“Kí Jèhófà fúnra rẹ̀ wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín ọmọ mi àti ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—1 SÁMÚẸ́LÌ 20:42.

ORIN: 125, 62

1, 2. Kí ló mú kí àjọṣe tó wà láàárín Dáfídì àti Jónátánì jẹ́ àpẹẹrẹ ìdúróṣinṣin téèyàn lè tẹ̀ lé?

Ó DÁJÚ pé ìgboyà tí Dáfídì ní máa ya Jónátánì lẹ́nu gan-an. Dáfídì ti pa Gòláyátì òmìrán, ó sì gbé “orí Filísínì náà” lọ fún bàbá Jónátánì, ìyẹn Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 17:57) Ó dá Jónátánì lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Dáfídì, àtìgbà yẹn sì ni Dáfídì àti Jónátánì ti di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Wọ́n ṣèlérí fúnra wọn pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn. (1 Sámúẹ́lì 18:1-3) Látìgbà náà lọ ni Dáfídì ti dúró gbágbáágbá ti Jónátánì.

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ni Jèhófà yàn dípò Jónátánì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù, síbẹ̀ Jónátánì ò dalẹ̀ Dáfídì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù sì fẹ́ pa Dáfídì, ọkàn Jónátánì ò balẹ̀ torí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Dáfídì. Jónátánì mọ̀ pé Dáfídì wà ní aginjù kan ní Hóréṣì, torí náà ó lọ síbẹ̀ láti fún un níṣìírí pé kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jónátánì sọ fún Dáfídì pé: “Má fòyà; nítorí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́, ìwọ ni yóò sì jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì, èmi ni yóò sì di igbá-kejì rẹ.”—1 Sámúẹ́lì 23:16, 17.

3. Kí ló ṣe pàtàkì sí Jónátánì ju jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì lọ, báwo la sì ṣe mọ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

 3 Inú wa máa ń dùn tá a bá rí àwọn adúróṣinṣin. Àmọ́, ṣé torí pé Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì nìkan la fi fẹ́ràn rẹ̀? Rárá, ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé Jónátánì ni bó ṣe máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Ìdí ẹ̀ sì nìyẹn tí Jónátánì fi jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì tí kò sì jowú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì máa jọba dípò rẹ̀. Kódà, Jónátánì ran Dáfídì lọ́wọ́ kó lè gbára lé Jèhófà. Àwọn méjèèjì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, wọn ò sì dalẹ̀ ara wọn. Wọn ò gbàgbé àdéhùn tí wọ́n jọ bára wọn ṣe pé: “Kí Jèhófà fúnra rẹ̀ wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín ọmọ mi àti ọmọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—1 Sámúẹ́lì 20:42.

4. (a) Kí ló máa mú ká láyọ̀ kí ọkàn wa sì balẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn tó wà nínú ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn ará nínú ìjọ. (1 Tẹsalóníkà 2:10, 11) Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó ṣe tán, òun ló dá wa. (Ìṣípayá 4:11) A máa ń láyọ̀, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àmọ́, a mọ̀ pé ó ṣì yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kódà láwọn ìgbà tí nǹkan ò bá rọgbọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí àpẹẹrẹ Jónátánì lè gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà: (1) tá a bá rò pé kò yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ, (2) tó bá di pé ká pinnu ẹni tá a máa jẹ́ adúróṣinṣin sí, (3) tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú bá ṣì wá lóye tàbí tó ṣàìdáa sí wa àti (4) tó bá ṣòro fún wa láti pa àdéhùn mọ́.

TÁ A BÁ RÒ PÉ KÒ YẸ KÁ BỌ̀WỌ̀ FÚN ẸNÌ KAN TÓ WÀ NÍPÒ ÀṢẸ

5. Kí nìdí tí kò fi rọrùn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń ṣàkóso wọn?

5 Nǹkan ò rọgbọ fún Jónátánì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Sọ́ọ̀lù Ọba tó jẹ́ bàbá Jónátánì ti di aláìgbọràn, Jèhófà sì ti kọ̀ ọ́. (1 Sámúẹ́lì 15:17-23) Síbẹ̀, Ọlọ́run gbà kí Sọ́ọ̀lù ṣàkóso fún ọ̀pọ̀ ọdún. Torí náà, ó ṣòro fáwọn èèyàn náà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run torí pé ọba tó wà lórí “ìtẹ́ Jèhófà” ń ṣe ohun tó burú jáì.—1 Kíróníkà 29:23.

