Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  May 2016

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Àwọn Tá A Fa Iṣẹ́ Náà Lé Lọ́wọ́”

“Àwọn Tá A Fa Iṣẹ́ Náà Lé Lọ́wọ́”

ÀPÉJỌ kan wáyé ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́jọ́ Monday, September 1, 1919. Kó tó dọjọ́ yẹn, òjò ti rọ̀ bí ẹni máa kú. Síbẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ló kọ́kọ́ dé síbi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà. Nígbà tó yá, ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn tún dé. Lọ́jọ́ kejì, èrò náà pọ̀ débi pé ìta gbangba ni wọ́n ti ṣe ìyókù àpéjọ náà, abẹ́ igi làwọn èèyàn sì jókòó sí.

Bí àwọn ará yẹn ṣe wà lábẹ́ igi, ìwọ̀nba òòrùn tó tàn sára wọn mú káṣọ wọn dùn ún wò. Afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ wá láti adágún Lake Erie ń fẹ́ yẹtuyẹtu akẹ̀tẹ̀ táwọn obìnrin dé. Arákùnrin kan sọ pé “ibi tá a ti ṣe àpéjọ yìí lẹ́wà gan-an, ó sì tòrò minimini, kò dà bí inú ayé tá a ti wá síbí, àfi bíi pé a ti wà nínú Párádísè.”

Àmọ́, ayọ̀ tó wà lójú wọn ló mú kí ibi àpéjọ náà lẹ́wà jù lọ. Ìwé ìròyìn kan sọ pé “ó jọ pé gbogbo wọn ló ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ojú wọn fani mọ́ra, wọ́n sì lọ́yàyà.” Ohun tó mú àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn láyọ̀ jù ni pé wọ́n wà pẹ̀lú àwọn ará wọn tó kojú onírúurú àdánwò láti ọdún mélòó kan sẹ́yìn, bí àtakò nígbà ogun; ìyapa nínú ìjọ; bí ìjọba ṣe ti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn pa; bí wọ́n ṣe ti àwọn ará kan mọ́lé nítorí iṣẹ́ ìwàásù, títí kan mẹ́jọ lára àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú, tí wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n nǹkan bí ogún ọdún. *

Èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nǹkan sì tojú sú wọn, torí náà wọ́n pa iṣẹ́ ìwàásù tì. Àmọ́, ọ̀pọ̀ fara da gbogbo ìnilára tí wọ́n dojú kọ látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ. Olùṣèwádìí kan sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n kìlọ̀ fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn dúró, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà sọ pé “àwọn ò ní jáwọ́ nínú wíwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run títí òpin máa fi dé.”

Ní gbogbo àkókò àdánwò yìí, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ kò yé “wọ̀nà fún ibi tí Olúwa máa darí wọn sí, . . . wọ́n ń gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Baba tọ́ àwọn sọ́nà.” Ní báyìí, inú wọn dùn pé àwọn tún wà pa pọ̀ ní àpéjọ tí wọ́n ṣe ní Cedar Point. Arábìnrin kan sọ bó ṣe rí lára ọ̀pọ̀ pé àwọn ò mọ “báwọn ṣe máa tún pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara wàásù lẹ́ẹ̀kan sí i.” Àmọ́, ara gbogbo wọn ti wà lọ́nà láti tún pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

 “GA”—IRINṢẸ́ TUNTUN KAN!

Látìgbà tí àpéjọ náà ti bẹ̀rẹ̀ làwọn èèyàn ti ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí ọ̀rọ̀ náà “GA” túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ náà wà lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ, káàdì ìkíni káàbọ̀, àti ara àwọn pátákó ìsọfúnni tó wà káàkiri. Nígbà tó di ọjọ́ Friday, tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ “Co-Laborers’ Day,” Arákùnrin Joseph F. Rutherford sọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà fáwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] tó wà níbẹ. “GA” dúró fún The Golden Age, ìyẹn ìwé ìròyìn tuntun tí wọ́n á máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. *

Nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, ó sọ pé: “Nítorí ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n ní, láìka àkókò wàhálà tí wọ́n là kọjá sí, wọ́n fi ojú ìgbàgbọ́ rí Àkókò Ológo tí ìṣàkóso Mèsáyà máa mú wá. . . . Wọ́n kà á sí ojúṣe àti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn pàtàkì tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láti kéde Àkókò Ológo tó ń bọ̀ fáráyé gbọ́. Ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ ni.”

