“Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n tú sí “aláìlábòsí” túmọ̀ sí “ohun kan tó dára lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” Ó tún túmọ̀ sí ìwà rere tàbí ìṣòtítọ́ tí kò lẹ́gbẹ́.

Ọwọ́ pàtàkì làwọn Kristẹni fi mú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ yìí, ó ní: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” Báwo la ṣe lè jẹ́ aláìlábòsí?

MÁ ṢE FÀYÈ GBA ÈRÒKÉRÒ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wo gíláàsì lárààárọ̀ kí wọ́n tó jáde kúrò nílé. Kí nìdí? Torí pé wọ́n fẹ́ kí ìrísí wọn dáa lójú àwọn èèyàn. Àmọ́, ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju pé kéèyàn ṣe irun tó dáa tàbí kó wọ aṣọ tó gbayì. Nǹkan náà ni, irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún tàbí ìwà wa. Ìwà tí à ń hù lè buyì kún wa tàbí kó kàn wá lábùkù láìka bá a ṣe rẹwà sí.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dìídì sọ pé ó máa ń wu àwa èèyàn láti ṣe ohun tó burú. Jẹ́nẹ́sísì 8:21 sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” Tórí náà, ká tó lè jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ darí wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bó ṣe sapá tó láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ darí òun, ó ní: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:22, 23.

Bí àpẹẹrẹ, tí ọkàn wa bá ń sún wa ṣáá pé ká hùwà àìṣòótọ́, kò yẹ ká gbà láti ṣe ohun tí ọkàn wa ń fẹ́ sún wa ṣe. Àwa fúnra wa la máa yan ohun tá a máa ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn là ń gbé, tí a kò bá gba èròkérò láyè lọ́kàn wa, a ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí híhùwà àìṣòótọ́.

BÁ A ṢE LÈ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́

Ká tó lè jẹ́ olóòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo àkókò tó pọ̀ láti ronú lórí bí ‘ìmúra tàbí ìrísí’ wọn ṣe máa dáa sí i, àmọ́ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú lórí bí ìwà wọn ṣe máa dáa sí i. Torí náà, wọ́n máa ń ṣe àwáwí pé ipò tí àwọn wà ló mú káwọn hùwà àìṣòótọ́. Ìwé The (Honest) Truth About Dishonesty sọ pé: “À máa ń ronú pé tá a bá rẹ́ àwọn èèyàn jẹ níwọ̀nba, a ò tíì ṣe ohun tó burú jù.” Ǹjẹ́ ìlànà kankan wa tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà.

Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́. Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ìlànà ìwà rere tí a kò lè rí níbòmíì. (Sáàmù 19:7) Bíbélì tún pèsè ìtọ́sọ́nà tó wúlò lórí àwọn nǹkan bí ìdílé, iṣẹ́, ìwà mímọ́ àti àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó sì ti pẹ́ gan-an tí àwọn ìlànà inú rẹ̀ ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àwọn  òfin àti ìlànà inú Bíbélì wúlò fún onírúurú èèyàn, láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti ìran tí wọ́n ti wá sí. Tá a bá ń ka Bíbélì, tá a ronú lórí ohun tá a kà, tá a sì fi àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, ó máa jẹ́ ká lè kọ́ ara wa láti jẹ́ olóòótọ́.

Àmọ́ yàtọ̀ sí pé ká ní ìmọ̀ Bíbélì, àwọn nǹkan míì wà tá a tún ní láti ṣe ká tó lè jẹ́ olóòótọ́. Ó ṣe tán, inú ayé tí onírúurú ìwà ìbàjẹ́ ti kún ọwọ́ àwọn èèyàn là ń gbé, wọ́n sì fẹ́ sọ wá di bí wọ́n ṣe dà. Ìdí nìyẹn tá a fi ní láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ kó sì tì wá lẹ́yìn. (Fílípì 4:6, 7, 13) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ìgboyà láti ṣe ohun tó tọ́, a ò sì lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.

