Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ

Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn

Bó O Ṣe Lè Fara Da Ọgbẹ́ Ọkàn

Ọ̀pọ̀ ìsọfúnni làwọn èèyàn ti tẹ̀ jáde lórí kókó yìí. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo rẹ̀ ló wúlò. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan á sọ pé o kò gbọ́dọ̀ sunkún tàbí kó o bara jẹ́ lọ́nàkọnà. Àwọ́n míì á sọ pé àfi kó o sun ẹkún àsun-ùn-dákẹ́ kó lè hàn pé ó dùn ẹ́. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ bá a ṣe lè fara da ọgbẹ́ ọkàn, ìwádìí táwọn èèyàn sì ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé òótọ́ ni Bíbélì sọ.

Láwọn ilẹ̀ kan, wọ́n gbà pé ọ̀lẹ ọkùnrin ló máa ń sunkún. Àmọ́, ṣé ó yẹ kójú máa ti èèyàn láti sunkún, kódà tó bá jẹ́ ní gbangba? Àwọn onímọ̀ nípa ọpọlọ gbà pé sísunkún jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn ń gbà fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn. Tó o bá sì fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn, ó máa jẹ́ kó o lè gbé ọ̀ràn náà kúrò lọ́kàn, láìka bí ikú ẹni náà ṣe dùn ẹ́ tó. Tá a bá pa ẹ̀dùn ọkàn náà mọ́ra, ńṣe ló máa dá kún ìbànújẹ́ náà. Bíbélì kò fara mọ́ èrò àwọn kan pé kò dáa kéèyàn sunkún tàbí pé ọ̀lẹ ọkùnrin ló máa ń sunkún. Wo àpẹẹrẹ Jésù. Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú, Jésù sunkún ní gbangba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lágbára láti jí i dìde.—Jòhánù 11:33-35.

Nígbà míì, ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ lè máa kanra, àgàgà tó bá jẹ́ pé ńṣe lẹni náà kú láìròtẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ máa kanra. Irú bí ìgbà tí ẹnì kan tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún bá sọ ọ̀rọ̀ láìronú tàbí sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́. Ọkùnrin kan lórílẹ̀ èdè South Africa tó ń jẹ́ Mike sọ pé: “Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni mí nígbà tí bàbá mi kú. Lọ́jọ́ ìsìnkú, òjíṣẹ́ ìjọ Anglican kan sọ pé, Ọlọ́run nílò àwọn èèyàn rere, ó sì máa ń yára mú wọn lọ. * Èyí múnú bí mi gan-an torí pé a ṣì nílò ìrànlọ́wọ́ bàbá mi. Ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] ti kọjá báyìí, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣì ń dùn mí.”

Àwọn míì máa ń dá ara wọn lẹ́bi, pàápàá tó bá jẹ́ ikú òjijì lẹni náà kú. Ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà lè máa sọ léraléra pé, ‘Ká ní mo ti ṣe báyìí ni, ì bá máà kú.’ Tàbí kó jẹ́ pé ìjà ni ìwọ àti ẹni tó kú náà fi túká nígbà tẹ́ ẹ ríra kẹ́yìn. Èyí lè dá kún bó o ṣe ń dá ara rẹ lẹ́bi.

Tó o bá ń kanra tàbí tí ò ń dá ara rẹ lẹ́bi, ó máa dáa kó o má ṣe pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fọ̀rọ̀ náà lọ ọ̀rẹ́ rẹ tó máa fara balẹ̀ gbọ́ ẹ tó sì máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ló máa ń ronú bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Ọ̀rẹ́ tó dáa jù tí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ lè ní ni Ẹlẹ́dàá wa, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. O lè tú ọkàn rẹ jáde sí Ọlọ́run nínú àdúrà nítorí pé ‘ó bìkítà fún ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Bákan náà, Ọlọ́run ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó bá gbàdúrà sí òun fún ìrànlọ́wọ́ máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:6, 7) Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ kí ọkàn wa lè fúyẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń tuni nínú. (Wo  àpótí tó wà nísàlẹ̀.) O tiẹ̀ lè  há díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Bíbélì náà sórí. Irú àwọn ẹsẹ Bíbélì báyìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ pàápàá tó o bá dá wà lọ́wọ́ alẹ́, tí o kò sì rí oorun sùn.—Aísáyà 57:15.

Ẹni ogójì [40] ọdún ni ọkùnrin kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Jack. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àrùn jẹjẹrẹ pa ìyàwó rẹ̀. Jack sọ pé nígbà míì ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà. Àmọ́ gbígbàdúrà ti ràn án lọ́wọ́. Ó ní: “Tí mo bá ti gbàdúrà sí Jèhófà, kì í ṣe mí bíi pé mo dá wà mọ́. Nígbà míì tí oorun bá dá lójú mi láàárín òru, mo máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú Bíbélì, màá sì ronú lé wọn lórí. Lẹ́yìn náà, màá wá sọ ẹdùn ọkàn mi fún Ọlọ́run, ìyẹn sì máa ń mú kí ọkàn mi tutù pẹ̀sẹ̀. Ara mi á wá balẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ kí n rí oorun sùn pa dà.”

Àìsàn kan gbẹ̀mí ìyá ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Vanessa. Àdúrà ló ran òun náà lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Nígbà tí nǹkan bá le koko, mo máa ń ké pe orúkọ Ọlọ́run, màá sì bú sẹ́kún. Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà mi, ó sì máa ń fún mi lókun tí mo nílò.”

Àwọn tó máa ń gba àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nímọ̀ràn sọ pé ó máa ń dáa kí àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn aráàlú lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí máa jẹ́ kó o láyọ̀, á sì mú kí ọkàn rẹ fúyẹ́. (Ìṣe 20:35) Ọ̀pọ̀ Kristẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ti rí i pé ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ti mú kí ara túbọ̀ tù wọ́n.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì kò fi irú ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ ohun mẹ́ta tó máa ń fa ikú.—Oníwàásù 9:11; Jòhánù 8:44; Róòmù 5:12.