ÀWỌN ẹ̀sìn jákèjádò ayé, irú bíi Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àtàwọn ẹlẹ́sìn míì, máa ń fi dandan lé e fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn àlùfáà wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbéyàwó. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àṣà yìí ló mú kí ìṣekúṣe wọ́pọ̀ láàárín àwọn aṣáájú ẹ̀sìn lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, Ṣé ó pọn dandan kí Kristẹni òjíṣẹ́ wà láìgbéyàwó? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ibi tí àṣà yìí ti bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn náà a ó wá jíròrò ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó.

IBI TÍ ÀṢÀ YÌÍ TI BẸ̀RẸ̀

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé “àwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń yàn láti má ṣe gbéyàwó tàbí lọ́kọ, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n kò ní máa ní ìbálòpọ̀ rárá.” Nígbà tí Pope Benedict Kẹrìndínlógún ń bá àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ̀rọ̀, ìyẹn Roman Curia, lọ́dún 2006, ó sọ pé bí wọ́n ṣe ń fi dandan lé e pé káwọn aṣáájú ẹ̀sìn má ṣègbéyàwó “jẹ́ àṣà àtayébáyé kan tó bẹ̀rẹ̀ láti àkókò àwọn Àpọ́sítélì.”

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ló dá àṣà káwọn èèyàn má ṣègbéyàwó sílẹ̀ o. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọ̀dún kìíní, kìlọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ nípa àwọn ọkùnrin tí wọ́n á máa sọ “àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà” tí wọ́n á sì máa “ka gbígbéyàwó léèwọ̀.”​—1 Tímótì 4:1-3.

Àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ni àṣà kí wọ́n máa ka ìgbéyàwó léèwọ̀ bẹ̀rẹ̀, tó sì rá pálá wọnú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì “Kristẹni” nílẹ̀ Yúróòpù. Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Celibacy and Religious Traditions, sọ ìdí táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi tẹ́wọ́ gba àṣà yìí, ó ní “ó jẹ́ nítorí àwuyewuye  kan tó wáyé ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.”

Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn Bàbá Ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣagbátẹrù rẹ̀ pé kí àwọn àlùfáà má ṣégbèyàwó. Wọ́n sọ pé ńṣe ni níní ìbálòpọ̀ máa ń sọni di aláìmọ́, kò sí bá iṣẹ́ àlùfáà mu. Ṣùgbọ́n, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Encyclopædia Britannica sọ pé “àwọn àlùfáà àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù ṣì máa ń gbéyàwó títí di ọwọ́ ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá.”

Ibi ìpàdé Lateran Councils tí wọ́n ṣe lọ́dún 1123 àti 1139 ní ìlú Róòmù ni wọ́n ti sọ ọ́ di òfin pé àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó mọ́. Òfin yìí sì ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ṣì ń tẹ̀ lé títí dòní. Wọ́n gbà pé èyí kò ní jẹ́ kí àṣẹ bọ́ lọ́wọ́ àwọn, kò sì ní jẹ́ kí àwọn àlùfáà tó gbéyàwó máa sọ ohun ìní ṣọ́ọ̀ṣì di ogún ìní àwọn ọmọ wọn.

OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WÒ Ó

Kedere ni Bíbélì ṣàlàyé ojú tí Ọlọ́run fi wo kéèyàn wà láìgbéyàwó. Jésù sọ nípa àwọn tí kò gbéyàwó bíi tirẹ̀ pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ “ní tìtorí ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 19:12) Bákan náa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wíwà ní àpọ́n bíi tiẹ̀ pé ó jẹ́ “nítorí ìhìn rere.”​—1 Kọ́ríńtì 7:37, 38; 9:23.

Ṣùgbọ́n, Jésù àti Pọ́ọ̀lù kò sọ ọ́ di dandan fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ láti má ṣègbéyàwó. Jésù sọ pé wíwà ní àpọ́n jẹ́ “ẹ̀bùn,” kì í sì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ló ní ẹ̀bìn yìí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa “àwọn wúńdíá,” ìyẹn àwọn tí kò ṣègbéyàwó rí, ó sọ gbangba-gbàǹgbà pé: “Èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo sọ èrò mi.”​—Mátíù 19:11; 1 Kọ́ríńtì 7:25.

Láfíkún sí i, Bíbélì fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tó fi mọ́ Pétérù, ló ní ìyàwó. (Mátíù 8:14; Máàkù 1:​29-31; 1 Kọ́ríńtì 9:5) Bákan náà, nítorí ìwà ìṣekúṣe tó gbòde kan nílẹ̀ Róòmù láyé ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn Kristẹni alábòójútó tó bá ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkọ aya kan,” kí wọ́n sì ní “àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹríba.”​—1 Tímótì 3:​2, 4.

Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé kéèyàn ní ìyàwó àmọ́ kó má ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ o. Torí Bíbélì dìídì sọ pé “kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un” àti pé kí àwọn tọkọtaya ‘má ṣe máa fi ìbálòpọ̀ du ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’ (1 Kọ́ríńtì 7:3-5) Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run kò fọwọ́ sí àṣà kéèyàn má ṣègbéyàwó, kì í sì í ṣe ọ̀rànyàn fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́.

NÍTORÍ ÌHÌN RERE

Tí kì í bá ṣe ọ̀rànyàn pé káwọn Kristẹni òjíṣẹ́ wà láìgbéyàwó, kí wá nìdí tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi sọ ohun tó dáa nípa rẹ̀? Ìdí ni pé téèyàn bá wà ní àpọ́n, ó máa ráyè láti wàásù ìhìn rere fáwọn ẹlòmíì. Àwọn tí kò gbéyàwó lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí pé wọn ò ní àníyàn táwọn tó ti ṣègbéyàwó máa ń ní.​—1 Kọ́ríńtì 7:32-35.

Gbé àpẹẹrẹ David yẹ̀wò. Mexico City ló ń gbé, ó sì ní iṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́. Àmọ́ ó fúnra rẹ̀ pinnu láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó sì lọ sí ìgbèríko kan lórílẹ̀-èdè Costa Rica, kó lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé David gbà pé bí òun kò ṣe tíì gbéyàwó ló jẹ́ kí òun lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Kò rọrùn fún mi láti ṣe àyípadà tó yẹ kí àṣà wọn àtí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn lè bá mi lára mu. Àmọ́, torí pé èmi nìkan ni, kò pẹ́ tí ara mi fi mọlé.”

Kristẹni ni Claudia kò sì tíì lọ́kọ. Ó máa ń lọ wàásù láwọn àgbègbè táwọn oníwàásù kò ti pọ̀, ó sọ pé: “Mo gbádùn iṣẹ́ ìsìn mi sí Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ mi àti àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run ti lágbára sí i torí pé mó máa ń rí ọwọ́ Ọlọ́run láyé mi.”

“Kì í ṣe dandan kó o wà ní àpọ́n tàbí kó o gbéyàwó. Ohun tó máa fún ẹ láyọ̀ ni pé kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà Ọlọ́run.”​—Claudia

Kò yẹ kí wíwà ní àpọ́n di ẹrù ìnira. Claudia fi kún un pé: “Kì í ṣe dandan kó o wà ní àpọ́n tàbí kó o gbéyàwó. Ohun tó máa fún ẹ láyọ̀ ni pé kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà Ọlọ́run.”​—Sáàmù 119:1, 2