Kí Lèrò Rẹ?

Kí ni ẹ̀bùn tó dára jù tí Ọlọ́run fún wa?

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.”​Jòhánù 3:16.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò ìdí tí Ọlọ́run fi rán Jésù wá sáyé láti wá kú fún wa àti bá a ṣe lè fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún ẹ̀bùn náà.