Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Johannes Rauthe wà lóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn míì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ láàárin ọdún 1920 sí 1929

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

“Iṣẹ́ Ìwàásù Mi Ń Sèso Rere, Ó sì Ń Fògo fún Jèhófà”

“Iṣẹ́ Ìwàásù Mi Ń Sèso Rere, Ó sì Ń Fògo fún Jèhófà”

ÌWÉ ÌRÒYÌN Ilé Ìṣọ́ September 1, 1915 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: ‘Gbogbo ogun tí wọ́n ti jà sẹ́yìn kò tó nǹkan kan tá a bá fi wéra pẹ̀lú rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Yúróòpù.’ Ogun Àgbáyé Kìíní yìí gbalẹ̀ gbòde, kódà ó tàn dé nǹkan bí ọgbọ̀n orílẹ̀-èdè. Ilé Ìṣọ́ yìí sọ bí ogun yẹn ṣe fawọ́ iṣẹ́ ìwàásù sẹ́yìn, ó ní: “Iṣẹ́ ìwàásù ò lọ dáadáa mọ́ pàápàá lórílẹ̀-èdè Jámánì àti ilẹ̀ Faransé.”

Torí rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé nígbà yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò mọ̀ bóyá káwọn wọṣẹ́ ológun tàbí káwọn má wọ̀ ọ́, àmọ́, wọ́n pinnu pé àwọn á máa wàásù nìṣó. Bí àpẹẹrẹ, Wilhelm Hildebrandt wà lára àwọn ọmọ ogun Jámánì tó lọ sí ilẹ̀ Faransé. Ó kó ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pè ní The Bible Students Monthly lédè Faransé dání kó lè pín in fáwọn ẹlòmíì. Ó ya àwọn èèyàn lẹ́nu láti rí ẹni tó wọ aṣọ ológun Jámánì tó sì ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà fáwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé.

Àwọn lẹ́tà tá a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yẹn sọ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà kódà nígbà tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun. Arákùnrin Lemke tó jẹ́ ọmọ ogun ojú omi wàásù fáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀, márùn-ún lára wọn ló sì nífẹ̀ẹ́ sóhun tó bá wọn sọ. Ó sọ pé: “Kódà nínú ọkọ̀ ojú omi yìí, iṣẹ́ ìwàásù mi ń sèso rere, ó sì ń fògo fún Jèhófà.”

Sójà ni Georg Kayser nígbà tó lọ sójú ogun, àmọ́ nígbà tó máa dé, ó ti di ìránṣẹ́ Jèhófà. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Ó ka ọ̀kan lára àwọn ìwé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó kà sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi tó fi pinnu pé òun ò jagun mọ́. Ó wá gbà láti máa ṣe iṣẹ́ tí kò ní mú kó wà lójú ogun. Lẹ́yìn tí ogun náà parí, ó ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ìlànà Bíbélì nípa ogun, síbẹ̀ ìwà wọn àti ìṣesí wọn yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn èèyàn tó ń ti ogun náà lẹ́yìn. Bí àwọn olóṣèlú àtàwọn àlùfáà ṣe ń koná sí ogun náà tí wọ́n sì ń gbé orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ, ṣe làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” náà lẹ́yìn. (Aísá. 9:6) Nígbà yẹn, àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun, síbẹ̀ wọ́n fara mọ́ ohun tí Konrad Mörtter tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ pé:  “Mo ti rí i kedere látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé kò yẹ káwa Kristẹni máa pààyàn.”—Ẹ́kís. 20:13. *

