Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  May 2016

Máa Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Tí Jèhófà Ń Pèsè fún Wa Lájẹyó

Máa Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Tí Jèhófà Ń Pèsè fún Wa Lájẹyó

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—AÍSÁ. 48:17.

ORIN: 117, 114

1, 2. (a) Ojú wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo Bíbélì? (b) Ìwé wo lo fẹ́ràn jù nínú Bíbélì?

ÀWA Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn Bíbélì gan-an. Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ máa ń tù wá nínú, ó ń jẹ́ ká nírètí, a sì máa ń rí àwọn ìtọ́ni tó wúlò gan-an nínú rẹ̀. (Róòmù 15:4) A kì í wo Bíbélì bí ìwé kan tó kún fún èrò èèyàn, àmọ́ a gbà á “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹs. 2:13.

2 Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a yàn láàyò. Ìwé Ìhìn Rere làwọn kan fẹ́ràn jù, ìyẹn àwọn ìwé tó jẹ́ ká rí bí Jésù ṣe gbé àwọn ànímọ́ Jèhófà yọ. (Jòh. 14:9) Àwọn Ìwé Bíbélì tó ní àsọtẹ́lẹ̀ nínú làwọn míì kúndùn, irú bí ìwé Ìṣípayá, ìyẹn ìwé tó jẹ́ ká mọ àwọn “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” (Ìṣí. 1:1) Ó sí dájú pé ọ̀pọ̀ wa làwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù ti tù nínú, a sì ti rí àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò gan-an kọ́ nínú ìwé Òwe. Ká sòótọ́, gbogbo èèyàn ni Bíbélì wúlò fún.

3, 4. (a) Ojú wo la fi ń wo àwọn ìtẹ̀jáde wa? (b) Àwọn ìtẹ̀jáde wo ló wà fáwọn kan pàtó tá a tún máa ń rí gbà?

3 Bá a ṣe fẹ́ràn Bíbélì náà la ṣe fẹ́ràn àwọn ìtẹ̀jáde wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a mọyì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà, irú bí àwọn ìwé, àwọn ìwé pẹlẹbẹ, àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìtẹ̀jáde wa míì. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń fún wa yìí ń mú ká wà  lójú fò nípa tẹ̀mí, wọ́n ń jẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, wọ́n sì ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i.—Títù 2:2.

4 Yàtọ̀ sáwọn ìtẹ̀jáde tó wà fún gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a tún máa ń ní àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá a dìídì ṣe fáwọn kan pàtó. Àwọn ọ̀dọ́ la dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde kan fún, àwọn òbí sì làwọn míì wà fún. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò wa tó wà lórí ìkànnì wa la dìídì ṣe fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà lọ́pọ̀ yanturu yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á “se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn.”—Aísá. 25:6.

5. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà mọyì rẹ̀?

5 Ó máa ń wu ọ̀pọ̀ lára wa pé ká túbọ̀ máa ráyè ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa. Ó dá wa lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo bá a ṣe ń sapá láti máa wáyè ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. (Éfé. 5:15, 16) Ká sòótọ́, a lè má ráyè ka gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde wa bá a ṣe fẹ́. Síbẹ̀, nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣọ́ra fún. Kí ni nǹkan ọ̀hún?

6. Èrò wo ló lè mú ká pàdánù àǹfààní tó yẹ ká rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa kan?

6 Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tọ́rọ̀ inú ẹ̀ ò kàn wá, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù àǹfààní tó yẹ ká rí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ò bá ipò wa mu. Tó bá sì jẹ́ pé àwa kọ́ ni wọ́n dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde kan fún ńkọ́? Ṣé a kàn máa ń fojú wo irú ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ gààràgà tàbí ṣe la kàn máa ń tọ́jú ẹ̀ láìkà? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń pàdánù àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó wúlò fún wa gan-an. Ọgbọ́n wo la wá lè dá sí i? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ni Orísun gbogbo àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà. Ó gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” (Aísá. 48:17) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àbá mẹ́tà kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú Bíbélì lódindi àti nínú ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Jèhófà ń fún wa.

ÀWỌN ÀBÁ TÁÁ JẸ́ KÁ TÚBỌ̀ GBÁDÙN BÍBÉLÌ KÍKÀ

7. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Bíbélì bíi pé àwa gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀?

