“Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 6:1.

ORIN: 75, 74

1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ, kí ló ní kí àwọn míì wá bá òun ṣe?

JÈHÓFÀ ni Ẹni Gíga Jù Lọ. Òun ló dá ohun gbogbo, ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ ò sì láàlà. Lẹ́yìn tí Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù lóye òtítọ́ yìí, Jóòbù sọ fún Jèhófà pé: ‘Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo, kò sì sí èrò-ọkàn kankan tí ó jẹ́ aláìṣeélébá fún ọ.’ (Jóòbù 42:2) Jèhófà lè ṣe ohunkóhun tó bá pinnu láti ṣe láì tiẹ̀ pe ẹnikẹ́ni sí i. Àmọ́ torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó pe àwọn míì kí wọ́n wá bá òun ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ìpinnu òun ṣẹ.

2. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jèhófà ní kí Jésù bá òun ṣe?

2 Kí Jèhófà tó dá ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì ló ti dá Jésù, Ọmọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn ló wá fún Ọmọ rẹ̀ yìí láǹfààní láti dá gbogbo ohun tó kù. (Jòhánù 1:1-3, 18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní  ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí, yálà wọn ì báà ṣe ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí ọlá àṣẹ. Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un.” (Kólósè 1:15-17) Torí náà, kì í ṣe pé Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ yìí níṣẹ́ pàtàkì láti ṣe nìkan ni, ó tún jẹ́ káwọn míì mọ iṣẹ́ pàtàkì tó gbé lé e lọ́wọ́. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o!

3. Kí ni Jèhófà ní kí Ádámù ṣe, kí sì nìdí?

3 Jèhófà tún fún àwọn èèyàn láǹfààní láti bá òun ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó fún Ádámù láǹfààní láti sọ àwọn ẹranko lórúkọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:19, 20) Fojú inú wo bí inú Ádámù á ṣe dùn tó bó ti ń ṣe iṣẹ́ yìí. Ó fara balẹ̀ wo ìrísí àti ìṣesí àwọn ẹranko náà kó tó sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lórúkọ. Jèhófà ló kúkú dá gbogbo àwọn ẹranko, tó bá sì wù ú, ó lè fúnra rẹ̀ sọ wọ́n lórúkọ. Àmọ́, ó jẹ́ kí Ádámù rí bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó, ó fún un láǹfààní láti sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Ọlọ́run tún gbé iṣẹ́ pàtàkì míì lé Ádámù lọ́wọ́, ó ní kó sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ádámù kọ̀ láti máa bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́, ìyẹn ló sì fa wàhálà ńlá bá òun àti gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19, 23.

4. Báwo làwọn míì ṣe bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?

4 Nígbà tó yá, Ọlọ́run fún àwọn míì láǹfààní láti bá òun ṣiṣẹ́. Nóà kan ọkọ̀ áàkì tó gba òun àti ìdílé rẹ̀ là nígbà Ìkún-omi. Mósè dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì. Jóṣúà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Sólómọ́nì kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Màríà di ìyá Jésù. Gbogbo àwọn olóòótọ́ èèyàn yìí àti ọ̀pọ̀ àwọn míì bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

5. (a) Iṣẹ́ wo la láǹfààní láti bá Jèhófà ṣe? (b) Ṣé Jèhófà ò lè dá ṣe iṣẹ́ yìí ni? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Lónìí, Jèhófà ní ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ti Ìjọba òun lẹ́yìn. Oríṣiríṣi ọ̀nà la sì lè gbà sin Ọlọ́run. Bí ọ̀pọ̀ wa ò bá tiẹ̀ ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, gbogbo wa la lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Jèhófà kúkú lè dá ṣe iṣẹ́ yìí fúnra rẹ̀. Tó bá wù ú, ó lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀run ní tààràtà kí wọ́n sì máa gbóhùn rẹ̀. Jésù sọ pé Jèhófà tiẹ̀ lè mú kí àwọn òkúta máa sọ fáwọn èèyàn nípa Ọba Ìjọba Rẹ̀. (Lúùkù 19:37-40) Àmọ́, Jèhófà fún wa láǹfààní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 6:1) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé à ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tó ń mú kí èyí máa fún wa láyọ̀.

