Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ No. 4 2017 | Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú?

KÍ LÈRÒ RẸ?

Ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa kú? Bíbélì sọ pé: [Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.”Ìṣípayá 21:4.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyè àti ikú.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìbéèrè Tó Ń Rúni Lójú

Níwọ̀n bí èrò táwọn èèyàn ní nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú ò ti dọ́gba, ibo wá la ti lè rí ìsọfúnni tó jẹ́ òótọ́ nípa ẹ̀?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú

Ṣé apá kan lára wa ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú? Ṣé a ní ọkàn tí kò lè kú? Ibo làwọn òkú wà?

Tí Àìsàn Gbẹ̀mí-Gbẹ̀mí Bá Ń Ṣe Ẹni Tá A Nífẹ̀ẹ́

Báwo làwọn mọ̀lẹ́bí ṣe lè ṣaájò ẹni tí àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ń ṣe kí wọ́n sì tù wọ́n nínú? Báwo lẹni tó ń tọ́jú aláìsàn náà ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn tí wọ́n máa ní láàárín àkókò náà?

Elias Hutter Ṣiṣẹ́ Ribiribi Sínú Àwọn Bíbélì Èdè Hébérù Tó Ṣe

Elias Hutter, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé kan ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún kẹrìndínlógún tẹ Bíbélì èdè Hébérù méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ jáde.

Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀ Látinú Lẹ́tà Èdè Hébérù Tó Kéré Jù Lọ

Kí ni Jésù fẹ́ fà yọ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa lẹ́tà tó kéré jù lọ?

Ṣé Ayé Máa Di Párádísè Lóòótọ́?

Àtọdúnmọ́dún làwọn èèyàn ti ń sọ ìtàn nípa Párádísè tó sọnù. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe káyé tún pa dà di Párádísè?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ó jọ pé ara ìgbésí ayé àwa èèyàn ni ṣíṣe àníyàn jẹ́. Ǹjẹ́ a lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?

Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè yìí máa tù ọ́ nínú, yóò sì jẹ́ kó o ní ìrètí.