6. Kí ló fi hàn pé Jónátánì ò fi Jèhófà sílẹ̀?

6 Jónátánì ò fi Jèhófà sílẹ̀. Ronú nípa ohun tí Jónátánì ṣe lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (1 Sámúẹ́lì 13:13, 14) Nígbà yẹn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun Filísínì wá gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun. Ẹgbẹ̀ta [600] ọmọ ogun péré ni Sọ́ọ̀lù ní, òun àti Jónátánì nìkan ló sì ní ohun ìjà ogun lọ́wọ́. Àmọ́, ẹ̀rù ò ba Jónátánì. Ó rántí ohun tí wòlíì Sámúẹ́lì sọ pé: “Nítorí Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 12:22) Torí náà, Jónátánì sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà pé: “Kò sí ìdílọ́wọ́ fún Jèhófà láti fi púpọ̀ tàbí díẹ̀ gbà là.” Torí náà, òun àti ọmọ ogun náà bá àwọn kan lára àwọn ọmọ ogun Filísínì jà, wọ́n sì pa àwọn tó tó ogún lára wọn. Jónátánì nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, Jèhófà sì bù  kún un. Jèhófà mú kí ilẹ̀ sẹ̀, àyà àwọn ọmọ ogun Filísínì domi, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í para wọn, bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun nìyẹn.—1 Sámúẹ́lì 13:5, 15, 22; 14:1, 2, 6, 14, 15, 20.

7. Báwo ni Jónátánì ṣe ń ṣe sí bàbá rẹ̀?

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà, síbẹ̀ Jónátánì ṣì ń gbọ́ràn sí bàbá rẹ̀ lẹ́nu bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n jọ jagun láti dáàbò bo àwọn èèyàn Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 31:1, 2.

8, 9. Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ, báwo nìyẹn á ṣe fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin?

8 Bíi ti Jónátánì, àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ká máa ṣègbọràn sáwọn tó ń ṣàkóso ní orílẹ̀-èdè tá à ń gbé, bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Jèhófà fàyè gba “àwọn aláṣẹ onípò gíga” yìí láti máa ṣàkóso wa, ó sì fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn. (Ka Róòmù 13:1, 2.) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ bí wọn ò tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ tá a sì rò pé wọn ò yẹ lẹ́ni tó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún. Kódà, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo àwọn tí Jèhófà fi sípò àṣẹ.—1 Kọ́ríńtì 11:3; Hébérù 13:17.

À ń fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya wa bí kì í bá tiẹ̀ ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 9)

9 Arábìnrin Olga tó ń gbé nílẹ̀ South America jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nípa bíbọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé  ọkọ rẹ̀ ń máyé nira fún un. [1] (Wo àfikún àlàyé.) Nígbà míì, ọkọ rẹ̀ máa ń yàn án lódì tàbí kó máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Olga. Ó tiẹ̀ máa ń halẹ̀ mọ́ ọn pé òun á fi í sílẹ̀, òun á sì kó àwọn ọmọ lọ. Àmọ́, Arábìnrin Olga ò “fi ibi san ibi.” Ó ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí aya rere máa ṣe lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ. Á se oúnjẹ fún ọkọ rẹ̀, á fọ aṣọ rẹ̀, á sì tọ́jú àwọn ọmọ. (Róòmù 12:17) Nígbà tó bá sì ṣeé ṣe fún un, ó máa ń bá a lọ sọ́dọ̀ ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí bàbá ọkọ ẹ̀ kú, tí wọ́n sì fẹ́ lọ sìnkú náà ní ìlú míì, Olga ṣètò gbogbo ohun tí wọ́n máa lò lọ́hùn-ún. Nígbà tí wọ́n sì débẹ̀, ó dúró sí ìta ṣọ́ọ̀ṣì de ọkọ rẹ̀ títí tí wọ́n fi parí ètò náà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ọkọ Olga bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa sí Olga torí sùúrù tó ní àti ọ̀wọ̀ tó ní fún un. Ní báyìí, ó máa ń rán an létí bí àkókò ìpàdé bá ti tó, ó máa ń gbé e lọ síbẹ̀, ó sì máa ń gbóríyìn fún un. Kódà nígbà míì, ó máa ń bá a lọ sí ìpàdé.—1 Pétérù 3:1.