Hans Hölterhoff ń lo ọmọlanke láti polongo ìwé ìròyìn The Golden Age

Ní ilẹ̀ Jámánì, àwọn tó lé ní ogún [20] ló kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà á. Àmọ́ òfin ilẹ̀ Jámánì kò fàyè gba irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ìjọba tiẹ̀ sọ pé àrùn ọpọlọ ló ń dàámú àwọn kan lára àwọn tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Lára àwọn tí ìjọba pè ní alárùn ọpọlọ ni Gustav Kujathti. Wọ́n gbé e lọ síbi tí wọ́n ti ń wo àwọn alárùn ọpọlọ, onírúurú oògùn ni wọ́n sì fún un níbẹ̀. Arákùnrin Hans Hölterhoff náà kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, ni wọ́n bá rán an lọ sẹ́wọ̀n, síbẹ̀ ó kọ iṣẹ́ èyíkéyìí tó ní í ṣe pẹ̀lú ogun. Àwọn ẹ̀ṣọ́ jù ú sínú àpò aṣọ tó nípọn kan tí kò jẹ́ kó lè ká ọwọ́ àtẹsẹ̀ kò, nígbà tó yá, àtigbọ́wọ́ àtẹsẹ wá dogun fún un. Nígbà tí wọ́n rí i pé kò yẹhùn, wọ́n mú un tipátipá lọ síbi tí wọ́n ti máa ń pa àwọn ọ̀daràn, wọ́n sì ṣe bíi pé wọ́n á yìnbọ fún un kó lè yẹhùn, àmọ́ wọn ò pa á. Síbẹ̀, Arákùnrin Hans jẹ́ adúróṣinṣin jálẹ̀ ogun náà.

Wọ́n mú àwọn arákùnrin míì wọṣẹ́ ológun, àmọ́ àwọn arákùnrin náà kọ̀ láti gbébọn, wọ́n sì ní kí wọ́n fún àwọn ní iṣẹ́ míì tí kò ní la ìjà lọ. * Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Johannes Rauthe, wọ́n wá ní kó lọ ṣiṣẹ́ ní rélùwéè. Wọ́n ní kí Konrad Mörtter lọ máa ran àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì lọ́wọ́ nílé ìwòsàn, wọ́n sì rán Reinhold Weber lọ ṣiṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Inú August Krafzig dùn pé iṣẹ́ tí wọ́n fún òun kò gba pé kóun lọ sójú ogun torí pé báàgì ni wọ́n ní kó máa tò. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Torí pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ láti dá sọ́rọ̀ ogun nígbà yẹn, ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ wọn lọ́wọ́ ṣọ́ wọn lẹ́sẹ̀. Nígbà tí ogun parí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kan àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Jámánì ṣáá, wọ́n sì ń gbé wọn lọ sílé ẹjọ́ torí pé wọ́n ń wàásù. Kó bàa lè rọrùn fáwọn ará wa ní Jámánì láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn ní kóòtù, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè náà dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin sílẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Magdeburg.

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ ń lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ológun àti òṣèlú. Torí náà, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, ó ti ṣe kedere sáwọn ará wa pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ogun lọ́nàkọnà. Ìdí nìyẹn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Jámánì fi ka àwọn ará wa sí ọ̀tá ìlú, wọ́n sì pọ́n wọn lójú gan-an. Tá a bá ní ká dẹ́nu lé ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tá à ń sọ yìí, ilẹ̀ á kún. Torí náà, a máa jíròrò rẹ̀ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí tó ń bọ̀, ìyẹn Látinú Àpamọ́ Wa ní Àárín Gbùngbùn Yúróòpù.

^ ìpínrọ̀ 7 Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wo àpilẹ̀kọ náà, “Látinú Àpamọ́ Wa—Wọ́n Dúró Ṣinṣin ní ‘Wákàtí Ìdánwò’” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2013.

^ ìpínrọ̀ 9 Ètò Ọlọ́run ló dábàá yìí nínú Ìdìpọ̀ Kẹfà ìwé Millennial Dawn (ọdún 1904) àti nínú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ti oṣù August ọdún 1906, lédè Jámánì. Àmọ́, nínú ìwé ìròyìn The Watch Tower toṣù September, ọdún 1915, ètò Ọlọ́run la àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóye pé kò yẹ kí wọ́n dá sọ́rọ̀ ogun mọ́ rárá. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yẹn kò jáde lédè Jámánì.