7 Kà á bíi pé ìwọ gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tím. 3:16) Òótọ́ ni pé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹnì kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn kan ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka Ìwé Mímọ́ bíi pé àwa gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́. Arákùnrin kan sọ pé: “Tí mo bá ń ka Bíbélì, mo máa ń fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo lè rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì tí mò ń kà. Èyí sì máa ń jẹ́ kí n ronú lórí ohun tí mò ń kà dáadáa.” Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, á dáa ká kọ́kọ́ bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè kà á bíi pé àwa gan-an ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀, kó sì fún wa ní ọgbọ́n ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó fẹ́ ká kọ́.—Ẹ́sírà 7:10; ka Jákọ́bù 1:5.

Ǹjẹ́ ò ń ka Bíbélì rẹ lọ́nà tó máa gbà yé ọ dáadáa? (Wo ìpínrọ̀ 7)

8, 9. (a) Tá a bá ń ka Bíbélì, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa? (b) Kí làwọn ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

8 Máa bi ara rẹ ní ìbéèrè. Tó o bá ń ka ibì kan nínú Bíbélì, mú sùúrù díẹ̀ kó o sì bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí lohun tí mò ń kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí sílò nígbèésí ayé mi? Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí ran ẹlòmíì lọ́wọ́?’ Ó dájú pé tá a bá ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, àá rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nínú Bíbélì kíkà wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tí Jèhófà ní kí àwọn arákùnrin kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kí wọ́n tó lè di alàgbà. (Ka 1 Tímótì 3:2-7.) Torí pé èyí tó  pọ̀ jù lára wa kì í ṣe alàgbà, a lè ronú pé bóyá làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí kàn wá. Àmọ́ tá a bá ronú lórí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tá a máa jíròrò yìí, àá rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí.

9 Kí lohun tí mò ń kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà? Ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká rí i pé ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kọjá ṣeréṣeré. Tórí wọ́n máa jíhìn fún Jèhófà, Jèhófà retí pé kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere kí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú ìjọ “èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Jèhófà fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn alàgbà tá a fi wé olùṣọ́ àgùntàn á bójú tó wa lọ́nà tó dára. (Aísá. 32:1, 2) Àwọn ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

10, 11. (a) Tá a bá ń ka àwọn ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀, báwo la ṣe lè máa fi ohun tá a kà náà sílò nígbèésí ayé wa? (b) Báwo la ṣe lè fi ran ẹlòmíì lọ́wọ́?

10 Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí sílò nígbèésí ayé mi? Ó yẹ kí alàgbà kọ̀ọ̀kan máa fi àwọn ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ yìí yẹ ara rẹ̀ wò látìgbàdégbà, kó sì máa ronú nípa ọ̀nà tóun lè gbà sunwọ̀n sí i. Arákùnrin tó “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” náà gbọ́dọ̀ máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí torí pé ó yẹ kóun náà máa sapá láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. (1 Tím. 3:1) Kódà, gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí torí pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ni Jèhófà ń retí pé kí gbogbo Kristẹni kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo Kristẹni ló yẹ kó yè kooro ní èrò inú kí wọ́n sì máa fòye báni lò. (Fílí. 4:5; 1 Pét. 4:7) Bí àwọn alàgbà ṣe ń fi “àpẹẹrẹ” tó dáa lélẹ̀ “fún agbo,” àá máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn, àá sì lè máa “fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”—1 Pét. 5:3; Héb. 13:7.

11 Báwo ni mo ṣe lè fi ohun tí mo kà yìí ran ẹlòmíì lọ́wọ́? A lè fi àwọn ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ yìí ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí bí àwọn alàgbà ṣe yàtọ̀ pátápátá sáwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Bákan náà, bá a ṣe ń kà á, àá máa rántí gbogbo ìsapá táwọn alàgbà ìjọ wa ń ṣe nítorí wa. Bá a ṣe ń ronú lórí gbogbo bí wọ́n ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe nítorí wa máa mú ká túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ “fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára”  láàárín wa. (1 Tẹs. 5:12) Bá a ṣe túbọ̀ ń bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí látọkàn wá, ayọ̀ wọn á máa pọ̀ sí i.—Héb. 13:17.