ÈRÈ TÓ WÀ NÍNÚ JÍJẸ́ OLÓÒÓTỌ́

Hitoshi, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ jàǹfààní torí pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kì í ṣe màdàrú. Ẹni tó mọyì kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ ló ń bá ṣiṣẹ́ báyìí. Hitoshi sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé mo rí iṣẹ́ tó máa jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.”

Àwọn míì náà ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Wo àpẹẹrẹ àwọn tó ti jàǹfààní nínú títẹ̀lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”

 • Ẹ̀rí Ọkàn Tó Mọ́

  “Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] ni mí nígbà tí mo fi iléèwé sílẹ̀, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn olè ṣiṣẹ́. Torí náà, ọ̀nà èrú ni mò ń gbà rí èyí tó pọ̀ jù lọ lára owó tí mò ń ná. Lẹ́yìn tí mo lọ sílé ọkọ, èmi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà * Ọlọ́run kórìíra ìwà àìṣòótọ́, torí náà a pinnu láti yíwà pa dà. Lọ́dún 1990, a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ṣe ìrìbọmi, a sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Òwe 6:16-19.

  “Nígbà kan, ẹrù olè ló kún ilé mi, àmọ́ ní báyìí kò sí ẹrù olè mọ́ nílé wa, èyí sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn sí àwọn ọdún tí mo fi hùwà àìṣòótọ́, ńṣe ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àánú rẹ̀ lórí mi. Ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ tí mo bá fẹ́ lọ sùn lálẹ́ pé Jèhófà ti yọ́nú sí mi báyìí.”—Cheryl, Ireland.

  “Nígbà tí ọ̀gá mi gbọ́ pé mi ò gba rìbá lọ́wọ́ ẹnì kan tó fẹ́ di oníbàárà wa, ó sọ fún mi pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti sọ ẹ́ di ẹni téèyàn lè fọkàn tán! Ìbùkún gidi lo jẹ́ fún iléeṣẹ́ yìí.’ Bí mo ṣe jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo ti jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Jèhófà Ọlọ́run. Ó tún ti jẹ́ kí n lè ran ìdílé mi àtàwọn míì lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́.”—Sonny, Hong Kong.

 • Ìbàlẹ̀ Ọkàn

  “Báǹkì ńlá kan ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá pátápátá ni mo sì ń bá ṣiṣẹ́. Nínú irú iṣẹ́ báyìí, àwọn èèyàn kì í ṣe òótọ́, torí kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀. Ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ ni pé, ‘kò sí ohun tó burú nínú ṣíṣe èrú tí owó bá ṣáà ti máa yọ nídìí ẹ̀, tó sì máa jẹ́ kí ọrọ̀ ajé túbọ̀ gbèrú.’ Àmọ́ torí pé mo jẹ́ olóòótọ́, ọkàn mi balẹ̀. Mo ti pinnu pé mi ò ní jáwọ́ nínú jíjẹ́ olóòótọ́ láìka ohun yòówù kó tìdí ẹ̀ yọ. Àwọn tó gbà mí síṣẹ́ mọ̀ pé mi ò ní parọ́ fún wọn, mi ò sì ní báwọn parọ́.”—Tom, Amẹ́ríkà.

 • Iyì Ara Ẹni

  “Ọ̀gá mi sọ fún mi pé kí n parọ́ nípa àwọn ohun èlò ibi iṣẹ́ wa tó sọnù, àmọ́ mo kọ̀ jálẹ̀. Nígbà tí àṣírí àwọn olè náà tú, àwọn tó gbà mí síṣẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ mi torí pé mo jẹ́ olóòótọ́. Ó gba pé kéèyàn ní ìgboyà kó tó lè jẹ́ olóòótọ́ nínú ayé tí ìwà àìṣòótọ́ kúnnú rẹ̀ yìí. Àmọ́ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn èèyàn máa fọkàn tán wa.”—Kaori, Japan.

Ó ṣàǹfààní gan-an pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, torí pé ó máa jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìbàlẹ̀ ọkàn àti iyì ara ẹni. Ṣé o gbà bẹ́ẹ̀?

^ ìpínrọ̀ 18 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.