Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 3 2016

Bí wọ́n ṣe kọ orúkọ Ọlọ́run sínú Bíbélì àfọwọ́kọ layé àtijọ́

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ Ọlọ́run kò lórúkọ, àwọn míì sọ pé orúkọ rẹ̀ ni Ọlọ́run tàbí Olúwa, àwọn míì sì sọ pé orúkọ Ọlọ́run pọ̀ lọ súà. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní orúkọ oyè tó pọ̀, orúkọ kan ṣoṣo ló fún ara rẹ̀.—Ẹ́kísódù 3:15.

  • Ọlọ́run kì í ṣe àwámáàrídìí; ó fẹ́ ká mọ òun.—Ìṣe 17:27.

  • Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká kọ́kọ́ mọ orúkọ rẹ̀.—Jákọ́bù 4:8.

Ṣé ó burú tá a bá pe orúkọ Ọlọ́run?

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Mi ò mọ̀

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ lọ́nà tí kò ní láárí.” (Ẹ́kísódù 20:7) Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò dáa ni tí kò bá bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.—Jeremáyà 29:9.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Jésù mọ orúkọ Ọlọ́run, ó sì lò ó. —Jòhánù 17:25, 26.

  • Ọlọ́run fẹ́ ká máa fi orúkọ tí òun jẹ́ pe òun. —Sáàmù 105:1.

  • Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run fẹ́ mú kí àwọn èèyàn gbàgbé orúkọ Ọlọ́run.—Jeremáyà 23:27.