Ìhìn rere Ìjọba Olọ́run ti dé gbogbo ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:14) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló gbé Ìjọba yìí kalẹ̀. Nínú ìwé Dáníẹ́lì orí kejì, a rí àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìjọba èèyàn táá máa ṣàkóso látìgbà ayé Bábílónì àtijọ́ títí di àkókò tá a wà yìí. Ẹsẹ 44 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó ní:

“Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn míì nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, ó sì máa mú ìtura bá gbogbo èèyàn tó wà láyé. Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú Ìjọba Ọlọ́run? Díẹ̀ rèé lára àwọn ìlérí àgbàyanu tó máa ṣẹ láìpẹ́.

 • KÒ NÍ SÍ OGUN MỌ́

  Sáàmù 46:9: “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”

  Òbítíbitì owó ni àwọn orílẹ̀-èdè ń ná sórí àwọn nǹkan ìjà ogun tó ń gbẹ̀mí àwọn èeyàn lóde òní. Báwo lo ṣe rò pé ayé yìí máa rí tó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń fi owó yẹn ṣe àwọn nǹkan tó máa ṣàǹfààní fọ́mọ aráyé? Ó dájú pé kò ní sí ogun mọ́ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

 • KÒ NÍ SÍ ÀÌSÀN MỌ́

  Aísáyà 33:24: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”

  Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí kò bá sẹ́ni tó ní àrùn ọkàn, àrùn jẹjẹrẹ, àìsàn ibà tàbí àìsàn èyíkéyìí mọ́. Kò ní sí ilé ìwòsàn àtàwọn oògùn mọ́. Gbogbo èèyàn pátá ni ara wọn máa le lábẹ́ ìjọba Ọlọ́run.

 • OÚNJẸ Á TÓ, Á TÚN ṢẸ́ KÙ

  Sáàmù 72:16: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”

  Oúnjẹ tó máa tó gbogbo èèyàn jẹ ni ilẹ̀ á máa mú jáde, á pọ̀ gan-an, á kárí, á sì tún jẹ́ oúnjẹ aṣaralóore.

 • KÒ NÍ SÍ ÌRORA, ÌBÀNÚJẸ́ ÀTI IKÚ MỌ́

  Ìṣípayá 21:4: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

   Ìyẹn ni pé a máa di pípé, ayé á di Párádísè, a ó sì máa wà láàyè títí láé! Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí nìyẹn.

‘YÓÒ NÍ ÀṢEYỌRÍ SÍ RERE TÍ Ó DÁJÚ’

Ṣé àlá tí kò lè ṣẹ làwọn nǹkan yìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì nípa bí ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú jẹ́ ohun àgbàyanu, àmọ́ ó ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́ pé èeyàn ò ní kú mọ́, wọ́n á sì máa gbé ayé títí láé. Ó tó nǹkan tó ń ṣeni ní kàyéfì lóòótọ́, torí pé kò sí èèyàn tí irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí tó lè sọ bó ṣe ń rí fún wa.

Ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti mú ọmọ aráyé lẹ́rú, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrora, ìyà àti ìdààmú ti fojú ìran èèyàn rí màbo, débi pé ọ̀pọ̀ èeyàn ti gba kámú pé bí nǹkan á ṣe máa rí lọ nìyí. Ṣùgbọ́n, bí Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí nǹkan rí fún wa kọ́ nìyẹn.

Kó bàa lè dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ṣe àwọn nǹkan tó ṣèlérí fún wa, ó wá fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé: “Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”​—Aísáyà 55:11.

Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run “tí kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Pẹ̀lú àwọn ìlérí àgbàyanu tí Olọ́run ṣe nípa ọjọ́ iwájú, ó bọ́gbọ́n mu ká béèrè pé: Ṣé lóòótọ́ ni àwa èèyàn á máa gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé? Kí ló yẹ ká ṣe ká bàa lè jàǹfààní àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí ní àwọn ojú ìwé tó kù nínú ìwé yìí.