ÌBÀNÚJẸ́ dorí Doreen kodò nígbà tó gbọ́ pé Wesley ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] ti ní àìsàn burúkú kan, ìyẹn kókó inú ọpọlọ. * Àwọn dókítà sọ pé oṣù díẹ̀ ló máa lò kó tó kú. Doreen sọ pé: “Àfi bí àlá lọ̀rọ̀ náà rí lójú mi. Ńṣe ni gbogbo nǹkan tojú sú mi. Ó wá ń ṣe mi bíi pé kí ló dé tó jẹ́ èmi nirú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀ sí. Mi ò rò ó rí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí wa.”

Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Doreen náà ló ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn. Kò sẹ́ni tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ò lè ṣe nígbàkigbà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń múra tán láti tọ́jú èèyàn wọn tí irú àìsàn yìí ṣe. Àmọ́, kì í ṣe iṣẹ́ kékeré láti tọ́jú aláìsàn. Kí làwọn mọ̀lẹ́bí lè ṣe láti tu èèyàn wọn ti àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ń ṣe nínú, kí wọ́n sì tọ́jú rẹ̀? Báwo làwọn tó ń tọ́jú aláìsàn náà ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn wọn ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń bójú tó aláìsàn náà? Kí ni wọ́n lè máa retí bí ọjọ́ ikú ẹni náà ṣe ń sún mọ́lé? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ohun tó mú kí ìtọ́jú ẹni tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ṣe jẹ́ ìṣòro tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

ÌṢÒRO TÓ GBÒDE KAN

Ìmọ̀ ìṣègùn ti mú kí àìsàn tó ń gbẹ̀mí èèyàn dín kù. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ẹ̀mí àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ gùn, kódà láwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà. Ìdí ni pé àwọn àìsàn tó ń ranni àti jàǹbá máa ń tètè gba ẹ̀mí àwọn èèyàn. Ilé ìwòsàn kò tó nǹkan, inú ilé ni wọ́n sì ti ń tọ́jú ọ̀pọ̀ aláìsan, ibẹ̀ náà ni wọ́n á sì kú sí.

Àmọ́ lóde òní, ìmọ̀ ìṣègùn tó ti tẹ̀síwájú ti mú káwọn oníṣègùn lè gbógun ti àìsàn, kí ẹ̀mí àwọn èèyàn lè gùn sí i. Àìsàn tó jẹ́ pé kíá ló máa ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn láyé àtijọ́ ti wá lè lo ọ̀pọ̀ ọdún lára kó tó ṣekú pani. Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé àìsàn náà ti lọ lára ẹni náà. Àwọn tírú àìsàn yìí ń ṣe lè má ní okun nínú tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ lè ṣe ohunkóhun fúnra wọn. Torí náà,  ó máa ń ṣòro láti tọ́jú àwọn aláìsàn yìí, ó sì máa ń gba ìsapá.

Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ èèyàn kì í kú sílé mọ́ torí pé wọ́n máa ń gbé wọn lọ sílé ìwòsàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣàìsàn. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ ni kò mọ béèyàn ṣe ń kú, èèyàn ò tiẹ̀ kú lójú ẹlòmíì rí. Torí náà, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n láti dúró ti mọ̀lẹ́bí tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ń ṣe torí wọn ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Kí wá ni ṣíṣe báyìí?

MÚRA SÍLẸ̀

Bíi ti Doreen, ńṣe ni nǹkan máa ń tojú sú ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ pé àìsàn tó ń ṣe mọ̀lẹ́bí wọn ló máa ṣekú pa á. Torí náà, wọ́n lè máa ṣàníyàn, kẹ́rù máa bà wọ́n, ìbànújẹ́ sì lè sorí wọn kodò. Kí ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? Ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan gbàdúrà pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” (Sáàmù 90:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, máa gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà Ọlọ́run pé kó fi hàn ẹ́ bí wàá ṣe máa ‘ka àwọn ọjọ́ rẹ’ lọ́nà ọgbọ́n, kó o bàa lè lo àkókò tó ṣẹ́ kù pẹ̀lú aláìsàn náà lọ́nà tó dára gan-an.

Èyí gba pé kó o ni ìṣètò tó dára. Tí aláìsàn náà bá ṣì lè sọ̀rọ̀, tó sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa bọ́gbọ́n mu tó o bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ta ló fẹ́ kó máa bá òun ṣe ìpinnu nígbà tí kò bá mọ ohun tó ń lọ. Ẹ jọ sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n nípa bóyá ó fẹ́ kí wọ́n jí i tó bá dákú, kí wọ́n gbé e lọ sílé ìwòsàn tàbí kí fún un nírú ìtọ́jú kan. Tẹ́ ẹ bá jọ sọ̀rọ̀ yìí, ó máa dín àìgbọ́ra-ẹni-yé kù, kò sì ní jẹ́ kẹ́ ẹ máa dá ara yín lẹ́bi tó bá di dandan pé kẹ́ ẹ ṣe ìpinnu kan nípa aláìsàn náà nígbà tí kò bá mọ ohun tó ń lọ. Tẹ́ ẹ bá tètè sọ̀rọ̀ yìí, tí ẹ kò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó máa jẹ́ kí àwọn mọ̀lẹ́bí lè gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe bójú tó aláìsàn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.”—Òwe 15:22.

