OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Alexandra fẹ́ rìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè kan ní South America sí òmíràn. Nígbà tí bọ́ọ̀sì tó wọ̀ dé bọ́dà, ó gbọ́ tí wọ́n ń sọ fún awakọ̀ bọ́ọ̀sì náà pé: “Bọ́ọ̀sì yìí lè máa lọ, àmọ́ ọmọ Ṣáínà yẹn ò gbọ́dọ̀ lọ!” Ló bá sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀, ó sì rí ọ̀dọ́kùnrin ọmọ Ṣáínà kan níbi tó ti ń gbìyànjú láti fi èdè Sípáníìṣì táátààtá tó gbọ́ ṣàlàyé ohun tójú ẹ̀ rí fún àwọn aṣọ́bodè. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Alexandra, ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Chinese ló ń lọ. Torí náà, ó yọ̀ǹda láti túmọ̀ ohun tó ń sọ.

Ọkùnrin náà sọ pé òun ní ìwé àṣẹ ìgbélùú, àmọ́ àwọn olè ti jí ìwé náà àti owó lápò òun. Aṣọ́bodè náà kò kọ́kọ́ gba ohun tó sọ gbọ́, ó tiẹ̀ tún ronú pé ajínigbé ni Alexandra. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yìn, ó gba ohun tí ọkùnrin náà sọ, síbẹ̀ ó ní láti san owó ìtanràn torí pé kò ní ìwé ẹ̀rí tó yẹ kó ní lọ́wọ́. Níwọ̀n bí kò ti sí owó kankan lọ́wọ́ rẹ̀, Alexandra sọ pé òun máa yá a ní ogún dọ́là [$20]. Inú ọkùnrin náà dùn gan-an, ó sì sọ pé òun máa fún un ní owó náà pa dà pẹ̀lú èlé. Alexandra ṣàlàyé fún un pé òun kò retí pé kó san èlé fún òun lórí owó náà, pé ńṣe ni òun kàn fẹ́ ràn án lọ́wọ́ torí pé ohun tó tọ́ láti ṣe nìyẹn. Ó wá fún ọkùnrin náà ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ó máa ń dùn mọ́ wa tá a bá gbọ́ báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ọ̀làwọ́ sẹ́ni tí wọn ò mọ̀ rí. Ó dájú pé àwọn èèyàn tó ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn àtàwọn tí kò tiẹ̀ ṣẹ̀sìn rárá náà máa ń hu irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ ìwọ́ ni, ṣé ó máa yá ẹ lára láti hu irú ìwà ọ̀làwọ́ yìí? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an torí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ìwà ọ̀làwọ́ tún bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu torí àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé ó máa ń ṣe ara wa láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

“OLÙFÚNNI ỌLỌ́YÀYÀ”

Àwọn ohun tí à ń rí fi hàn pé àwọn ọ̀làwọ́ èèyàn máa ń láyọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” Àwọn Kristẹni tó fi owó ṣètọrẹ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí nǹkan nira fún ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 8:4; 9:7) Pọ́ọ̀lù ò sọ̀ pé ayọ̀ tí wọ́n ní ló jẹ́ kí wọ́n fúnni lẹ́bùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé, bí wọ́n ṣe ń fúnni lẹ́bùn ló jẹ́ kí wọ́n láyọ̀.

Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé tá a bá ń fúnni lẹ́bùn, “ó máa múnú wa dùn, àá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, àá sì fọkàn tán wọn. Ó sì tún máa ń jẹ́ ká ní ìtẹ́lọ́ruń.” Ìwádìí míì fi hàn pé “tá a bá fúnyàn lówó, ara wa máa ń yá gágá ju ká ná owó náà fún ara wa lọ.”

