Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Ìṣọ́  |  No. 1 2016

 BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Fún Mi Ní Ayọ̀ àti Ìbàlẹ̀ Ọkàn fún Ọdún Kan Péré

Fún Mi Ní Ayọ̀ àti Ìbàlẹ̀ Ọkàn fún Ọdún Kan Péré
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1971

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: FRANCE

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌỌ̀TA, ONÍṢEKÚṢE, MO SÌ Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Abúlé Tellancourt, tó wà ní àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Faransé ni ìdílé wa ń gbé. Ọmọ orílẹ̀-èdè Faransé ni bàbá mi, ìyá mi sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ítálì. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, a kó lọ sí àdúgbò táwọn tálákà pọ̀ sí ní ìlú Róòmù, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Nǹkan ò rọrùn rárá níbẹ̀. Ńṣe làwọn òbí mi tiẹ̀ máa ń jágbe mọ́ ara wọn lórí ọ̀rọ̀ owó.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ìyá mi rọ̀ mí pé kí n lọ wá àwọn ọ̀rẹ́ tí a ó jọ máa jáde, kí n má kàn máa jókòó sílé. Bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jáde nìyẹn. Ìgbà tó yá, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni màá fi lọ tí mi ò sì ní wálé. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan tó ṣe bí aláàánú wá bá mi. Ó fún mi ní oògùn olóró, èmi náà sì lò ó kí n lè dà bí ọkùnrin gidi lójú ara mi. Bí mo ṣe jingíri sínú lílo oògùn olóró àti ìṣekúṣe nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fipá bá mi ṣèṣekúṣe. Ìgbésí ayé kò nítumọ̀ kankan sí mi, ikú gan-an ò jọ mí lójú mọ́. Kò sẹ́ni tó rí tèmi rò. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo gbìyànjú láti pa ara mi. Ńṣe ni mo mu odindi ìgò ọtí wisikí kan tán, mo sì lọ bẹ́ sódò. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni mo fi dákú lọ gbári.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kí n mọyì ẹ̀mí mi, àmọ́ mo ṣì ń hùwà ìpáǹle mo sì ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì. Màá lọ bá àwọn èèyàn pé ká jọ gbéra wa sùn, màá wá rọ wọ́n lóògùn yó, màá sì jí wọn lẹ́rù. Mo tún máa ń bá àwọn ọ̀daràn gbé oògùn olóró kiri orílẹ̀-èdè Ítálì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń kó sọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá. Ńṣe ló dà bíi pé ìgbésí ayé mi ti dojú rú. Síbẹ̀, mo mọ̀ lọ́kàn mi pé ó máa nídìí tí Ọlọ́run fi dá mi. Torí náà, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn fún ọdún kan péré.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Nítorí pé àwọn tó ń gbé oògùn olóró ni mò ń bá ṣiṣẹ́, gbogbo ìgbà lẹ̀mí mi máa ń wà nínú ewu. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24], mo pinnu láti kó lọ sí orílẹ̀-èdè England. Kí n tó lọ, mo lọ wo ìyá mi, ó sì yà mí lẹ́nu láti rí ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Annunziato Lugarà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì fún un. * Ẹ̀rù bà mí torí mo mọ̀ pé ògbólógbòó ọ̀daràn  ni, mo sì bi í pé kí ló wá ṣe. Ó sọ àwọn ìyípadà tó ti ṣe nígbèésí ayé rẹ̀ kó lè di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sì ní kí n ṣèlérí fún òun pé, tí mo bá dé England, màá wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn. Mo gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí mo débẹ̀, ńṣe ni mo pa dà sí irú ìgbésí ayé ti mò ń gbé tẹ́lẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, mo rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní òpópónà London tí èrò pọ̀ sí. Mo rántí ìlérí tí mo ṣe fún Annunziato, mo sì bi Ẹlẹ́rìí náà bóyá ó lè wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì wú mi lórí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ tí 1 Jòhánù 1:9, sọ nípa Ọlọ́run wọ̀ mí lọ́kàn gidigidi, ó sọ pé: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́.” Ẹsẹ Bíbélì yẹn gún mi ní kẹ́sẹ́ torí ó jẹ́ kí n rí i pé ìgbésí ayé tí mò ń gbé kò dáa. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Mo kíyè sí pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni wọ́n ní fún ara wọn ó sì wù mí láti dara pọ̀ mọ́ wọn, torí pé àárín irú àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn bẹ́ẹ̀ ló máa ń wù mí kí n wà.

Kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró àti ìṣekúṣe. Àmọ́, ó nira fún mi láti yí ìṣesí mi pa dà. Mo rí i pé ó yẹ kí n túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, kí n sì máa gba tiwọn rò. Kódà, mo ṣì ń sapá láti fi àwọn ìwà kan tí kò dáa sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́, torí mo ti ṣe ọ̀pọ̀ àtúnṣe. Mo ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1997, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi, mo fẹ́ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara. Kò tíì pẹ́ tí òun náà di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ rí i pé mo ti tún ìgbésí ayé mi ṣe, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tí òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà ẹ̀gbọ́n ìyá ìyá mi tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe ìrìbọmi kó tó kú.

Ní báyìí mo ti di alàgbà nínú ìjọ tí mo wà, èmi àti ìyàwó mi sì jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. À ń kọ́ àwọn tó ń sọ èdè Ítálì nílùú London lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà míì wà tí ọkàn mi máa ń dà rú nítorí irú ìgbésí ayé tí mo ti gbé sẹ́yìn, àmọ́ alátìlẹyìn gidi ni Barbara ìyàwó mi jẹ́ fún mi. Mo ti wá ní irú ìdílé tí mò ń fẹ́, ìyẹn ìdílé tó wà níṣọ̀kan. Mo sì tún ní irú Bàbá tó wù mí, ìyẹn Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi. Ọdún kan péré ni mo sọ fún Ọlọ́run pé kó fi jẹ́ ki ń ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn, ṣùgbọ́n ohun tó fún mi kọjá bẹ́ẹ̀!

Mo ti wá ní irú ìdílé tí mò ń fẹ́, ìyẹn ìdílé tó wà níṣọ̀kan, mo sì tún ní irú Bàbá tó wù mí, ìyẹn Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ mi

^ ìpínrọ̀ 10 Wo àpilẹ̀kọ náà “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—Ìbọn Máa Ń Wà Lára Mi Níbikíbi Tí Mo Bá Lọ,” gẹ́gẹ́ bí Annunziato Lugarà ṣe sọ ọ́, nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2014, ojú ìwé 8 sí 9.