Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?

Ṣé o máa ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe máa rí? Bíbélì sọ pé:

“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”​—Sáàmù 37:29.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí máa jẹ́ kó o mọ àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé àti àwa èèyàn, á tún jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti jàǹfààní nínú rẹ̀.