TÓ BÁ DI PÉ KÁ PINNU ẸNI TÁ A MÁA JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ

10. Báwo ni Jónátánì ṣe mọ ẹni tó yẹ kí òun jẹ́ adúróṣinṣin sí?

10 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù sọ pé òun máa pa Dáfídì, ó ṣòro fún Jónátánì láti mọ ohun tí ì bá ṣe. Kò fẹ́ dalẹ̀ bàbá rẹ̀, kò sì fẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ òun àti Dáfídì já. Jónátánì mọ̀ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn Dáfídì, ó sì mọ̀ pé Ọlọ́run ti kọ Sọ́ọ̀lù sílẹ̀, torí náà Jónátánì yàn láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì. Jónátánì ní kí Dáfídì lọ fara pa mọ́, ó sì bẹ Sọ́ọ̀lù pé kó má pa Dáfídì.—Ka 1 Sámúẹ́lì 19:1-6.

11, 12. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe máa mú ká pinnu pé a máa jẹ́ adúróṣinṣin sí i?

11 Ó di dandan fún Arábìnrin Alice tó ń gbé nílẹ̀ Ọsirélíà láti pinnu ẹni tó máa jẹ́ adúróṣinṣin sí. Nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó máa ń sọ àwọn nǹkan tó ń kọ́ fún ìdílé rẹ̀. Ó tún sọ fún wọn pé òun ò ní máa bá wọn ṣayẹyẹ Kérésì mọ́, ó sì sọ ìdí rẹ̀ fún wọn. Nígbà tó kọ́kọ́ sọ fún wọn, ńṣe ló dà bí àlá lójú wọn, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí i gan-an. Wọ́n rò pé àwọn ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan lójú Alice mọ́. Màmá Alice wá sọ pé òun ò fẹ́ rí Alice sójú mọ́. Alice sọ pé: “Ara mi bù máṣọ, ó sì dùn mí gan-an torí pé mo nífẹ̀ẹ́ ìdílé mi. Síbẹ̀, mo pinnu pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ni màá fi ayé mi fún, mo sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ tá a ṣe lẹ́yìn náà.”—Mátíù 10:37.

12 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun gba ìjọsìn Jèhófà mọ́ wa lọ́wọ́. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan, iléèwé tàbí orílẹ̀-èdè wa ò gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì sí wa ju ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà lọ. Bí àpẹẹrẹ, Henry fẹ́ràn láti máa ta ayò kan tí wọ́n ń pè ní chess pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ tó ń tayò náà níléèwé wọn torí pé ó fẹ́ gba àmì ẹ̀yẹ fún iléèwé rẹ̀. Àmọ́, torí pé gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ló fi ń tayò yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé jẹ, kò sì lọ sóde ẹ̀rí déédéé mọ́. Henry sọ pé iléèwé òun ti wá ṣe pàtàkì sí òun ju ìdúróṣinṣin òun sí Ọlọ́run lọ. Torí náà, ó pinnu pé òun ò ní tayò náà fún iléèwé òun mọ́.—Mátíù 6:33.

13. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ìdílé?