Ṣé o máa ń ronú pé o ò lè fúnyàn ní nǹkan torí pé kò sówó lọ́wọ́ rẹ? Ká sòótọ́, tá a bá jẹ́ “olùfúnni ọlọ́yàyà” a máa rí ayọ̀ tó ń wá látinú fífúnni. Tá a bá ní èrò tó tọ́, a ò ní dúró dìgbà tá a bá ní owó ńlá ká tó lè fúnyàn ní nǹkan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi owó ránṣẹ́ sí àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn  yìí, ó sì sọ pé: “Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló ti jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ni mo fi ń ṣe ìtìlẹ́yìn ní Gbọ́ngàn Ìjọba.” Àmọ́ ó fi kún un pé: “Jèhófà Ọlọ́run ti fún mi ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó ju ohun tí mo fún un lọ. . . . Mo dúpẹ́ pé ẹ fún mi láyè láti ṣe ìtọrẹ yìí, ó mára tù mí gan-an ni.”

Àmọ́ kì í ṣe owó nìkan la lè fúnyàn o. Àwọn ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà fúnni ní nǹkan.

O MÁA NÍ ÌLERA TÓ DÁA TÓ O BÁ Ń FÚNNI NÍ NǸKAN

Fífúnni ní nǹkan máa mú èrè wá fún ẹ àtàwọn míì

Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ìkà ènìyàn ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ẹ̀yà ara òun fúnra rẹ̀.” (Òwe 11:17) Àwọn onínúure èèyàn máa ń lawọ́, wọ́n sì máa ń múra tán láti fúnni ní àkókò wọn, okun wọn, ìtọ́jú àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Irú ìwà ọ̀làwọ́ yìí máa ń ṣe wọ́n láǹfààní lónírúurú ọ̀nà, èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé ó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìlera tó dáa.

Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ ní ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn. Ní kúkúrú, wọ́n máa ń ní ìlera tó dáa. Tí ẹni tó ní àìsan lílekoko, bíi multiple sclerosis tàbí HIV bá ń fúnni ní nǹkan, ó máa ń jẹ́ kí ìlera rẹ̀ dára sí i. Ẹ̀rí tún fi hàn pé táwọn tó ń gbìyànjú láti fi ọtí àmujù sílẹ̀ bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ìdààmú ọkàn wọn máa ń dínkù, ó sì máa jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti má ṣe pa dà máa mu ọtí lámujù.

Ìdí sì ni pé téèyàn bá ń “káàánú àwọn míì, kò ní jẹ́ ká máa ronú òdì.” Tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan, ó tún máa dín ìdààmú àti ìṣòro ẹ̀jẹ̀ ríru kù. Tí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú bá sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn wọn tètè fúyẹ́.

Kò sí iyè méjì pé fífúnni ní nǹkan máa mú èrè wá fún ẹ.

Ó MÁA Ń JẸ́ KÁWỌN MÍÌ DI Ọ̀LÀWỌ́

Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.” (Lúùkù 6:38) Tó o bá ń fúnni ní nǹkan, àwọn èèyàn máa fi ẹ̀mí ìmoore hàn, ó sì máa sọ àwọn náà di ọ̀làwọ́. Torí náà, fífúnni máa ń jẹ́ kí àjọṣe tó dáa wà láàárín àwọn èèyàn.

Fífúnni máa ń jẹ́ kí àjọṣe tó dáa wà láàárín àwọn èèyàn

Àwọn tó ń ṣewádìí nípa àjọṣe àwọn èèyàn ti kíyè sí i pé “àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́ máa ń mú kí àwọn míì ní ìwà ọ̀làwọ́.” Tá a bá “kàn kà nípa inú rere àrà ọ̀tọ̀ tẹ́nì kan fi hàn, ó máa ń mú káwa náà túbọ̀ máa hùwà ọ̀làwọ́.” Ìwádìí tiẹ̀ tún fi hàn pé, “ìwà ọ̀làwọ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń hù lè mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míì tí a ò tiẹ̀ mọ̀ rí di ọ̀làwọ́.” Bí àpẹẹrẹ, ìwà ọ̀làwọ́ kan ṣoṣo lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn láàárín ìlú, táá sì mú kí wọ́n máa fún ara wọn ní nǹkan. Ṣé kò ní wù  ẹ́ láti gbé nírú ìlú bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé èrè bàǹtà banta la máa rí tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ fífúnni di àṣà wọn.

