Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti rí bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé ẹ̀bi fún aláre tí wọ́n sì ń gbé àre fún ẹlẹ́bi, a tún ń rí bí àwọn ẹni ibi ṣe ń fìyà jẹ aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Ṣé ìgbà kan tiẹ̀ ń bọ̀ tí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìkà kò ní sí mọ́?

Nínú Bíbélì, Sáàmù 37 dáhùn ìbéèrè yìí, ó sì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an. Gbọ́ ohun tó sọ nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí.

  • Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ń ni wá lára?​—Ẹsẹ 1 àti 2.

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni burúkú? ​—Ẹsẹ 10.

  • Báwo ni ọjọ́ ọ̀la àwọn tó ń hùwà rere ṣe máa rí?​—Ẹsẹ 11 àti 29.

  • Kí ló yẹ ká máa ṣe báyìí?​Ẹsẹ 34.

Ohun tí Ọlọ́run sọ ní Sáàmù 37 jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára fún àwọn tó ‘ní ìrètí nínú Jèhófà, tí wọ́n sì ń pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.’ Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì mọ ohun tó yẹ kó o ṣe kí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ lè gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ yẹn.