13 Nígbà míì, ó lè má rọrùn láti tẹ́  gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́rùn. Bí àpẹẹrẹ, Ken sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti máa lọ kí màmá mi nílé lọ́pọ̀ ìgbà káwọn náà sì wá máa lo ọjọ́ mélòó kan lọ́dọ̀ wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, màmá mi àti ìyàwó mi ò rẹ́. Kódà, mi ò lè ṣe ohun tí ọ̀kan ń fẹ́ kí n má ṣẹ èkejì.” Ken ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ, ó sì rí i pé nínú ọ̀rọ̀ tó wà ńlẹ̀ yìí, òun gbọ́dọ̀ tẹ́ ìyàwó òun lọ́rùn ná kí òun sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Torí náà, ó fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà, inú ìyàwó rẹ̀ sì dùn sí ohun tó ṣe yẹn. Ó wá sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé kó máa ṣe dáadáa sí ìyá òun, ó sì tún ṣàlàyé fún ìyá rẹ̀ náà pé ó yẹ kó máa ka ìyàwó òun kún.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

BÍ ARÁKÙNRIN KAN BÁ ṢÌ WÁ LÓYE TÀBÍ ṢÀÌDÁA SÍ WA

14. Ìwà àìdáa wo ni Sọ́ọ̀lù hù sí Jónátánì?

14 A lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà kódà bí arákùnrin kan tó ń múpò iwájú bá hùwà tí ò dáa sí wa. Ọlọ́run ló yan Sọ́ọ̀lù ọba sípò, síbẹ̀ Sọ́ọ̀lù fi ojú ọmọ òun fúnra ẹ̀ rí màbo. Sọ́ọ̀lù ò mọ ìdí tí Jónátánì fi fẹ́ràn Dáfídì tó bẹ́ẹ̀. Torí náà, nígbà tí Jónátánì gbìyànjú láti ran Dáfídì lọ́wọ́, Sọ́ọ̀lù gbaná jẹ, ó sì tún dójú ti Jónátánì lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Síbẹ̀, Jónátánì ṣì bọ̀wọ̀ fún bàbá rẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jónátánì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti sí Dáfídì tí Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù.—1 Sámúẹ́lì 20:30-41.

15. Bí arákùnrin kan bá hùwà tí ò dáa sí wa, kí ló yẹ ká ṣe?

 15 Nínú àwọn ìjọ wa lónìí, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú máa ń gbìyànjú láti gbọ́ ti gbogbo èèyàn tó wà nínú ìjọ. Àmọ́, aláìpé làwọn arákùnrin yìí, wọ́n sì lè máà lóye ìdí tá a fi ṣe nǹkan tá a ṣe nígbà míì. (1 Sámúẹ́lì 1:13-17) Torí náà, tí wọ́n bá ṣì wá lóye, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.

TÓ BÁ ṢÒRO FÚN WA LÁTI PA ÀDÉHÙN MỌ́

16. Àwọn ìgbà wo ló pọn dandan pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run?

16 Jónátánì ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ kó di ọba lẹ́yìn òun dípò Dáfídì. (1 Sámúẹ́lì 20:31) Àmọ́, Jónátánì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. Kàkà kí Jónátánì jẹ́ onímọtara ẹni nìkan, ó di ọ̀rẹ́ Dáfídì ó sì pa àdéhùn tó ní pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Kódà, gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i kì í yẹ ẹ̀jẹ́ tó bá jẹ́ ‘bí ó ti wù kí o nira tó.’ (Sáàmù 15:4, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àá máa pa àdéhùn tá a bá ṣe mọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn iṣẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan, á máa rí i dájú pé a ṣe ohun tá a ṣèlérí pé a máa ṣe, kódà bí kò bá tiẹ̀ rọrùn pàápàá. Bí nǹkan ò bá lọ bó ṣe yẹ nínú ìgbéyàwó wa ńkọ́? Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí ọkọ wa tàbí ìyàwó wa ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Ka Málákì 2:13-16.

Tá a bá ṣe àdéhùn pẹ̀lú ẹni tá a bá dòwò pọ̀, ó yẹ ká pa àdéhùn wa mọ́ torí pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 16)

17. Kí lo ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

17 Bíi ti Jónátánì, a fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kódà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro lílekoko. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn wá. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀, ìyẹn ló sì máa fún wa láyọ̀ tó wà pẹ́ títí. (Òwe 27:11) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò jẹ́ ṣe ohun tó máa pa wá lára, ó sì máa tọ́jú wa. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun tá a lè rí kọ́ lára àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ayé Dáfídì àtàwọn tó kọ̀ láti jẹ́ adúróṣinṣin.

^ [1] (ìpínrọ̀ 9) A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.