BÍBÁ ỌLỌ́RUN ṢIṢẸ́ Ń FÚN WA LÁYỌ̀

6. Báwo ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe bí inú rẹ̀ ṣe dùn tó torí ó ń ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀?

6 Kò sígbà tínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í dùn bí wọ́n ṣe ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́. Kí àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run tó wá sáyé, ó sọ pé: ‘Jèhófà ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀, mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.’ (Òwe 8:22, 30) Nígbà tí Jésù bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀, inú rẹ̀ dùn torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe láṣeyọrí, ó sì mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Àwa náà ńkọ́?

Kí ló tún lè fúnni láyọ̀ ju kéèyàn kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù fi ń fún wa láyọ̀?

 7 Jésù sọ pé a máa láyọ̀ nígbà tá a bá fúnni àti nígbà tá a bá rí gbà. (Ìṣe 20:35) Inú wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ kí nìdí tínú wa tún fi ń dùn bá a ṣe ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ìdí ni pé à ń rí i bínú wọn ṣe ń dùn bí wọ́n bá jàjà lóye ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Inú wa ń dùn bá a ṣe ń rí wọn tí wọ́n ń yí èrò wọn pa dà tí wọ́n sì ń tún ìgbésí ayé wọn ṣe. Iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, òun sì ni iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ jù lọ. Iṣẹ́ yìí ló máa mú kí àwọn tó bá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní ìyè àìnípẹ̀kun.—2 Kọ́ríńtì 5:20.

8. Kí làwọn kan sọ nípa béèyàn ṣe máa ń láyọ̀ tó bá ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́?

8 Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá mọ Ọlọ́run, a mọ̀ pé ńṣe là ń múnú Jèhófà dùn àti pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Èyí tún ń fi kún ayọ̀ wa. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Arákùnrin Marco tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ pé: “Mo láyọ̀ gan-an pé Jèhófà ni mò ń lo gbogbo okun mi fún kì í ṣe fún èèyàn kan tí ò ní pẹ́ rárá tó fi máa gbàgbé gbogbo iṣẹ́ tí mo ṣe.” Arákùnrin Franco tóun náà ń sìn lórílẹ̀-èdè Ítálì sọ ohun tó jọ èyí, ó ní: “Jèhófà ń rán wa létí lójoojúmọ́ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tó fún wa pé òun nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe fún òun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tá à ń ṣe yìí lè má fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú tiwa. Ìdí nìyí tí bí mo ṣe ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ fi ń múnú mi dùn gan-an, tó sì tún ń jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.”

BÍBÁ ỌLỌ́RUN ṢIṢẸ́ Ń MÚ KÁ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ ÀTÀWỌN ARÁ WA

9. Àjọṣe wo ló wà láàárín Jèhófà àti Jésù, kí sì nìdí?

9 Bá a ṣe ń bá àwọn tá a nífẹ̀ẹ́ ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa mọ̀ wọ́n sí i. Àá túbọ̀ mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àtàwọn ànímọ́ rere tí  wọ́n ní. Àá mọ àwọn ohun tí wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn àtàwọn ohun tí wọ́n ṣe kọ́wọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́. Àfàìmọ̀ kí Jésù má ti bá Jèhófà ṣiṣẹ́ fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún. Èyí sì mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn lágbára débi pé kò sóhun tó lè da àárín wọn rú. Jésù jẹ́ ká rí bí àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà ṣe lágbára tó nígbà tó sọ pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” (Jòhánù 10:30) Àwọn méjèèjì mọwọ́ ara wọn gan-an, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan.

Iṣẹ́ ìwàásù ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, ó sì ń jẹ́ ká máa rántí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa àtàwọn ìlànà tó fìfẹ́ fún wa

10. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù fi ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará?