12, 13. (a) Irú àwọn ìwádìí wo la lè fi àwọn ohun èlò ìwádìí tá a ní ṣe? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí bí àwọn ìsọfúnni kan ṣe lè jẹ́ ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ kan tá ò lè tètè rí nínú ẹsẹ Bíbélì tá à ń kà.

12 Ṣe ìwádìí. A lè lo àwọn ohun èlò ìwádìí tí ètò Ọlọ́run ṣe láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Ta ló kọ ibi tí mo kà nínú Ìwé Mímọ́ yìí?

  • Ìgbà wo ni wọ́n kọ ọ́, ibo ni wọ́n sì ti kọ ọ́?

  • Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ló wáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Ìwé Bíbélì yìí?

Àwọn ìsọfúnni yìí máa jẹ́ ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ kan tá ò lè tètè rí.

13 Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Jèhófà sọ nínú Ìsíkíẹ́lì 14:13, 14 pé: “Ní ti ilẹ̀ kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó dá ẹ̀ṣẹ̀ sí mi ní ṣíṣe àìṣòótọ́, èmi yóò na ọwọ́ mi lòdì sí i pẹ̀lú, èmi yóò sì bá a ṣẹ́ àwọn ọ̀pá tí a ń fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí, èmi yóò sì rán ìyàn sí i, èmi yóò sì ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. ‘Ká ní àwọn ọkùnrin mẹ́ta wọ̀nyí wà ní àárín rẹ̀, Nóà, Dáníẹ́lì àti Jóòbù, àwọn alára nítorí òdodo wọn yóò dá ọkàn wọn nídè,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.” Ìwádìí tá a ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan bí ọdún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ apá ibi yìí nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Nóà àti Jóòbù ti kú, síbẹ̀ Ọlọ́run ò gbà gbé bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin. Àmọ́ Dáníẹ́lì ṣì wà láyè nígbà yẹn. Kódà, ó lè má tíì pọ́mọ ogun ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ́mọ ogun ọdún nígbà tí Jèhófà sọ pé ó jẹ́ olódodo bíi ti Nóà àti Jóòbù. Kí la rí kọ́? Jèhófà ń rí bí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́, títí kan àwọn ọmọdé, ó sì mọyì wọn gàn-an.—Sm. 148:12-14.

MÁA KA Ọ̀KAN-KÒ-JỌ̀KAN ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE WA

14. Báwo làwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́ ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́, báwo làwọn míì sì ṣe ń jàǹfààní látinú wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

14 Bó ṣe ṣàǹfààní pé ká máa ka gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì láìdá apá kan sí, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ń ka gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò. Àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ti tẹ ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde fáwọn ọ̀dọ́. [1] Torí àtiran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ kí ìwà burúkú tó kún iléèwé máa bàa ràn wọ́n tàbí kí wọ́n lè yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú bí wọ́n ṣe ń dàgbà la ṣe ṣe àwọn ìwé kan. Àǹfààní wo ni gbogbo wa máa rí tá a bá ń ka àwọn ìtẹ̀jáde yìí? Tá a bá ń kà wọ́n, àwa náà á mọ ohun tójú àwọn ọ̀dọ́ wa ń rí. Ìyẹn á sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ká sì máa fún wọn níṣìírí.

15. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn àgbàlagbà máa ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́?

15 Kì í ṣàwọn ọ̀dọ́ nìkan ló máa ń kojú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro tá a máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde yìí. Gbogbo wa la ní láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa, ká máa kó ara wa níjàánu, ká má jẹ́ káyé sọ wá dà bí wọ́n ṣe dà, ká má kẹ́gbẹ́ búburú ká má sì lọ́wọ́ sáwọn eré ìnàjú tí kò yẹ Kristẹni. Àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì la máa ń jíròrò nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́. Ṣó yẹ káwọn àgbàlagbà máa ronú pé àwọn ti dàgbà ju ẹni tó ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn ọ̀dọ́? Rárá! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ la dìídì ṣe àwọn ìtẹ̀jáde yìí fún, orí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ṣàǹfààní fún tọmọdétàgbà ni gbogbo ẹ̀ dá lé, gbogbo wa sì ni àwọn ìtẹ̀jáde yìí máa ṣe láǹfààní.

16. Kí làwọn ìtẹ̀jáde wa tún máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ṣe?

 16 Yàtọ̀ sí pé àwọn ìtẹ̀jáde yìí máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro, ó tún máa ń mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú wọn, kí wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Ka Oníwàásù 12:1, 13.) Ẹ gbọ́ ná, ṣáwọn ọ̀dọ́ nìkan làwọn ìtẹ̀jáde yìí wúlò fún ni? Rárá! Bí àpẹẹrẹ, Jí! April 2009 ní àpilẹ̀kọ kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Kí Bíbélì Kíkà Gbádùn Mọ́ Mi?” Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn àbá mélòó kan tá a lè fi sílò, ó tiẹ̀ tún ní àpótí kan téèyàn lè gé kó sì fi há Bíbélì rẹ̀ kó lè máa rántí àwọn ohun tó yẹ kó ṣe tó bá ń ka Bíbélì. Ǹjẹ́ a tiẹ̀ rí àwọn àgbàlagbà tí àpilẹ̀kọ yìí ti ṣe láǹfààní? Ìyàwó ilé kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún [24] tó sì ti bímọ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti gbìyànjú láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ àmọ́ pàbó ló ń já sí. Mo lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, àpótí tí mo gé jáde náà sì wúlò fún mi gan-an. Bí Bíbélì kíkà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn mọ́ mi gan-an nìyẹn. Mo rí bí àwọn ìwé Bíbélì ṣe bára mu tí wọ́n sì wọnú ara wọn, àfi bí aṣọ òfì aláràbarà tí wọ́n fara balẹ̀ kóṣẹ́ sí. Mo mà fẹ́ràn Bíbélì kíkà o!”

17, 18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí? Sọ àpẹẹrẹ kan.

17 Àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Látọdún 2008 ni ètò Ọlọ́run ti ń tẹ ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́, èyí tá a dìídì ṣe fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tá a dìídì ṣe fàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Ṣé àwọn ìtẹ̀jáde yìí lè ṣe àwa náà láǹfààní? Àpèjúwe kan rèé. Ká sọ pé lọ́jọ́ kan, kí àsọyé fún gbogbo èèyàn tó bẹ̀rẹ̀, lo bá rí ẹnì kan tó o pè wá sípàdé lórí ìjókòó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó dájú pé inú rẹ̀ á dùn gan-an. Bí alásọyé ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ṣeé ṣe kó o máa ronú nípa ẹni tó o pè wá sípàdé náà. Wàá máa ronú nípa bí àsọyé náà á ṣe máa wọ ẹni náà lọ́kàn táá sì ṣe é láǹfààní. Ìyẹn á mú kí àsọyé náà túbọ̀ wọ ìwọ náà lọ́kàn, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ fẹ́ràn ohun tí àsọyé náà dá lé.

18 Bó ṣe máa ri tá a bá ka àwọn ìtẹ̀jáde tó wà fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń fi sóde máa ń ṣàlàyé Bíbélì lọ́nà tó máa tètè yé àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Bí ọ̀pọ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo náà ṣe rí nìyẹn, irú bí àwọn tó wà nínú apá tá a pé ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ” àti “Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Ń Béèrè.” Tá a bá ń ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí, àwọn òtítọ́ kan tá a ti mọ̀ á túbọ̀ wọ̀ wá lọ́kàn. Yàtọ̀ síyẹn, a tún lè kọ́ àwọn ọ̀nà tuntun tá a lè gbà ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn tá a bá ń wàásù. Bákan náà, ìwé ìròyìn Jí! máa ń mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run tòótọ́ wà, ó sì tún máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣàlàyé àwọn ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn.—Ka 1 Pétérù 3:15.

19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọ rírì oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa?

19 Ó ṣe kedere pé Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ láti bójú tó ‘àìní wa nípa ti ẹ̀mí.’ (Mát. 5:3) Ẹ jẹ́ ká máa jẹ gbogbo oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa yìí lájẹyó. Àá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a mọ rírì ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa, torí pé òun ni Ẹni tí ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní.—Aísá. 48:17.

^ [1] (ìpínrọ̀ 14) Lára irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ ni Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Kejì, àti ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé,” tó máa ń wà lórí ìkànnì wa.