Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ilé Iṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)  |  August 2016

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ló dé táwọn ọ̀tá Jésù fi ranrí mọ́ ọ̀rọ̀ fífọ ọwọ́?

Èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn táwọn ọ̀tá Jésù fi kan òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Òfin Mósè sọ àwọn àṣẹ tí ẹni tó ní ìsunjáde tàbí àrùn ẹ̀tẹ̀ máa tẹ̀ lé kó lè di mímọ́, títí kan bí wọ́n á ṣe mójú tó òkú èèyàn àti òkú ẹran. Ó tún sọ ohun tí wọ́n lè ṣe kí ẹnì kan tàbí ohun kan tó ti di aláìmọ́ lè di mímọ́. Lára ohun tí wọ́n lè ṣe ni pé kí wọ́n fọ̀ ọ́, kí wọ́n rúbọ tàbí kí wọ́n wọ́n omi tàbí nǹkan míì sí i.—Léf. orí 11-15; Núm. orí 19.

Àwọn Júù tó jẹ́ rábì ń fẹ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ inú òfin yìí lójú. Ìwádìí kan sọ pé gbogbo ohun tó lè sọ èèyàn di aláìmọ́ làwọn rábì máa ń “yẹ̀ wò fínnífínní kí wọ́n lè mọ ibi tí ẹ̀gbin ti lè wá, bó ṣe máa ń ràn, ibi tó lè ràn dé, àwọn ohun èlò tó lè di aláìmọ́ àtèyí tí ò lè di aláìmọ́ àti gbogbo ohun tí wọ́n nílò fún ìwẹ̀mọ́gaara.”

Àwọn alátakò Jésù bi í pé: “Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í hùwà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń fi ọwọ́ ẹlẹ́gbin jẹ oúnjẹ wọn?” (Máàkù 7:5) Kì í ṣe pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń fi ọwọ́ tó dọ̀tí jẹun ni àwọn ọ̀tá yìí ń sọ. Ara ààtò ẹ̀sìn àwọn rábì ni pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ da omi sí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n tó jẹun. Ìwádìí tá a mẹ́nu bà lókè yìí tún sọ pé: “Wọ́n tún máa ń rin kinkin lórí irú ìkòkò tó yẹ kí wọ́n fi da omi náà, irú omi tó yẹ kí wọ́n lò, ẹni tó yẹ kó dà á àti ibi tó yẹ kí wọ́n da omi náà dé lápá wọn.”

Ojú wo ni Jésù fi wo àwọn òfin táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ yìí? Èsì tó fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe kedere, ó ní: “Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa ẹ̀yin alágàbàgebè, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi [Jèhófà]. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.’ Ní pípa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ̀yin di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti ènìyàn mú ṣinṣin.”—Máàkù 7:6-8.