10 Jésù bẹ Jèhófà pé kó máa dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Kí nìdí? Jésù sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́.” (Jòhánù 17:11) Bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, tá a sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ la óò túbọ̀ máa mọ àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Jèhófà ní. Àá máa rí ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká gbẹ́kẹ̀ lé e ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó ń fún wa. Bá a sì ṣe ń sún mọ́ Ọlọ́run lòun náà á máa sún mọ́ wa. (Ka Jákọ́bù 4:8.) Bákan náà, àá túbọ̀ sún mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa torí pé ìṣòro kan náà ni gbogbo wa ń dojú kọ, ohun kan náà ló ń fún gbogbo wa láyọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun sì ni gbogbo wa ń lé. A jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, à ń bára wa yọ̀, a sì jọ ń fara dà á nìṣó. Arábìnrin Octavia tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ ti mú kí n túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará.” Ó ṣàlàyé pé kò sóhun tó fà á ju pé àfojúsùn kan náà lòun àtàwọn ará tóun yàn lọ́rẹ̀ẹ́ ní, ìlànà kan náà làwọn sì jọ ń tẹ̀ lé. Ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára gbogbo wa náà nìyẹn. Bá a ṣe ń rí gbogbo ìsapá táwọn ará wa ń ṣe torí kí wọ́n lè múnú Jèhófà dùn, ṣe nìyẹn máa ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ wọn.

11. Kí nìdí tá a fi máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará wa nínú ayé tuntun ju ti ìsinsìnyí lọ?

11 Ìfẹ́ tó lágbára gan-an la ní sí Jèhófà àtàwọn ará wa nísinsìnyí, àmọ́ ìfẹ́ yẹn tún máa wá lágbára sí i tá a bá dénú ayé tuntun. Ìwọ tiẹ̀ ronú nípa gbogbo iṣẹ́ aláyọ̀ tá a máa ṣe nínú ayé tuntun! A máa kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀, a sì máa kọ́ wọn nípa Jèhófà. A tún máa sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. Kò sí àní-àní pé ayọ̀ ọ̀hún á pọ̀ nígbà tí Kristi bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ ayé, tí gbogbo wa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, tá a sì ń di pípé. Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, aráyé máa wà níṣọ̀kan, gbogbo wọ́n á sún mọ́ Jèhófà, ẹni tó máa “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn” dájúdájú.—Sáàmù 145:16.

BÍBÁ ỌLỌ́RUN ṢIṢẸ́ Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ

12. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń dáàbò bò wá?

12 Ó ṣe pàtàkì ká dáàbò bo àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Torí pé ayé tí Sátánì ń darí là ń gbé àti pé àwa fúnra wa ṣì jẹ́ aláìpé, ó rọrùn kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ronú báyé ṣe ń ronú kéèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà bí wọ́n ṣe ń hùwà. Ńṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà téèyàn  ń lúwẹ̀ẹ́ nínú odò àmọ́ tí omi ọ̀hún ń gbìyànjú láti gbé wa lọ síbi tá ò fẹ́ lúwẹ̀ẹ́ gbà. Àfi ká yáa fi gbogbo agbára wa lúwẹ̀ẹ́ gba ibi tá a fẹ́ gbà kí omi má bàá gbé wa lọ. Lọ́nà kan náà, àfi ká yáa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe káyé Sátánì má bàá sọ wá dà bó ṣe dà. Báwo wá ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń dáàbò bò wá? Bá a ṣe ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làwa náà á máa pọkàn pọ̀ sorí àwọn ohun tó dára tó sì ṣe pàtàkì, a ò sì ní máa gbọ́kàn wa sórí àwọn ohun tó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́. (Fílípì 4:8) Iṣẹ́ ìwàásù máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i torí ó máa ń rán wa létí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wa àtàwọn ìlànà tó fìfẹ́ fún wa. Ó tún máa ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tá a lè fi dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ Sátánì àti ayé tó ń darí, ká sì máa fi wọ́n ṣèwà hù nígbà gbogbo.—Ka Éfésù 6:14-17.

Tá a bá ń jẹ́ kọ́wọ́ wá dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a ò ní ráyè máa ronú nípa àwọn ìṣòro wa ṣáá

13. Kí ni arákùnrin kan tó ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù?

13 Tá a bá jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, táà ń fi àkókò tó pọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣe àwọn ohun táá ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́, ààbò lèyí máa jẹ́ fún wa torí kò ní jẹ́ ká ráyè tá ó fi máa ronú nípa àwọn ìṣòro wa ṣáá débi táwọn ìṣòro yẹn á fi gbà wá lọ́kàn. Arákùnrin Joel tó ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kí n túbọ̀ wà lójúfò. Ó ń jẹ́ kí n mọ onírúurú ìṣòro tó ń bá àwọn èèyàn fínra, ó sì ń jẹ́ kí n máa rántí àwọn àǹfààní tí mo ti rí bí mo ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé mi. Iṣẹ́ ìwàásù ń mú kí n túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó ti jẹ́ kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí n sì fọkàn tán àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi.”

