Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

ILÉ ÌṢỌ́ (Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́) May 2016

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti June 27 sí July 31, 2016 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Ẹ Máa Fìfẹ́ Yanjú Aáwọ̀

Tó o bá fẹ́ lọ ba ẹnì kan tó ṣẹ̀ ọ́, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Ṣé o fẹ́ lọ fẹ̀bi ẹ̀ hàn án ni àbí o fẹ́ lọ wá àlàáfíà?

“Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”

Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́rin kan jẹ́ ká mọ àwọn tó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ lónìí.

Báwo Lo Ṣe Máa Ń Ṣèpinnu?

Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu kan àmọ́ tí ò sí òfin pàtó kan nínú Bíbélì nípa rẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

Ǹjẹ́ Bíbélì Ṣì Ń Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Pa Dà?

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi tẹ́tẹ́ títa sílẹ̀, ó jáwọ́ nínú sìgá mímu àti lílo ogun olóró kó lè tóótun láti ṣèrìbọmi. Àmọ́ lẹ́yìn ìrìbọmi, ó wá rí i pé ó ṣòro gan-an fún òun láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan.

Máa Jẹ Oúnjẹ Tẹ̀mí Tí Jèhófà Ń Pèsè fún Wa Lájẹyó

Èrò wo ló lè mú ká pàdánù àwọn oúnjẹ tẹ̀mí kan?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Àwọn Tá A Fa Iṣẹ́ Náà Lé Lọ́wọ́”

Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919 jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan tó máa kárí ayé.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni Kristẹni kan ṣe máa mọ̀ bóyá ó tọ́ kí òun fún òṣìṣẹ́ ìjọba kan ní owó tàbí ẹ̀bùn? Báwo ni àwọn ará nínú ìjọ ṣe lè fi ayọ̀ wọn hàn nígbà tí wọ́n bá ṣèfilọ̀ pé a ti gba ẹnì kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ pa dà? Kí ló máa ń mú kí adágún omi Bẹtisátà “dà rú”?