Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 3 2016

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Kọ́ Láti Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Obìnrin Kí N Sì Mọyì Ara Mi

Mo Kọ́ Láti Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Obìnrin Kí N Sì Mọyì Ara Mi
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1960

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: FARANSÉ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÒ Ń HÙWÀ IPÁ, MÒ Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ, MI Ò SÌ KA OBÌNRIN SÍ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìpínlẹ̀ Mulhouse lórílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n bí mi sí. Àwọn oníjàgídíjàgan ló sì kún agbègbè yìí. Ohun tí mo máa ń rántí nípa ìgbà kékeré mi ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé lágbègbè náà ló máa ń bá ara wọn fa wàhálà. Nínú ìdílé wa, wọn ò ka àwọn obìnrin sí, àwọn ọkùnrin kì í sì í gbọ́ tẹnu wọn rárá. Ohun tí wọ́n kọ́ mi ni pé obìnrin kò níṣẹ́ míì ju kó dáná, kó tọ́jú ọkọ, kó sì bójú tó àwọn ọmọ.

Nǹkan ò rọrùn rárá fún mi ní kékeré. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ọtí àmujù pa bàbá mi. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin pa ara ẹ̀. Lọ́dún yẹn kan náà, ìjà ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí wa, ojú mi báyìí ni wọ́n ṣe pa ẹnì kan. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn bà mí lẹ́rù gan-an. Àwọn mọ̀lẹ́bí tiẹ̀ tún kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀bẹ àti ìbọn, wọ́n sì kọ́ mi bí màá ṣe jà nígbà tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀. Torí pé mi ò láyọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí, mo sì ń fín àwòrán sára.

Nígbà tí màá fi pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo ti ń mu ìgò bíà mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lójúmọ́, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró. Kí n lè máa rówó mutí, mo máa ń ta irin táwọn èèyàn kó dànù, mo sì tún máa ń jalè. Nígbà tí màá fi pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], mo ti fi ẹ̀wọ̀n jura. Lápapọ̀, ó tó ìgbà méjìdínlógún [18] tí wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n torí ìwà jàgídíjàgan àti olè jíjà.

Nígbà tí màá fi lé lọ́mọ ogún ọdún, ìwà mi ti wá gogò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Mo máa ń fa igbó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogún [20] lójúmọ́, mo sì máa ń lo àwọn oògùn olóró míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìlòkulò oògùn fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró, torí náà, mo máa ń mú ọ̀bẹ àti ìbọn rìn nígbà gbogbo. Ó tiẹ̀ nígbà kan tí mo yìnbọn fún ọkùnrin kan, àmọ́ ọta ìbọn náà ba irin bẹ́líìtì rẹ̀, ó sì ta dànù! Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ni mí nígbà tí màmá mi kú, èyí sì wá mú kí n máa bínú lódìlódì. Ńṣe làwọn èèyàn máa ń sá tí wọ́n bá pàdé mi lọ́nà. Torí pé mo máa ń jà gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àgọ́ ọlọ́pàá ni mo ti máa ń lo òpin ọ̀sẹ̀ tàbí kó jẹ́ ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń bá mi rán ojú ọgbẹ́.

Mo gbéyàwó lọ́mọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28]. Ẹ̀yín náà ti máa mọ̀ pé mi ò lè hùwà tó dáa sí ìyàwó mi. Mo máa ń sọ̀rọ̀ gbá a lórí, mo sì máa ń lù ú. A kì í ṣe nǹkan pa pọ̀ bíi tọkọtaya. Mo ronú pé tí mo bá ti ń kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí mo jí gbé fún un, ìyẹn náà ti tó. Àmọ́, ohun kan tí mi ò rò tẹ́lẹ̀ ṣẹlẹ̀. Ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.  Lẹ́yìn ọjọ́ àkọ́kọ́ tó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ wọn, ó jáwọ́ nínú sìgá mímú, kò sì gba owó tí mo jí mọ́. Kódà, ó dá àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí mo ti fún un pa dà. Èyí múnú bí mi gan-an. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí i nítorí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, nígbà míì màá tú èéfín sìgá sí i lójú. Mo sì máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ládùúgbò.