14. Kí ni bá ò ṣe jáwọ́ wíwàásù fi hàn?

14 Iṣẹ́ ìwàásù tún máa ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé iṣẹ́ rẹ ni láti máa fún àwọn èèyàn tó wà ládùúgbò rẹ lóúnjẹ. Iṣẹ́ ọ̀hún ò sì yọwó, kódà àpò ara ẹ lo ti ń mú owó tó o fi ń wọ mọ́tò dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí oúnjẹ náà, bó o ṣe ń gbé oúnjẹ ọ̀hún wá tiẹ̀ ń bí àwọn kan nínú pàápàá. Ọjọ́ mélòó lo máa ṣèyẹn dà? Ó dájú pé kò ní pẹ́ sú ẹ, ó sì ṣeé ṣe kó o fi iṣẹ́ ọ̀hún sílẹ̀. Iṣẹ́ ìwàásù ń ná wa lówó, ó sì tún ń ná wa lákòókò, àwọn kan tiẹ̀ ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, inú sì ń bí àwọn kan torí pé à ń wàásù. Síbẹ̀ náà, a ò yé wàásù! Ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro nìyẹn pé Jèhófà ń fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́.

BÍBÁ ỌLỌ́RUN ṢIṢẸ́ Ń FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN ÀTÀWỌN ÈÈYÀN

15. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ṣe ń mú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáráyé ṣẹ?

15 Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ṣe ń mú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fáráyé ṣẹ? Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwa èèyàn wà láàyè títí láé, ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ò sì yí èyí pa dà. (Aísáyà 55:11) Ọlọ́run ṣe ohun táá mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kí ló ṣe? Ó rán Jésù wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.  Àmọ́ káwọn èèyàn tó lè jàǹfààní látinú ẹbọ tí Jésù fẹ̀mí rẹ̀ rú yìí, àfi kí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jésù kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí àwọn náà máa kọ́ àwọn èèyàn. Bá a ṣe ń wàásù tá a sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ńṣe là ń bá Ọlọ́run ìfẹ́ ṣiṣẹ́ bó ṣe ń gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

16. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń mú ká pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́?

16 Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. “Ìfẹ́ rẹ̀ [ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Nígbà tí Farisí kan béèrè lọ́wọ́ Jésù pé èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin Ọlọ́run, Jésù dá a lóhùn pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” (Mátíù 22:37-39) À ń pa àṣẹ yìí mọ́ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere.—Ka Ìṣe 10:42.

17. Ojú wo lo fi ń wo àǹfààní tó o ní láti máa wàásù ìhìn rere?

17 Àǹfààní ńlá gbáà la ní! Jèhófà ti fún wa ní iṣẹ́ tó ń jẹ́ ká máa láyọ̀, iṣẹ́ tó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn ká sì túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa, iṣẹ́ tó tún ń dáàbò bo àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú rẹ̀. Iṣẹ́ yìí ló tún ń jẹ́ ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Jèhófà ní àwọn èèyàn tó pọ̀ káàkiri ayé, ipò gbogbo wọn sì yàtọ̀ síra. Àmọ́ yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, yálà a rí já jẹ tàbí a ò rí já jẹ, yálà ara wa le tàbí ara wa ò fi bẹ́ẹ̀ le, gbogbo wa ń ṣe ohun tá a lè ṣe ká lè máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Ṣe ni inú wa ń dùn bíi ti Arákùnrin Chantel tó wá láti ilẹ̀ Faransé, arákùnrin yìí sọ pé: “Ẹni tó lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, Ọlọ́run aláyọ̀, sọ fún mi pé: ‘Lọ! Sọ fún wọn, bá mi sọ fún wọn, sọ̀rọ̀ látọkàn rẹ wá. Mo ti fún ẹ lókun, mo ti fún ẹ ní Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ mi, àwọn áńgẹ́lì àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà láyé náà tún wà ńbẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, màá tún máa dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́, màá sì máa fún ẹ láwọn ìtọ́ni tó ṣe kedere lásìkò tó tọ́.’ Inú mi dùn gan-an pé mò ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, mo sì láǹfààní láti máa bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́!”