BẸ́ Ẹ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́

Ojúṣe ẹni tó ń tọ́jú aláìsàn ni pé kó máa tu aláìsàn nínú. Ẹ gbọ́dọ̀ fi dá ẹni tó ń kú lọ náà lójú pé ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé ẹ wà pẹ̀lú rẹ̀. Báwo lẹ ṣe lè ṣe é? Máa kàwé fún aláìsàn náà tàbí kó o kọrin fún un. Yan ìwé tàbí orin tó máa mára tu ẹni náà, tó sì máa múnú rẹ̀ dùn. Ara máa ń tu ọ̀pọ̀ èèyàn tí mọ̀lẹ́bí wọn kan bá di ọwọ́ wọn mú tàbí tó sọ̀rọ̀ tútù fún wọn.

Ó tún máa ń dáa tẹ́ ẹ bá ń sọ àwọn tó wá kí i. Ìròyìn kan fi hàn pé: “Nínú ẹ̀yà ara márùn-ún tá a fi ń mọ nǹkan lára, agbára ìgbọ́rọ̀ lèèyàn máa ń pàdánù kẹ́yìn. [Aláìsàn] náà ṣì lè máa gbọ́rọ̀ kódà tó bá  dà bíi pé ó ti sùn, torí náà má ṣe sọ ohun tí oò ní lè sọ lójú wọn nírú àsìkò bẹ́ẹ̀.”

Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ gbàdúrà pa pọ̀. Bíbélì ròyìn pé ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wà nínú ìdààmú tó lékenkà, débi pé kò dá wọn lójú pé ìṣòro náà kò ní gbẹ̀mí wọn. Ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n béèrè fún? Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin pẹ̀lú lè ṣèrànlọ́wọ́ ní àfikún nípa ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ yín fún wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:8-11) Àdúrà àtọkànwá tá a gbà nígbà tí nǹkan nira gan-an tàbí lásìkò àìsàn tó le koko máa ń ṣèrànwọ́.

MÁ TAN ARA RẸ

Ìdààmú máa ń bá wa tá a bá ń ronú pé ẹni tá a fẹ́ràn máa kú. Kò jọni lójú, torí pá Ọlọ́run kò dá ikú mọ́ wa. Ikú kì í ṣe apá kan ìgbésí ayé wa. (Róòmù 5:12) Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi pé ikú ni “ọ̀tá.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Torí náà, kì í ṣe ohun tó yani lẹ́nu tí a kò bá fẹ́ rò ó rárá pé èèyàn wa máa kú.

Síbẹ̀ náà, tá a bá ń fojú sọ́nà fún ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, ó máa jẹ́ kí ìbẹ̀rù wa dín kù, á sì jẹ́ ká gbájú mọ́ bí nǹkan ò ṣe ni lọ́jú pọ̀. A sọ díẹ̀ lára ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nínú àpótí tá a pè ní “ Ní Ọ̀sẹ̀ Mélòó Kan Kéèyàn Tó Kú.” Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo aláìsan lohun tá a sọ níbẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí, ó sì lè má ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra bá a ṣe tò ó síbẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ aláìsàn ni àwọn kan lára ohun tá a kọ síbẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí.

Tí aláìsàn náà bá ti kú, ó máa dáa ká pe àwọn ọ̀rẹ́ tó ti gbà tẹ́lẹ̀ pé àwọn máa ràn wá lọ́wọ́. A máa ní láti fi dá ẹni tó ń tọ́jú aláìsàn náà àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lójú pé ẹni tó kú náà kò jẹ̀rora mọ́ báyìí. Ẹlẹ́dàá wa mú un dá wa lójú pé “ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.

OLÙTỌ́JÚ TÓ GA JÙ LỌ

Ẹ kọ́ láti gba gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe fún un yín

Ó ṣe pàtàkì ká gbára lé Ọlọ́run nígbà tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí bá ń ṣe mọ̀lẹ́bí wa, a sì tún gbọ́dọ̀ gbára lé Ọlọ́run nígbà tá a bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni náà lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtùnú táwọn èèyàn sọ àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n pèsè. Doreen sọ pé: “Mo kọ́ láti má ṣe kọ ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́ ṣe fún mi. Ó jọ wá lójú gan-an báwọn èèyàn ṣe dúró tì wá lásìkò náà. Èmi àti ọkọ mi mọ pé Jèhófà ló ń sọ fún wa pé: ‘Mo wà pẹ̀lú yín, màá sì ràn yín lọ́wọ́.’ Mi ò lè gbà gbé ìrànlọ́wọ́ yìí títí láé.”

Kò sí àní-àní pé Jèhófà Ọlọ́run ni Olùtọ́jú tó ga jù lọ. Torí pé òun ló ṣẹ̀dá wa, ó mọ ìrora wa àtohun tó ń bà wá nínú jẹ́. Ó lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì fún wa ní ìṣírí ká lè fara dà á, ó sì ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí tó wá dùn mọ́ wa jù ni pé ó ti ṣèlérí pé òun máa mú ikú kúrò títí láé, á sì jí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Nígbà náà, gbogbo wa á lè tún ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?”—1 Kọ́ríńtì 15:55.

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.