A máa lo ìwé ìròyìn The Golden Age, “tó jẹ́ Ìwé Ìròyìn Tó Ń Gbé Ìròyìn Òtítọ́, Ìrètí, àti Ìgbàgbọ́ Tó Dáni Lójú jáde,” láti máa wàásù òtítọ́ fáwọn èèyàn. Àá máa sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n san àsansílẹ̀ owó kí wọ́n lè máa rí ìwé ìròyìn náà gbà. Nígbà tí wọ́n béèrè pé àwọn wo ló máa fẹ́ lọ́wọ́ sí iṣẹ́ yìí, gbogbo àwọn tó pé jọ ló dìde dúró. Arákùnrin J. M. Norris sọ pé lẹ́yìn náà “wọ́n wá fi ayọ̀ àti ìtara” kọ orin “Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde, Olúwa,” kìkì àwọn tó ń tọ Jésù lẹ́yìn nìkan ló máa ń ní irú ayọ̀ tí wọ́n fi kọrin yẹn.” “Ohùn àwọn èèyàn náà lọ sókè débi tó fi dà bíi pé àwọn igi náà ń mì tìtì.”

Lẹ́yìn ìpàdé, ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn èèyàn fi wà lórí ìlà kí wọ́n lè forúkọ sílẹ̀ láti san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn lọ̀rọ̀ wọn jọ ti Mabel Philbrick, tó sọ pé: “Inú wa dùn gan-an láti mọ̀ pé a ti tún pa dà ní iṣẹ́ láti ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i!”

“ÀWỌN TÁ A FA IṢẸ́ NÁÀ LÉ LỌ́WỌ́”

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló gbára dì fún iṣẹ́ ìwàásù. Ìwé ìléwọ́ náà Organization Method àti ìwé pẹlẹbẹ To Whom the Work Is Entrusted ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà, ó ní: Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ní oríléeṣẹ́ ló máa darí iṣẹ́ náà. A máa dá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn sílẹ̀ nínú ìjọ àti olùdarí kan. A máa pín ìpínlẹ̀ ìwàásù, ọ̀kọ̀ọ̀kàn sì máa ní ilé àádọ́jọ [150] sí igba [200] nínú. A ó máa ṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Thursday, kí àwọn ará lè sọ ìrírí tí wọ́n ní, kí wọ́n sì fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀.

Arákùnrin Herman Philbrick sọ pé: “Ṣe la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí ní pẹrẹu nígbà tá a pa dà sílé.” Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń tẹ́tí sáwọn ará yìí. Arábìnrin Beulah Covey sọ pé “ìbànújẹ́ tó gba àwọn èèyàn lọ́kàn lẹ́yìn ogun yẹn mú kí wọ́n fẹ́ gbọ́ nípa ìgbà tí ò ní sí wàhálà mọ́ tí gbogbo ìṣòro sì máa dópin,” ìyẹn àkókò ológo náà. Arthur Claus kọ̀wé pé: “Ẹnu ya gbogbo àwọn ará ìjọ nígbà tí wọ́n rí bí iye àwọn tó gbà láti máa san àsansílẹ̀ owó náà ṣe pọ̀ tó.” Láàárín oṣù méjì tí wọ́n tẹ ẹ̀dà àkọ́kọ́ jáde, nǹkan bí ìlàjì mílíọ̀nù ìwé ìròyìn The Golden Age la ti fi sóde, àwọn tó sì forúkọ sílẹ̀ fún àsansílẹ̀ owó tó ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000].

Arákùnrin A. H. Macmillan sọ pé àpilẹ̀kọ náà “Gospel of the Kingdom,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 1920, ni àpilẹ̀kọ “tó kọ́kọ́ rọ gbogbo àwọn ará jákèjádò ayé pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” Àpilẹ̀kọ náà rọ gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n “jẹ́rìí fáráyé pé ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” Lóde òní, àwọn arákùnrin Kristi “tá a gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́” ń dúró de àkókò ológo tí Mèsáyà máa mú wá. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà kárí ayé sì ń tì wọ́n lẹ́yìn.

^ ìpínrọ̀ 5 Wo àpilẹ̀kọ yìí “A Time of Testing (1914-1918)” nínú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, orí 6.

^ ìpínrọ̀ 9 Wọ́n yí orúkọ ìwé ìròyìn The Golden Age pa dà sí Consolation lọ́dún 1937. Àmọ́ látọdún 1946 la ti ń pè é ní Jí!