Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 2 2017

Okòwò tó lówó lórí gan-an ni òwò ẹrú láàárín ilẹ̀ Áfíríkà àti Amẹ́ríkà

Òwò Ẹrú​—Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní

Òwò Ẹrú​—Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní

Wọ́n ṣèlérí fún Blessing * pé tó bá ti dé ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n máa bá a wáṣẹ́ aṣerunlóge. Àmọ́, ọjọ́ mẹ́wàá gbáko ni wọ́n fi lù ú bí ẹni máa pa á, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ ọn pé wọ́n máa lọ fìyà jẹ àwọn ẹbí rẹ̀ tó fi sílẹ̀, nígbẹ̀yìn wọ́n fipá mú un wọṣẹ́ aṣẹ́wó.

Àpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì

Wọ́n ní Blessing gbọ́dọ̀ máa pa owó tó tó 200 sí 300 euros, [nǹkan bíi 64,000 sí 100,000 náírà] lálaalẹ́, kó lè san gbèsè tó lé ní 40,000 euros [nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà] tí ọ̀gá rẹ̀ sọ pé ó jẹ òun. * Blessing sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò máa ń ronú pé kí n sá lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí kí wọ́n má lọ ṣe àwọn ẹbí mi léṣe. Iwájú ò wá ṣeé lọ, ẹ̀yìn ò sì ṣeé pa dà sí.” Àwọn èèyàn tó lé ni mílíọ̀nù mẹ́rin lọ̀rọ̀ wọn jọ ti Blessing, tí wọ́n ti fipá mú láti máa ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó.

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù tà á sí oko ẹrú nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Ó wá lọ di ẹrú ní ilé ọkùnrin kan tó gbajúmọ̀ nílẹ̀ Íjíbítì. Lóòótọ́ wọn ò kọ́kọ́ fìyà jẹ Jósẹ́fù bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Blessing. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ní kò wá bá òun sùn, ṣùgbọ́n Jósẹ́fù kọ̀. Torí náà, ó fẹ̀sùn èké kan Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá òun lò pọ̀. Wọ́n sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n.​—Jẹ́nẹ́sísì 39:1-20; Sáàmù 105:17, 18.

Ayé àtijọ́ ni wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú; ayé òde òní ni Blessing ṣe ẹrú ní tiẹ̀. Síbẹ̀ àwọn méjèèjì ló jìyà látàrí àṣà kan tó ti wà látayébáyé, ìyẹn ni òwò ẹrú, níbí tí wọ́n ti ń ta èèyàn bí ẹni ta ẹran nítorí owó.

OGUN MÚ KÍ ỌJÀ ẸRÚ TÀ WÀRÀWÀRÀ

Láyé àtijọ́, ogun jíjà jẹ́ ọ̀nà tó rọrùn láti fi kó ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Íjíbítì kan tó ń jẹ́ Thutmose Kẹta lọ jagun nílẹ̀ Kénáánì, ó kó nǹkan  bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún [90,000] èèyàn lẹ́rú. Àwọn ọmọ Íjíbítì sì fi wọ́n ṣiṣẹ́ awakùsà, kíkọ́ tẹ́ńpílì, àti ilẹ̀ gbígbẹ́.

Lásìkò ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ogun máa ń jẹ́ kí wọ́n rí omilẹgbẹ èèyàn kó lẹ́rú, ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń jagun torí pé wọ́n nílò ẹrú. Wọ́n tiẹ̀ fojú bù ú pé nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìlàjì àwọn èèyàn tó ń gbé ìlú Róòmù ló jẹ́ ẹrú. Àwọn ará Íjíbítì àti Róòmù máa ń fìyà jẹ àwọn ẹrú wọn gan-an. Kódà àwọn ẹrú tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà nílẹ̀ Róòmù kì í ju ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún lọ kí wọ́n tó kú.

Ńṣe ni ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ẹrú ń le koko sí i bọ́dún ṣe ń gorí ọdún. Láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sí ìkọkàndínlógún, òwò ẹrú tí ilẹ̀ Áfíríkà àti Amẹ́ríkà jọ dàpọ̀ ni okòwò tó ń mówó wọlé jù lọ jákèjádò ayé. Ìròyìn àjọ UNESCO sọ pé nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù [30] èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọdé ni wọ́n tà lẹ́rú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn ló sì máa ń kú nígbà tí wọ́n bá ń kó wọn sọdá òkun Àtìláńtíìkì. Olaudah Equiano, tí wọ́n kó lẹ́rú ròyìn pé: “Igbe oro táwọn obìnrin ń ké àti ìrora táwọn èèyàn ń jẹ kí wọ́n tó kú, mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọjá àfẹnusọ.”

