Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Wá bó o ṣe lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ lọ́wọ́, wò ó bóyá o lè tù wọ́n nínú tàbí kó o lo Bíbélì láti fún wọn níṣìírí

Ṣé O Lè Ran Ìjọ Rẹ Lọ́wọ́?

Ṣé O Lè Ran Ìjọ Rẹ Lọ́wọ́?

KÍ JÉSÙ tó pa dà sọ́run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Báwo ni wọ́n ṣe máa wàásù dé ibi gbogbo láyé?

Ọ̀jọ̀gbọ́n Martin Goodman ti ilé ẹ̀kọ́ gíga Oxford University sọ pé “nígbà tí ilẹ̀ ọba Róòmù ṣì wà lójú ọpọ́n, ọwọ́ pàtàkì táwọn Kristẹni fi mú iṣẹ́ ìwàásù ló mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹlẹ́sìn yòókù, tó fi mọ́ àwọn Júù.” Jésù wàásù láti ìlú kan sí ìlú míì. Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, káwọn náà máa wàásù “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” níbi gbogbo. Wọ́n ní láti wá àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ rí. (Lúùkù 4:43) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn kan wà tí wọ́n mọ̀ sí “àpọ́sítélì,” èyí tó túmọ̀ sí àwọn tí a rán jáde lọ ṣe nǹkan kan. (Máàkù 3:14) Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:18-20.

Àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí Jésù yàn ò sì láyé mọ́ báyìí, àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tí ètò Ọlọ́run gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n lọ wàásù níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, kíá ni wọ́n sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi”! (Aísáyà 6:8) Àwọn kan, irú bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ti ṣí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré. Àwọn míì ṣí lọ sí apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè wọn. Ọ̀pọ̀ sì ti kọ́ èdè míì kí wọ́n lè ran ìjọ tàbí àwùjọ tó ń sọ èdè náà lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun táà ń sọ yìí kì í fìgbà gbogbo rọrùn, àwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn pẹ̀lú. Torí náà, wọ́n  ti ronú nípa ẹ̀ dáadáa, wọ́n sì lo àkókò wọn, okun wọn àti owó wọn láti lọ wàásù níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. (Lúùkù 14:28-30) Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ń ṣe.

Kì í ṣe gbogbo wa la lè ṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí ká kọ́ èdè míì. Àmọ́ gbogbo wa lè ṣe bíi míṣọ́nnárì nínú ìjọ wa.

ÌWỌ NÁÀ LÈ DÀ BÍI MÍṢỌ́NNÁRÌ NÍNÚ ÌJỌ RẸ

Ran àwọn ará lọ́wọ́

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni fìtara wàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára wọn ò ṣí lọ sílùú míì, wọn kì í sì í ṣe míṣọ́nnárì. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tímótì 4:5) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí lóòótọ́, àmọ́ wọ́n ṣì wúlò fún wa títí dòní. Gbogbo àwa Kristẹni la gbọ́dọ̀ pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ká sì sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà la sì lè gbà dà bíi míṣọ́nnárì kódà nínú ìjọ tá a wà.

Bí àpẹẹrẹ, táwọn míṣọ́nnárì bá ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì, ipò nǹkan máa ń yàtọ̀ sí bó ṣe rí lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ní láti ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ kí orílẹ̀-èdè tuntun náà lè bá wọn lára mu. Bá ò bá tiẹ̀ lè ṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, ǹjẹ́ a lè wá àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà wàásù fáwọn èèyàn? Bí àpẹẹrẹ, ọdún 1940 ni ètò Ọlọ́run kọ́kọ́ rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa ṣe ìjẹ́rìí òpópónà lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ṣé o ti gbìyànjú ìjẹ́rìí òpópónà rí? Ǹjẹ́ o ti fi àwọn àtẹ tó ṣeé tì kiri wàásù rí? Ká kúkú sọ pé, Ǹjẹ́ o ṣe tán láti gbìyànjú àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

Fún wọn níṣìírí láti “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere”

Tó o bá lẹ́mìí tó dáa, wàá máa fìtara wàásù. Àwọn tó ń lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí àwọn tó ń kọ́ èdè tuntun sábà máa ń jẹ́ àwọn akéde tó kúnjú ìwọ̀n, irú wọn sì máa wúlò gan-an nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń múpò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bọ́rọ̀ àwọn míṣọ́nnárì náà sì ṣe rí nìyẹn, àwọn ló sábà máa ń múpò iwájú nínú ìjọ tí wọ́n bá lọ títí táwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ yẹn á fi tóótun láti máa bójú tó àwọn ìṣètò ìjọ. Tó o bá jẹ́ ọkùnrin, tó o sì ti ṣèrìbọmi, ǹjẹ́ ò “ń nàgà,” ìyẹn ni pé, ṣé o ṣe tán láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kó o lè máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìjọ lọ́wọ́?—1 Tímótì 3:1.

 JẸ́ “ÀRÀNṢE AFÚNNILÓKUN”

Ṣe ohun kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́

Àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà ran ìjọ wa lọ́wọ́. Gbogbo wa lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà la lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fáwọn ará wa tó nílò ìrànlọ́wọ́.—Kólósè 4:11.

Tá a bá fẹ́ ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́, àfi ká sún mọ́ wọn ká lè mọ̀ wọ́n dáadáa. Bíbélì gbà wá níyànjú pé tá a bá pàdé pọ̀ ká máa “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì,” tàbí lédè míì, ká máa ronú nípa ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nílò. (Hébérù 10:24) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé ká máa wá fìn-ín ìdí kókò nípa ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dáadáa ká sì máa fòye mọ ohun tí wọ́n nílò. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n nílò kẹ́nì kan ṣe ohun kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kẹ́nì kan tù wọ́n nínú tàbí kẹ̀, kó lo Bíbélì láti fún wọn níṣìírí. Òótọ́ ni pé ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nìkan ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gálátíà 6:1) Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, gbogbo wa la lè ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti dàgbà tàbí àwọn ìdílé tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́.

Sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tó wà nínú ìṣòro

Arákùnrin Salvatore rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Nǹkan dẹnu kọlẹ̀ fún un débi pé ó ní láti ta ilé iṣẹ́ rẹ̀, ilé rẹ̀ àtàwọn ohun ìní míì tó jẹ́ ti ìdílé rẹ̀. Ojú ẹ̀ rí tó kó tó lè máa bọ́ ìdílé rẹ̀. Ìdílé kan nínú ìjọ kíyè sí i pé ìdílé Arákùnrin Salvatore nílò ìrànlọ́wọ́. Wọ́n fún wọn lówó, wọ́n sì tún bá òun àti ìyàwó ẹ̀ wáṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lọ kí wọn nílé kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí. Ìdílé méjèèjì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ní báyìí, ìdílé méjèèjì ò jẹ́ gbàgbé bí wọ́n ṣe jọ máa ń wà pa pọ̀ ní gbogbo ìgbà tí nǹkan le koko yẹn.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í tijú láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká sì jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ àwọn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe. Yálà a lè ṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí a ò lè lọ, gbogbo wa la lè sa ipá wa ká lè máa ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ wa. (Gálátíà 6:10) Tá a bá ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, àá máa láyọ̀, àá sì máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.”—Kólósè 1:10; Ìṣe 20:35.