Lálẹ́ ọjọ́ kan tí mo ti mutí yó kẹ́ri, mo dáná sun ilé wa. Ọpẹ́lọpẹ́ ìyàwó mi, òun ni kò jẹ́ kí èmi àti ọmọbìnrin wa tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún jóná mọ́lé. Nígbà tí ọtí náà dá lójú mi, ńṣe lójú tì mí wẹ̀lẹ̀mù. Mo gbà lọ́kàn ara mi pé Ọlọ́run kò lè dárí jì mí láéláé. Mo rántí ìgbà kan tí mo gbọ́ tí àlùfáà kan sọ pé ọ̀run àpáàdì ni àwọn ẹni burúkú ń lọ. Dókítà ọpọlọ tó ń tọ́jú mi tiẹ̀ sọ fún mi pé: “Ó ti tán fún ẹ! Ọ̀rọ̀ ẹ ti kọjá àtúnṣe.”

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Lẹ́yìn tí ilé wa jóná, a kó lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí ìyàwó mi. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí wá sọ́dọ̀ ìyàwó mi, mo bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí?” Wọ́n fi ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9-11 hàn mí. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ onírúurú àwọn ìwà tí Ọlọ́run kórìíra, àmọ́ ó fi kún un pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.” Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn jẹ́ kó dá mi lójú pé mo lè yí pa dà. Lẹ́yìn náà, wọ́n ka 1 Jòhánù 4:8 fún mi, wọ́n sì jẹ́ kí n mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi. Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, torí náà mo ní kí wọ́n wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìgbà méjì lọ́sẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé wọn lọ sí ìpàdé. Mo sì tún máa ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé.

Àárín oṣù kan péré ni mo jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti ọtí àmujù. Ara mi ò wá lélẹ̀ mọ́! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní onírúurú ìṣòro tí àwọn tó jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró máa ń ní, bí àlákálàá, ẹ̀fọ́rí àti ara ríro. Láìfi gbogbo ìnira yìí pè, mo mọ̀ pé Jèhófà kò fi mí sílẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń fún mi lókun. Ọ̀rọ̀ mi wá dà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ bí Ọlọ́run ṣe ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Nígbà tó yá, mo jáwọ́ pátápátá nínú sìgá mímu.—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Yàtọ̀ sí pé Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti tún ìgbésí ayé mi ṣe, ó tún ti jẹ́ kí ìdílé mi tòrò. Mi ò hùwàkiwà sí ìyàwó mi mọ́. Mo ti ń fọ̀wọ̀ tiẹ̀ wọ̀ ọ́, mo sì máa ń lo èdè ọ̀wọ̀ fún un, irú bíi “jọ̀wọ́” àti “o ṣeun.” Mo sì tún ti jẹ́ bàbá gidi fún ọmọbìnrin wa. Lẹ́yìn tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọdún kan, mo tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìyàwó mi, èmi náà ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Kò sí àní-àní pé ìlànà Bíbélì tí mò ń tẹ̀ lé ló jẹ́ kí n ṣì wà láàyè báyìí. Àwọ́n mọ̀lẹ́bí mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá gbà pé, ó ṣeé ṣe kí n ti kú látàrí lílo oògùn olóró tàbí kí àwọn tí mò ń bá jà ti lù mí pa.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ti mú kí èmi, ìyàwó mi àti ọmọ mi jọ máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà torí pé ó jẹ́ kí n mọ ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi baálé ilé. (Éfésù 5:25; 6:4) A ti wá ń ṣe nǹkan pa pọ̀ bí ìdílé. Ní báyìí, dípò tí màá fi sọ ìyàwó mi di gbọ́ńjẹ ṣúlẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń tì í lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ajíhìnrere tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Òun náà sì ń tì mí lẹ́yìn kí n lè ṣe iṣẹ́ alàgbà ìjọ tí mò ń ṣe.

Ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní sí wa wọ̀ mí lọ́kàn gidigidi. Ó sì máa ń wù mí tọkàntọkàn láti sọ nípa ànímọ́ rere rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n rò pé ọ̀rọ̀ wọn kò ní àtúnṣe mọ́, torí àwọn èèyàn gbà pé ọ̀rọ̀ tèmi náà ti kọjá àtúnṣe tẹ́lẹ̀. Mo mọ̀ pé Bíbélì ní agbára láti ran ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ kó lè tún ayé rẹ̀ ṣe, kí ẹni náà sì gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin kí n sì tún bọ̀wọ̀ fún wọn. Mo sì tún ti kọ́ láti mọyì ara mi.