌ YÌÍ GBAYÌ GAN-AN”

Àkọlé Bíbélì èdè Hébérù tí Hutter ṣe lọ́dún 1587

Ní ọdún 1587, Hutter mú ẹ̀dà Bíbélì kan jáde ní èdè Hébérù, irú èyí tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Láéláé. Ó pe orúkọ ẹ̀dà náà ni Derekh ha-Kodesh, inú ìwé Aísáyà 35:8 ló ti mú u, ó sì túmọ̀ sí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Torí pé àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi tẹ ìwé náà rẹwà, èyí mú kí àwọn kan sọ̀rọ̀ tó dáa nípa rẹ̀ pé “ẹ̀dà Bíbélì yìí gbayì gan-an.” Àmọ́, ohun tó mú kí Bíbélì yìí wúlò jù ni pé ó rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti fi kọ́ èdè Hébérù.

Ká lè mọ ìdí tí Bíbélì èdè Hébérù tí Hutter ṣe fi wúlò gan-an, ó máa dáa ká wo méjì lára ìṣòro tí ẹni tó ń kọ́ èdè Hébérù máa ń ní tó bá fẹ́ ka Bíbélì ní èdè náà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, álífábẹ́ẹ̀tì èdè yìí yàtọ̀, kì í ṣe èyí téèyàn lè tètè mọ̀. Ohun kejì ni pé àwọn ọ̀rọ̀ àsomọ́ tó ń ṣáájú àti èyí tó ń kẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò nínú èdè yìí máa ń jẹ́ kó ṣòro láti mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ gangan. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù yìí נפשׁ (tí wọ́n tú sí ne’phesh), túmọ̀ sí “ọkàn.” Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì 18:4, ọ̀rọ̀ àsomọ́ yìí ה (ha), tó túmọ̀ sí “náà,” ló ṣáájú ọ̀rọ̀ náà ọkàn nínú ẹsẹ yìí, èyí jẹ́ kó di הנפשׁ (han·ne’phesh), tó túmọ̀ sí “ọkàn náà.” Tí ẹni tí kò mọ èdè Hébérù bá wo ọ̀rọ̀ yìí הנפשׁ (han·ne’phesh), ọ̀rọ̀ míì ló máa jọ lójú ẹ̀ torí ó ti yàtọ̀ pátápátá sí נפשׁ (ne’phesh).

Hutter lo ọgbọ́n tí wọ́n fi ń tẹ ìwé nígbà yẹn láti tẹ àwọn lẹ́tà èdè Hébérù inú ìwé náà lọ́nà tó máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́wọ́, àwọn lẹ́tà kan fún pọ̀, àwọn míì  ní àlàfo láàárín. Ó fi lẹ́tà tó fún pọ̀ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan. Àwọn lẹ́tà tó ní àlàfo láàárín ló fi tẹ àwọn ọ̀rọ̀ àsomọ́ tó máa ń ṣáájú àtàwọn tó máa ń kẹ́yìn ọ̀rọ̀. Ọgbọ́n tó dá yìí mú kó rọrùn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti dá àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù gangan mọ̀ yàtọ̀ sí àwọn àsomọ́ tí wọ́n fi kún un, èyí sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ èdè náà. Wọ́n lo irú ọgbọ́n yìí nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures—With References. * Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú ní tààràtà ló dúdú gan-an, àwọn àsomọ́ ọ̀rọ̀ sì wà bí àwọn ọ̀rọ̀ tó kù. Àwọn ibi tá a ṣe àmì sí nínú àwòrán méjì yìí jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 18:4 nínú Bíbélì èdè Hébérù tí Hutter ṣe àti bí àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà fún ẹsẹ Bíbélì yìí kan náà ṣe rí nínú Reference Bible.

ÌTÚMỌ̀ “MÁJẸ̀MÚ TUNTUN” SÍ ÈDÈ HÉBÉRÙ

Hutter tún ṣe apá kejì Bíbélì táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun jáde ní èdè méjìlá. Ó tẹ ẹ̀dà yìí jáde ní Nuremberg lọ́dún 1599, wọ́n sì máa ń pè é ní Nuremberg Polyglot. Hutter fẹ́ túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni ní èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù. Àmọ́ ó sọ pé asán ni gbogbo ìsapá òun ì bá já sí ká ní òun “ní kí wọ́n bá òun ṣe iṣẹ́” ìtúmọ́ náà sí èdè Hébérù. * Ló bá pinnu pé òun á túmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun láti èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù fúnra òun. Hutter pa àwọn nǹkan míì tó ń ṣe tì kó lè ráyè ṣe ìtúmọ̀ yìí, ọdún kan péré ló sì fi ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ tó dáwọ́ lé yìí!

Báwo ni ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù tí Hutter dáwọ́ lé ṣe dáa tó? Ọ̀mọ̀wé kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún tó ń jẹ́ Franz Delitzsch, tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Hébérù sọ pé: “Iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì sí èdè Hébérù tí Hutter ṣe fi hàn pé òye tó ní nípa èdè ṣọ̀wọ́n láàárín àwọn Kristẹni, ìtúmọ̀ rẹ̀ ṣeé gbára lé gan-an, ẹ̀rí sì fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ tó bá a mú wẹ́kú ló lò nínú ìtúmọ̀ tó ṣe.”

IṢẸ́ RIBIRIBI TÓ ṢE Ò PA RẸ́

Hutter ò sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nídìí iṣẹ́ ìtúmọ̀ tó ṣe, ẹ̀rí sì fi hàn pé ẹ̀dà Bíbélì tó ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ tà. Síbẹ̀ náà, iṣẹ́ ribiribi tó ṣe ò pa rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1661, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ William Robertson ṣe àtúnṣe sí Májẹ̀mú Tuntun ní èdè Hébérù tí Hutter ṣe, ó sì tún un tẹ̀. Ohun kan náà ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Richard Caddick ṣe ní ọdún 1798. Nínú ìtúmọ̀ tí Hutter ṣe látinú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ó dìídì tú àwọn orúkọ òyè náà Kyʹri·os (Olúwa) àti The·osʹ (Ọlọ́run) sí “Jèhófà” (יהוה, JHVH) ní àwọn ibi tí wọ́n bá ti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Ìwé Mímọ́ ní èdè Hébérù tàbí láwọn ibi tó bá ti rí i pé Jèhófà ni wọ́n ń tọ́ka sí. Ohun tó ṣe yìí dára gan-an torí pé wọn ò lo orúkọ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun. Ìtúmọ́ tí Hutter ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé ó bá a mú kí á dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.

Tó o bá tún ti ń ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tó o sì rí orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà níbẹ̀ tàbí tó ò ń ka àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé nínú Bíbélì Reference Bible, kó o máa rántí iṣẹ́ ribiribi tí Elias Hutter ṣe sínú àwọn Bíbélì èdè Hébérù tó ṣe.

^ ìpínrọ̀ 7 Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kejì nípa Ìsíkíẹ́lì 18:4 àti Appendix 3B nínú Bíbélì Reference Bible.

^ ìpínrọ̀ 9 Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọ̀mọ̀wé kan ti fìgbà kan ṣe ìtúmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun ní èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù. Ọ̀kan lára wọn ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Simon Atoumanos, tó wá láti Byzantine, ní nǹkan bí ọdún 1360. Ẹlòmíì tó ṣe ìtúmọ̀ yìí ni Oswald Schreckenfuchs, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Jámánì ní nǹkan bí ọdún 1565. Wọn ò tẹ àwọn ìtúmọ̀ yìí jáde, wọ́n sì ti sọnù báyìí.