Ó ṣeni láàánú pé wọ́n ṣì máa ń mú àwọn èèyàn lẹ́rú títí dòní. Àjọ International Labour Organization sọ pé àwọn èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọdé tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nú mọ́kànlélógún [21] ló ń ṣẹrú, tí wọ́n sì ń san owó táṣẹ́rẹ́ fún tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ sanwó fún wọn rárá. Lóde òní, wọ́n máa ń fi àwọn ẹrú ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn, bí ilẹ̀ gbígbẹ́, ṣíṣe bíríkì, iṣẹ́ aṣẹ́wó àti iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bófin mu, síbẹ̀ ńṣe ni mímúni lẹ́rú túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ṣì wà lábẹ́ ìsìnrú

WỌ́N GBA ÒMÌNIRA

Bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn ẹrú rí màbo ti mú kí púpọ̀ nínú wọn ja àjàgbara. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Spartacus kó àwọn ẹrú tó tó nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] jọ láti sọ̀tẹ̀ sí Róòmù, àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn já sí. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún, àwọn ẹrú tó wà ní erékùṣù Caribbean lágbègbè Hispaniola gbógun ti àwọn ọ̀gá wọn. Ọdún mẹ́tàlá ni ogun abẹ́lé fi jà lágbègbè náà, nítorí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ẹrú ní oko ìrèké, èyí ló ṣokùnfà bí wọ́n ṣe dá orílẹ̀-èdè Haiti sílẹ̀ lọ́dún 1804.

Látìgbà tí àwọn ẹrú tí ń gba òmìnira, èyí tó tíì kẹ́sẹ járí jù lọ ni bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kúrò lóko ẹrú  ní Íjíbítì. Odindi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n tó nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn ló bọ́ lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n nílò òmìnira yìí lójú méjèèjì. Bíbélì sọ ohun tí ojú wọn rí ní Íjíbítì pé “wọ́n lò wọ́n bí ẹrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀.” (Ẹ́kísódù 1:11-14) Kódà, ọba Fáráò kan tiẹ̀ pàṣe pé kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọkùnrin tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.​—Ẹ́kísódù 1:8-22.

Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bọ́ lóko ẹrú ní Íjíbítì ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an torí pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gbà wọ́n sílẹ̀. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú. Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè.” (Ẹ́kísódù 3:7, 8) Títí dòní làwọn Júù fi ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ́dọọdún kí wọ́n lè rántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yẹn.​—Ẹ́kísódù 12:14.

BÍ FÍFI ÈÈYÀN ṢE ẸRÚ ṢE MÁA DÓPIN TÍTÍ LÁÉ

Bíbélì sọ pé: ‘Kò sí àìṣòdodo lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.’ Ó sì mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò tíì yí pa dà. (2 Kíróníkà 19:7; Málákì 3:6) Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé kó lè wá “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè . . . , láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀.” (Lúùkù 4:18) Ṣé èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó wà lóko ẹrú máa dòmìnira? Rárá o. Ńṣe ni Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé kó lè wá tú wa sílẹ̀ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Jésù sọ pé: “Òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Lóde òní pàápàá, òtítọ́ tí Jésù kọ́ni ń tú àwọn èèyàn tó wà nínú ìdè sílẹ̀.​—Wo àpótí náà “ Mo Bọ́ Lóko Ẹrú Oògùn Olóró.”

Ọlọ́run ran Jósẹ́fù àti Blessing lọ́wọ́ láti bọ́ lóko ẹrú. Ìtàn Jósẹ́fù wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì orí 39 sí 41. Ibo wá lọ̀rọ̀ Blessing tá a fi bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí já sí.

Nígbà tí wọ́n lé e kúrò ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù, ó sá lọ sí Sípéènì. Ibẹ̀ ló ti pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó wá pinnu pé òun máa tún ayé òun ṣe, torí náà ó wáṣẹ́ gidi ṣe, ó sì bẹ ọ̀gá rẹ̀ pé kó dín gbésè tí òun á máa san lóṣooṣù kù. Lọ́jọ́ kan, Blessing gba ipè látọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Ó ní òun ti wọ́gi lé gbogbo gbèsè tí Blessing jẹ, ó sì ní kó dárí ji òun. Kí ló fa àyípadà yìí? Obìnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Blessing wá sọ pé: “Òtítí máa ń sọni dòmìnira lọ́nà tó ń yani lẹ́nu.”

Ó dun Jèhófà Ọlọ́run bó ṣe rí ìyà táwọn ará Íjíbítì fi jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; ó sì dájú pé ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí irú ìwà bẹ́ẹ̀ lóde òní. Ká sòótọ́, àyípadà ńlá gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwa èèyàn kí àṣà mímúni lẹ́rú tó lè dópin. Ọlọ́run sì ṣèlérí pé òun máa ṣe àyípadà yẹn. “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”​—2 Pétérù 3:13

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.

^ ìpínrọ̀ 3 Lásìkò yẹn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé iye kan náà ni euro àti dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà jẹ́.