Ohun kan ṣẹlẹ̀ nílùú Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Lẹ́yìn tí ìjì líle kan jà tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ilé wọn bà jẹ́. Bí wọ́n ṣe ń dúró kí wọ́n kó irinṣẹ́ tí wọ́n máa lò dé, wọ́n ṣàkíyèsí pé fẹ́ǹsì ará àdúgbò kan ti bà jẹ́, wọ́n sì ní àwọn máa báa tún un ṣe. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, aláàdúgbò náà kọ lẹ́tà sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Títí láé ni màá máa dúpẹ́ oore yìí. Mo rí i pé àwọn èèyàn yìí wà lára àwọn tí ìwà wọn dára jù lọ nínú àwọn èèyàn tí mo tíì bá pàdé.” Ẹ̀mí ìmoore tó ní mú kó fi owó tó jọjú ránṣẹ́ sí wa, ká lè lò ó lẹ́nu iṣẹ́ tó pè ní iṣẹ́ àkànṣe táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ẸNI TÍ ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́ RẸ̀ GA JÙ LỌ

Ìwádìí tó gbàfiyèsí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé “ohun kan wà tó ń mú kó máa wu àwa èèyàn láti ran àwọn míì lọ́wọ́.” Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn ọmọdé “ti máa ń lẹ́mìí ọ̀làwọ́ kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n mọ̀rọ̀ sọ.” Kí nìdí? Bíbélì sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀.” Èyí fi hàn pé àwa èèyàn ní irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

Ìwà ọ̀làwọ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ní. Ó fún wà ní ẹ̀mí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan míì táá jẹ́ ká láyọ̀. (Ìṣe 14:17; 17:26-28) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a máa túbọ̀ mọ Baba wa ọ̀run, àá sì tún mọ àwọn ìlérí àtàtà tó ṣe fún wa. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti ṣèlérí àkókò kan lọ́jọ́ iwájú tí gbogbo wa máa láyọ̀. * (1 Jòhánù 4:9, 10) Jèhófà Ọlọ́run ló pilẹ̀ ìwà ọ̀làwọ́, ó sì dá wa ní àwòrán rẹ̀. Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa jíjẹ́ ọ̀làwọ́, a máa rí èrè níbẹ̀, a sì tún máa rí ojúure Ọlọ́run.​—Hébérù 13:16.

Ṣó ò gbàgbé Alexandra, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? Ibo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá yọrí sí? Ẹnì kan tí wọ́n jọ wọkọ̀ sọ fún Alexandra pé owó ẹ ti wọgbó. Àmọ́ ọmọ Ṣáínà yẹn pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà ní ibi tí ọkọ̀ náà tún ti dúró, ó gba owó lọ́wọ́ wọn, ó sì fún Alexandra ní ogún dọ́là [$20] rẹ̀ pa dà. Láfikún sí i, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí Alexandra ṣe sọ fún un. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, inú Alexandra dùn láti pàdé ọkùnrin náà ní àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ní èdè Chinese lórílẹ̀-èdè Peru. Ọkùnrin náà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún oore tó ṣe fún un, ó sì ní kí Alexandra àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá lọ jẹun ní ilé oúnjẹ òun.

Tá a bá ń fáwọn èèyàn ní nǹkan tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó máa fún wa láyọ̀ tó gọntíọ. O sì tún lè tipa bẹ́ẹ̀ ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà Ọlọ́run tó fún wa ní gbogbo ẹ̀bùn rere! (Jákọ́bù 1:17) Ṣé ìwọ náà ń rí èrè tó wà nínú fífúnni ní nǹkan?

^ ìpínrọ̀ 21 Tó o bá fẹ́ ìsọfúnnni síwájú sí i, wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo. Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ.