Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Báwo Lo Ṣe Máa Ń Ṣèpinnu?

Báwo Lo Ṣe Máa Ń Ṣèpinnu?

“Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”ÉFÉ. 5:17.

ORIN: 69, 57

1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn òfin tó wà nínú Bíbélì, àǹfààní wo la sì ń rí bá a ṣe ń pa wọ́n mọ́?

NÍNÚ Bíbélì, Jèhófà ti fún wa láwọn òfin pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, ó ka àwọn nǹkan kan léèwọ̀ fún wa, irú bí ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà àti ìmutípara. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Jésù Kristi tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run náà pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:19, 20) Kò sí àní-àní pé àwọn òfin tí Ọlọ́run fún wa àtàwọn àṣẹ tó pa fún wa ń dáàbò bò wá. Torí pé à ń pa àwọn òfin àti àṣẹ Ọlọ́run mọ́, a lẹ́nu ọ̀rọ̀ láwùjọ, a ní ìlera tó dáa, ìdílé wa sì túbọ̀ ń láyọ̀. Èyí tó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì jù ni pé à ń rójú rere Jèhófà, ó sì ń bù kún wa torí pé à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo títí kan àṣẹ tó pa fún wa pé ká máa wàásù.

2, 3. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ni Bíbélì ti sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí ò sí òfin pàtó kan nípa ẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìwé Mímọ́, kò sí òfin pàtó kan tó sọ  irú aṣọ táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa wọ̀. Báwo nìyẹn ṣe fi ọgbọ́n Jèhófà hàn? Yàtọ̀ sí pé àṣà, ìmúra àti bí wọ́n ṣe ń ránṣọ láwọn ibì kan yàtọ̀ sí ti ibòmíì, ọdọọdún ni nǹkan ń yí pa dà níbi gbogbo. Ká ní Bíbélì ti sọ pé irú àwọn aṣọ kan la gbọ́dọ̀ máa wọ̀ ni, ó dájú pé ohun tó bá sọ kò ní bóde mu mọ́ lónìí. Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fún wa láwọn òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran nípa irú iṣẹ́ tí Kristẹni kan lè ṣe, irú ìtọ́jú ìṣègùn tó lè gbà àti irú eré ìnàjú tó lè ṣe. Ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwọn olórí ìdílé ló máa pinnu ohun tó wù wọ́n lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí.

3 Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ohun tó bá ṣáà ti wu wá la lè ṣe tó bá di pé ká ṣèpinnu lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò sí òfin kan pàtó nípa ẹ̀ tàbí tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó lè nípa lórí ìgbésí ayé wa? Ṣé Baba wa ọ̀run á fọwọ́ sí ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe tí ò bá ṣáà ti ta ko òfin èyíkéyìí nínú Bíbélì? Bí kò bá sí òfin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, báwo la ṣe lè ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn?

ṢÓHUN TÓ BÁ ṢÁÀ TI WÙ MÍ NI MO LÈ ṢE?

4, 5. Ipa wo làwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè ní lórí àwa fúnra wa àtàwọn míì?

4 Àwọn kan lè máa ronú pé ohun tó bá ṣáà ti wu àwọn làwọn lè ṣe. Àmọ́, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu táá sì múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ fi àwọn òfin àti ìlànà tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn ká sì tẹ̀ lé wọn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ rójú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ pa òfin rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ mọ́. (Jẹ́n. 9:4; Ìṣe 15:28, 29) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, á ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ìpinnu tó bá ìlànà àti òfin inú Ìwé Mímọ́ mu.

5 A lè ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan tó lè nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Awọn ìpinnu tá à ń ṣe lè ní ipa rere tàbí búburú lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Tá a bá ṣe ìpinnu tó dáa, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á túbọ̀ lágbára, àmọ́ tá a bá ṣe èyí tí kò dára, á ba àjọṣe náà jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìpinnu tí kò dára lè mú àwọn míì kọsẹ̀, ó lè ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì lè ba ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́. Torí náà, àwọn ìpinnu tá a bá ṣe máa nípa lórí àwa fúnra wa àtàwọn míì.—Ka Róòmù 14:19; Gálátíà 6:7.

6. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ ṣèpinnu?

6 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tí kò sì sí òfin kan pàtó nípa ẹ̀ nínú Bíbélì? Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló kù sí láti ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa ká sì ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu táá sì múnú rẹ̀ dùn, kó má jẹ́ pé ohun tó bá kàn ti wù wá la máa ṣe.—Ka Sáàmù 37:5.

FÒYE MỌ OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́

7. Bí kò bá sí òfin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, báwo la ṣe lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́?

7 O lè máa wò ó pé, ‘Báwo la ṣe máa mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ gan-an nígbà tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò fún wa lófin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe?’ Ìwé Éfésù 5:17 sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” Bí kò bá sí òfin pàtó kan nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, báwo la ṣe lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́? A lè ṣe bẹ́ẹ̀, tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà tá a sì gbà kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà.

8. Báwo ni Jésù ṣe mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe fòye mọ ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kó ṣe. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù kọ́kọ́ gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ kó tó pèsè oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu.  (Mát. 14:17-20; 15:34-37) Síbẹ̀, nígbà tébi ń pa á ní aginjù tí Èṣù sì dán an wò pé kó sọ òkúta di búrẹ́dì, ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Mátíù 4:2-4.) Torí pé Jésù mọ èrò Bàbá rẹ̀ dunjú, ó mọ̀ pé kò yẹ kóun sọ òkúta di búrẹ́dì. Ó mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ kóun lo irú agbára bẹ́ẹ̀ láti fi wá oúnjẹ fún ara òun. Bó ṣe kọ̀ láti sọ òkúta di búrẹ́dì yìí fi hàn pé ó gbà kí Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, ó sì nígbàgbọ́ pé ó máa pèsè oúnjẹ fún òun.

9, 10. Kí ló máa mú kó rọrùn fún wa láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Sọ àpèjúwe kan.

9 Táwa náà bá fẹ́ máa ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà. Ó yẹ ká fi ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí sọ́kàn pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ. Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yí padà kúrò nínú ohun búburú.” (Òwe 3:5-7) Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ èrò Jèhófà nípasẹ̀ Bíbélì, á rọrùn fún wa láti fòye mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe tá a bá fẹ́ ṣèpinnu. Lọ́nà yìí, àá túbọ̀ lè máa fòye mọ àwọn ohun tó fẹ́ ká ṣe.—Ìsík. 11:19.

10 Àpèjúwe kan rèé: Ká sọ pé ìyàwó ilé kan lọ sọ́jà. Ó wá rí bàtà kan tó wù ú, àmọ́ bàtà náà wọ́n gan-an. Ó wá ń bi ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni ọkọ mi máa sọ tó bá gbọ́ pé adúrú owó yìí ni mo fi ra bàtà?’ Bí ọkọ ẹ̀ ò tiẹ̀ sí níbẹ̀, kò sí àní-àní pé á ti mọ ohun tí ọkọ ẹ̀ máa sọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, ọjọ́ pẹ́ tóun àti ọkọ ẹ̀ ti ń bára wọn bọ̀, ó sì ti mọ̀ pé ṣe làwọn máa ń ṣọ́wó ná. Torí náà, ó fòye mọ ohun tí ọkọ ẹ̀ máa sọ tó bá ná adúrú owó yẹn sórí bàtà. Lọ́nà kan náà, bá a ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà tá a sì ń mọ àwọn ìlànà rẹ̀, àá túbọ̀ máa fòye mọ ohun tí Baba wa ọ̀run fẹ́ ká ṣe tá a bá fẹ́ ṣèpinnu.

BÁWO LA ṢE LÈ MỌ OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́?

11. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa tá a bá ń ka Bíbélì tàbí tá à ń dá kẹ́kọ̀ọ́? (Wo àpótí náà “ Tó O Bá Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bi Ara Rẹ Pé.”)

11 Ká lè túbọ̀ máa mọ èrò Jèhófà, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìdákẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá ń ka Bíbélì tàbí tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ká máa bi ara wa pé, ‘Kí lohun tí mo kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà, kí ló jẹ́ kí n mọ̀ nípa èrò rẹ̀ àtàwọn ìlànà rẹ̀?’ Ó yẹ ká ní irú èrò tí onísáàmù náà Dáfídì ní, ó kọ ọ́ lórin pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi. Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 25:4, 5) Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì kan tó o kà, o lè bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ibi tí mo kà yìí sílò nínú ìdílé mi? Ibo ni mo ti lè fi í sílò? Ṣé nínú ilé ni àbí níléèwé, níbiiṣẹ́ àbí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?’ Tá a bá ti mọ àwọn ibi tá a ti lè lò ó, á rọrùn fún wa láti lè fòye mọ bá a ṣe máa fi í sílò.

12. Báwo ni ìpàdé àtàwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe lè mú ká mọ èrò Jèhófà nípa àwọn nǹkan?

12 Ọ̀nà míì táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ èrò Jèhófà ni pé ká máa fiyè sí àwọn ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ṣe ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ká lè túbọ̀ mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó gba pé ká ṣèpinnu. A tún máa ń jàǹfààní láwọn ìpàdé wa tá a bá ń tẹ́tí sílẹ̀ tá a sì ń lóhùn sí i. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ohun tá à ń kọ́, àá  túbọ̀ máa fòye mọ èrò Jèhófà, àá sì lè máa ṣe àwọn ohun tó bá èrò rẹ̀ mu. Bá a bá ń lo àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ń fún wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, àá túbọ̀ máa mọ èrò Jèhófà, àá sì lè máa ṣe àwọn ìpinnu táá múnú rẹ̀ dùn táá sì mú kó bù kún wa.

MÁA ṢE ÀWỌN ÌPINNU TÓ BÁ ÈRÒ JÈHÓFÀ MU

13. Sọ apẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí i pé èèyàn lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu téèyàn bá ronú nípa ojú tí Jèhófà á fi wo ọ̀rọ̀ náà.

13 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá mọ èrò Jèhófà, èèyàn á lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ká sọ pé ó wù ẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ kí àwọn ohun ìní díẹ̀ lè tẹ́ ọ lọ́rùn. Àmọ́, o tún bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bóyá ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ á tẹ́ ọ lọ́rùn tí wàá sì lè bójú tó àwọn ohun tó o nílò nípa tara. Lóòótọ́, kò sófin kankan nínú Bíbélì tó sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó ṣe tán èèyàn lè jẹ́ akéde kó sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àmọ́, Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó bá yááfì àwọn nǹkan nítorí Ìjọba Ọlọ́run. (Ka Lúùkù 18:29, 30.) Yàtọ̀ síyẹn, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sí àwọn “ẹbọ ìyìn àtọkànwá” wa, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí ìjọsìn tòótọ́ lè máa tẹ̀ síwájú. (Sm. 119:108, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀; 2 Kọ́r. 9:7) Tó o bá ronú lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ yìí, tó o sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, ǹjẹ́ o ò ní fòye mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Tó o bá ń ronú jinlẹ̀ lọ́nà yìí, wàá lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, Baba wa ọ̀run á sì bù kún rẹ.

14. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá inú Jèhófà á dùn sí irú àwọn aṣọ kan?

14 Jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì: Ká sọ pé o fẹ́ràn láti máa wọ aṣọ kan tó sì ṣeé ṣe kíyẹn máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn kan láàmú nínú ìjọ. Síbẹ̀, o mọ̀ pé kò sófin kankan nínú Bíbélì tó kà á léèwọ̀. Ó dáa, kí lèrò Jèhófà nípa ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀  àwọn iṣẹ́ rere.” (1 Tím. 2:9, 10) Gbogbo Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló yẹ kó máa fi ìlànà yìí sílò, kì í ṣàwọn obìnrin nìkan. Ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a kì í ronú lórí ohun tá a bá ṣáà ti fẹ́ nìkan, a máa ń gba tàwọn míì rò, torí náà, a máa ń ronú lórí ipa tí aṣọ wa àti ìmúra wa máa ní lórí àwọn míì. Tá a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àá máa gba tiwọn rò, a ò sì ní fẹ́ ṣohun tó máa mú wọn kọsẹ̀ tàbí tó tiẹ̀ lè bí wọn nínú pàápàá. (1 Kọ́r. 10:23, 24; Fílí. 3:17) Tá a bá fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ sọ́kàn, àá fòye mọ èrò Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó máa múnú rẹ̀ dùn.

15, 16. Báwo ló ṣe máa rí lára Jèhófà tá a bá ń fọkàn wa ro èròkerò? (b) Báwo la ṣe lè mọ irú eré ìnàjú tí inú Jèhófà dùn sí? (d) Kí ló yẹ ká a ṣe tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó lágbára?

15 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń dun Jèhófà gan-an táwọn èèyàn bá ń hùwà tí kò dára, ó sì máa ń dùn ún tí ‘ìtẹ̀sí èrò ọkàn [wọn bá] jẹ́ búburú ní gbogbo ìgbà.’ (Ka Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6.) Èyí jẹ́ ká rí i pé kò dáa kéèyàn máa fọkàn yàwòrán ìṣekúṣe torí pé ìyẹn lè mú kéèyàn dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, tó jẹ́ ara ẹ̀ṣẹ̀ tí Bíbélì dá lẹ́bi tí kò sì bá èrò Jèhófà mu. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.” (Ják. 3:17) Ó yẹ kí èyí mú ká yẹra fún eré ìnàjú tó lè mú ká máa ro èròkerò tàbí tó lè mú kí ohun tí kò tọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wù wá. Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè bóyá òun lè ka àwọn ìwé kan, wo irú àwọn fíìmú kan tàbí gbá géèmù tó ní àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra nínú. Ó mọ̀ pé Jèhófà kórìíra irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.

16 Tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣèpinnu, ohun tẹ́nì kan ṣe lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, síbẹ̀ kí ìpinnu táwọn méjèèjì ṣe múnú Jèhófà dùn. Àmọ́, tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára, á dáa ká fọ̀rọ̀ lọ àwọn alàgbà tàbí àwọn Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. (Títù 2:3-5; Ják. 5:13-15) Àmọ́ o, kò yẹ ká máa sọ pé káwọn míì ṣèpinnu fún wa. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ kọ́ agbára ìmòye wọn kí wọ́n sì máa lò ó. (Héb. 5:14) Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa rántí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gál. 6:5.

17. Èrè wo la máa rí tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó ń múnú Jèhófà dùn?

17 Tá a bá ń ṣèpinnu tó bá èrò Jèhófà mu, àárín àwa àti Jèhófà á túbọ̀ gún régé. (Ják. 4:8) Àá rójú rere rẹ̀, á sì máa bù kún wa. Èyí á mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Baba wa ọ̀run máa lágbára sí i. Torí náà, ká jẹ́ kí àwọn ìlànà àti òfin tó wà nínú Bíbélì máa darí àwọn ìpinnu tá à ń ṣe, àá tipa bẹ́ẹ̀ máa ṣe ohun tó bá èrò Ọlọ́run mu. Òótọ́ kan ni pé títí láé làá máa róhun tuntun kọ́ nípa Jèhófà. (Jóòbù 26:14) Àmọ́, tá a bá sapá gidigidi nísinsìnyí, àá ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye táá jẹ́ ká máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Òwe 2:1-5) Àwọn èèyàn lè gbà pé ohun kan dáa lónìí, àmọ́ kó dọ̀la kó máa wúlò mọ́. Àmọ́ ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀, onísáàmù náà rán wa létí pé: “Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ète Jèhófà yóò dúró; ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ ń bẹ láti ìran kan tẹ̀ lé ìran mìíràn.” (Sm. 33:11) Ó ṣe kedere nígbà náà pé a lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tá a bá ń jẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ orísun ọgbọ́n, máa darí èrò àti ìṣe wa.